2 Timothy 2:14-19

Nkan wọnyi ni ki o mã rán wọn leti, mã kìlọ fun wọn niwaju Oluwa pe, ki nwọn ki o máṣe jijà ọ̀rọ ti kò lere, fun iparun awọn ti ngbọ. Ṣãpọn lati fi ara rẹ hàn niwaju Ọlọrun li ẹniti o yege, aṣiṣẹ́ ti kò ni lati tiju, ti o npín ọ̀rọ otitọ bi o ti yẹ. Ṣugbọn yà kuro ninu ọ̀rọ asan, nitoriti nwọn ó mã lọ siwaju ninu aiwa-bi-Ọlọrun, Ọrọ wọn yio si mã jẹ bi egbò kikẹ̀; ninu awọn ẹniti Himeneu ati Filetu wà; Awọn ẹniti o ti ṣìna niti otitọ, ti nwipe ajinde ti kọja na; ti nwọn si mbì igbagbọ́ awọn miran ṣubu. Ṣugbọn ipilẹ Ọlọrun ti o daju duro ṣinṣin, o ni èdidi yi wipe, Oluwa mọ̀ awọn ti iṣe tirẹ̀. Ati pẹlu, ki olukuluku ẹniti npè orukọ Oluwa ki o kuro ninu aiṣododo.
II. Tim 2:14-19