Deuteronomy 31:6-9

Ẹ ṣe giri ki ẹ si mu àiya le, ẹ máṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe fòya wọn: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ, on li o mbá ọ lọ; on ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃ni ki yio kọ̀ ọ. Mose si pè Joṣua, o si wi fun u li oju gbogbo Israeli pe, Ṣe giri ki o si mu àiya le: nitoripe iwọ ni yio bá awọn enia yi lọ si ilẹ na, ti OLUWA ti bura fun awọn baba wọn, lati fi fun wọn; iwọ o si mu wọn gbà a. Ati OLUWA on li o nlọ ṣaju rẹ; on ni yio pẹlu rẹ, on ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃ni ki yio kọ̀ ọ: máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o máṣe fò ọ. Mose si kọwe ofin yi, o si fi i fun awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ti ima rù apoti majẹmu OLUWA, ati fun gbogbo awọn àgba Israeli.
Deu 31:6-9