Ephesians 1:9-12

Ẹniti o ti sọ ohun ijinlẹ ifẹ rẹ̀ di mimọ̀ fun wa, gẹgẹ bi idunnú rẹ̀, eyiti o ti pinnu ninu rẹ̀, Fun iṣẹ iriju ti kikun akoko na, ki o le ko ohun gbogbo jọ ninu Kristi, iba ṣe eyiti mbẹ ninu awọn ọrun, tabi eyiti mbẹ li aiye, ani ninu rẹ̀: Ninu ẹniti a fi wa ṣe ini rẹ̀ pẹlu, awa ti a ti yan tẹlẹ, gẹgẹ bi ipinnu ẹniti nṣiṣẹ ohun gbogbo gẹgẹ bi ìmọ ifẹ rẹ̀: Ki awa ki o le jẹ fun iyin ogo rẹ̀, awa ti a ti ni ireti ṣaju ninu Kristi
Efe 1:9-12