1 Petrus 3:18-21

Nitoriti Kristi pẹlu jìya lẹ̃kan nitori ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ fun awọn alaiṣõtọ, ki o le mu wa de ọdọ Ọlọrun, ẹniti a pa ninu ara, ṣugbọn ti a sọ di ãye ninu ẹmí: Ninu eyiti o lọ pẹlu, ti o si wãsu fun awọn ẹmí ninu tubu: Awọn ti o ṣe alaigbọran nigbakan, nigbati sũru Ọlọrun duro pẹ ni sã kan ni ọjọ Noa, nigbati nwọn fi nkàn ọkọ̀ ninu eyiti à gba ọkàn diẹ là nipa omi, eyini ni ẹni mẹjọ; Apẹrẹ eyiti ngbà nyin là nisisiyi pẹlu, ani baptismu, kì iṣe ìwẹ ẽri ti ara nù, bikoṣe idahùn ọkàn rere sipa Ọlọrun, nipa ajinde Jesu Kristi
I. Pet 3:18-21