2 Chronicles 20:15-17

O si wipe, Ẹ tẹti silẹ, gbogbo Judah, ati ẹnyin olugbe Jerusalemu, ati iwọ Jehoṣafati ọba; Bayi li Oluwa wi fun nyin, Ẹ máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fòya nitori ọ̀pọlọpọ enia yi; nitori ogun na kì iṣe ti nyin bikòṣe ti Ọlọrun. Lọla sọ̀kalẹ tọ̀ wọn: kiyesi i, nwọn o gbà ibi igòke Sisi wá; ẹnyin o si ri wọn ni ipẹkun odò na, niwaju aginju Jerueli. Ẹnyin kò ni ijà li ọ̀ran yi; ẹ tẹgun, ẹ duro jẹ, ki ẹ si ri igbala Oluwa lọdọ nyin, iwọ Juda ati Jerusalemu: ẹ máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fòya: lọla, ẹ jade tọ̀ wọn: Oluwa yio si pẹlu nyin.
II. Kro 20:15-17