3 John 1:2-4

Olufẹ, emi ngbadura pe ninu ohun gbogbo ki o le mã dara fun ọ, ki o si mã wà ni ilera, ani bi o ti dara fun ọkàn rẹ. Nitori mo yọ̀ gidigidi, nigbati awọn arakunrin de ti nwọn si jẹri si otitọ rẹ, ani bi iwọ ti nrìn ninu otitọ. Emi kò ni ayọ̀ ti o pọjù eyi lọ, ki emi ki o mã gbọ́ pe, awọn ọmọ mi nrìn ninu otitọ.
III. Joh 1:2-4