Àwọn èsì àwárí fún: romans 8:28

Rom 8:28 (YBCV)

Awa si mọ̀ pe ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ̀ si rere fun awọn ti o fẹ Ọlọrun, ani fun awọn ẹniti a pè gẹgẹ bi ipinnu rẹ̀.

Eks 8:28 (YBCV)

Farao si wipe, Emi o jẹ ki ẹnyin lọ, ki ẹ le rubọ si OLUWA Ọlọrun nyin ni ijù; kìki ki ẹnyin ki o máṣe lọ jìna jù: ẹ bẹ̀bẹ fun mi.

Lef 8:28 (YBCV)

Mose si gbà wọn li ọwọ́ wọn, o si sun wọn lori pẹpẹ li ẹbọ sisun: ìyasimimọ́ ni nwọn fun õrùn didùn: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA.

Joṣ 8:28 (YBCV)

Joṣua si kun Ai, o sọ ọ di òkiti lailai, ani ahoro titi di oni-oloni.

Esr 8:28 (YBCV)

Mo si wi fun wọn pe, Mimọ́ li ẹnyin si Oluwa; mimọ́ si li ohun èlo wọnyi; ọrẹ atinuwa si Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin ni fàdaka ati wura na.

Owe 8:28 (YBCV)

Nigbati o sọ awọsanma lọjọ̀ soke: nigbati o fi agbara fun orisun ibu:

Mat 8:28 (YBCV)

Nigbati o si de apa keji ni ilẹ awọn ara Gergesene, awọn ọkunrin meji ẹlẹmi èṣu pade rẹ̀, nwọn nti inu ibojì jade wá, nwọn rorò gidigidi tobẹ̃ ti ẹnikan ko le kọja li ọ̀na ibẹ̀.

Mak 8:28 (YBCV)

Nwọn si dahùn wipe, Johanu Baptisti: ẹlomiran si wipe Elijah; ṣugbọn awọn ẹlomiran wipe, Ọkan ninu awọn woli.

Luk 8:28 (YBCV)

Nigbati o ri Jesu, o ke, o wolẹ niwaju rẹ̀, o wi li ohùn rara, pe, Kini ṣe temi tirẹ Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun Ọgá-ogo? emi bẹ̀ ọ máṣe da mi loró.

Joh 8:28 (YBCV)

Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Nigbati ẹ ba gbé Ọmọ-enia soke, nigbana li ẹ o mọ̀ pe, emi ni, ati pe emi kò dá ohunkohun ṣe fun ara mi; ṣugbọn bi Baba ti kọ́ mi, emi nsọ nkan wọnyi.

A. Oni 8:28 (YBCV)

Bẹ̃li a si tẹ̀ ori Midiani ba niwaju awọn ọmọ Israeli, nwọn kò si gbé ori wọn soke mọ́. Ilẹ na si simi ni ogoji ọdún li ọjọ́ Gideoni.

I. Kro 8:28 (YBCV)

Wọnyi li olori awọn baba, nipa iran wọn, awọn olori. Awọn wọnyi ni ngbe Jerusalemu.

Iṣe Apo 8:28 (YBCV)

On si npada lọ, o si joko ninu kẹkẹ́ rẹ̀, o nkà iwe woli Isaiah.

I. A. Ọba 8:28 (YBCV)

Sibẹ̀ iwọ ṣe afiyèsi adura iranṣẹ rẹ, ati si ẹbẹ rẹ̀, Oluwa Ọlọrun mi, lati tẹtisilẹ si ẹkun ati si adura, ti iranṣẹ rẹ ngbà niwaju rẹ loni:

II. A. Ọba 8:28 (YBCV)

On si lọ pẹlu Joramu ọmọ Ahabu si ogun na ti o mba Hasaeli ọba Siria jà ni Ramoti-Gileadi; awọn ara Siria si ṣa Joramu li ọgbẹ́.

Gẹn 28:8 (YBCV)

Nigbati Esau ri pe awọn ọmọbinrin Kenaani kò wù Isaaki baba rẹ̀;

Eks 28:8 (YBCV)

Ati onirũru-ọnà ọjá rẹ̀, ti o wà lori rẹ̀ yio ri bakanna, gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; ti wurà, ti aṣọ-alaró, ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ.

Num 28:8 (YBCV)

Ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o fi rubọ li aṣalẹ: bi ẹbọ ohunjijẹ ti owurọ̀, ati bi ẹbọ ohunmimu rẹ̀ ni ki iwọ ki o ṣe, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.

Deu 28:8 (YBCV)

OLUWA yio paṣẹ ibukún sori rẹ ninu aká rẹ, ati ninu ohun gbogbo ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé; on o si busi i fun ọ ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.

Job 28:8 (YBCV)

Awọn ọmọ kiniun kò rin ibẹ rí, bẹ̃ni kiniun ti nké ramuramu kò kọja nibẹ rí.

Owe 28:8 (YBCV)

Ẹniti o fi elé ati ère aiṣõtọ sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di pupọ, o kó o jọ fun ẹniti yio ṣãnu fun awọn talaka.

Isa 28:8 (YBCV)

Nitori gbogbo tabili li o kún fun ẽbi ati ẹgbin, kò si ibi ti o mọ́.

Jer 28:8 (YBCV)

Awọn woli ti o ti ṣaju mi, ati ṣaju rẹ ni igbãni sọ asọtẹlẹ pupọ, ati si ijọba nla niti ogun, ati ibi, ati ajakalẹ-arun.

Esek 28:8 (YBCV)

Nwọn o mu ọ sọkalẹ wá sinu ihò, iwọ o si kú ikú awọn ti a pa li ãrin okun.

Mat 28:8 (YBCV)

Nwọn si fi ibẹru pẹlu ayọ̀ nla yara lọ kuro ni ibojì; nwọn si saré lọ iròhin fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.