1 John 4:8-10

Ẹniti kò ba ni ifẹ kò mọ̀ Ọlọrun: nitoripe ifẹ ni Ọlọrun. Nipa eyi li a gbé fi ifẹ Ọlọrun hàn ninu wa, nitoriti Ọlọrun rán Ọmọ bíbi rẹ̀ nikanṣoṣo si aiye, ki awa ki o le yè nipasẹ rẹ̀. Ninu eyi ni ifẹ wà, kì iṣe pe awa fẹ Ọlọrun, ṣugbọn on fẹ wa, o si rán Ọmọ rẹ̀ lati jẹ ètutu fun ẹ̀ṣẹ wa.
I. Joh 4:8-10