Efe 1:16-18

Emi kò si simi lati mã dupẹ nitori nyin, ati lati mã darukọ nyin ninu adura mi; Pe ki Ọlọrun Jesu Kristi Oluwa wa, Baba ogo, le fun nyin li Ẹmi nipa ti ọgbọ́n ati ti ifihan ninu ìmọ rẹ̀: Ki oju ọkàn nyin le mọlẹ; ki ẹnyin ki o le mọ ohun ti ireti ìpe rẹ̀ jẹ, ati ohun ti ọrọ̀ ogo ini rẹ̀ ninu awọn enia mimọ́ jẹ
Efe 1:16-18