Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Deuteronomy 6:4-14

Deu 6:4-14 - Gbọ́, Israeli: OLUWA Ọlọrun wa, OLUWA kan ni.
Ki iwọ ki o si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ.
Ati ọ̀rọ wọnyi, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ki o ma wà ni àiya rẹ:
Ki iwọ ki o si ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ rẹ gidigidi, ki iwọ ki o si ma fi wọn ṣe ọ̀rọ isọ nigbati iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrìn li ọ̀na, ati nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide.
Ki iwọ ki o si so wọn mọ́ ọwọ́ rẹ fun àmi, ki nwọn ki o si ma ṣe ọja-igbaju niwaju rẹ.
Ki iwọ ki o si kọ wọn sara opó ile rẹ, ati sara ilẹkun ọ̀na-ode rẹ.

Yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na, ti o bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fun ọ ni ilu ti o tobi ti o si dara, ti iwọ kò mọ̀,
Ati ile ti o kún fun ohun rere gbogbo, ti iwọ kò kún, ati kanga wiwà, ti iwọ kò wà, ọgbà-àjara ati igi oróro, ti iwọ kò gbìn; nigbati iwọ ba jẹ tán ti o ba si yó;
Kiyesara rẹ ki iwọ ki o má ba gbagbé OLUWA ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú.
Bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o si ma sìn i, ki o si ma bura li orukọ rẹ̀.
Ẹnyin kò gbọdọ tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ninu oriṣa awọn enia, ti o yi nyin ká kiri

Gbọ́, Israeli: OLUWA Ọlọrun wa, OLUWA kan ni. Ki iwọ ki o si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ. Ati ọ̀rọ wọnyi, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ki o ma wà ni àiya rẹ: Ki iwọ ki o si ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ rẹ gidigidi, ki iwọ ki o si ma fi wọn ṣe ọ̀rọ isọ nigbati iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrìn li ọ̀na, ati nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide. Ki iwọ ki o si so wọn mọ́ ọwọ́ rẹ fun àmi, ki nwọn ki o si ma ṣe ọja-igbaju niwaju rẹ. Ki iwọ ki o si kọ wọn sara opó ile rẹ, ati sara ilẹkun ọ̀na-ode rẹ. Yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na, ti o bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fun ọ ni ilu ti o tobi ti o si dara, ti iwọ kò mọ̀, Ati ile ti o kún fun ohun rere gbogbo, ti iwọ kò kún, ati kanga wiwà, ti iwọ kò wà, ọgbà-àjara ati igi oróro, ti iwọ kò gbìn; nigbati iwọ ba jẹ tán ti o ba si yó; Kiyesara rẹ ki iwọ ki o má ba gbagbé OLUWA ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú. Bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o si ma sìn i, ki o si ma bura li orukọ rẹ̀. Ẹnyin kò gbọdọ tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ninu oriṣa awọn enia, ti o yi nyin ká kiri

Deu 6:4-14

Deuteronomy 6:4-14
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò