Àwọn èsì àwárí fún: romans 15:13
Joh 15:13 (YBCV)
Ko si ẹnikan ti o ni ifẹ ti o tobi jù eyi lọ, pe ẹnikan fi ẹmí rẹ̀ lelẹ nitori awọn ọrẹ́ rẹ̀.
Rom 15:13 (YBCV)
Njẹ ki Ọlọrun ireti ki o fi gbogbo ayọ̀ on alafia kún nyin ni gbigbagbọ, ki ẹnyin ki o le pọ̀ ni ireti nipa agbara Ẹmí Mimọ́.
Gẹn 15:13 (YBCV)
On si wi fun Abramu pe, Mọ̀ nitõtọ pe irú-ọmọ rẹ yio ṣe alejo ni ilẹ ti ki iṣe ti wọn, nwọn o si sìn wọn, nwọn o si jẹ wọn ni íya ni irinwo ọdún;
Eks 15:13 (YBCV)
Ninu ãnu rẹ ni iwọ fi ṣe amọ̀na awọn enia na ti iwọ ti rapada: iwọ si nfi agbara rẹ tọ́ wọn lọ si ibujoko mimọ́ rẹ.
Lef 15:13 (YBCV)
Nigbati ẹniti o ní isun ba si di mimọ́ kuro ninu isun rẹ̀, nigbana ni ki o kà ijọ́ meje fun ara rẹ̀, fun isọdimimọ́ rẹ̀, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi ti nṣàn, yio si jẹ́ mimọ́.
Num 15:13 (YBCV)
Gbogbo ibilẹ ni ki o ma ṣe nkan wọnyi bayi, nigbati nwọn ba nru ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA.
Deu 15:13 (YBCV)
Nigbati iwọ ba si nrán a lọ li ominira kuro lọdọ rẹ, iwọ kò gbọdọ jẹ ki o lọ li ọwọ́ ofo:
Joṣ 15:13 (YBCV)
Ati fun Kalebu ọmọ Jefunne li o fi ipín fun lãrin awọn ọmọ Juda, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA fun Joṣua, ani Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni); Arba si ni baba Anaki.
Job 15:13 (YBCV)
Ti iwọ fi yi ẹmi rẹ pada lodi si Ọlọrun, ti o fi njẹ ki ọ̀rọkọrọ ki o ma bọ li ẹnu rẹ bẹ̃?
Owe 15:13 (YBCV)
Inu-didùn a mu oju daraya; ṣugbọn nipa ibinujẹ aiya, ọkàn a rẹ̀wẹsi.
Jer 15:13 (YBCV)
Ohun-ini ati iṣura rẹ li emi o fi fun ijẹ, li aigbowo, nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ ni àgbegbe rẹ.
Mat 15:13 (YBCV)
O si dahùn, o wi fun wọn pe, Igikigi ti Baba mi ti mbẹ li ọrun kò ba gbìn, a o fà a tu kuro.
Mak 15:13 (YBCV)
Nwọn si tún kigbe soke, wipe, Kàn a mọ agbelebu.
Luk 15:13 (YBCV)
Kò si to ijọ melokan lẹhinna, eyi aburo kó ohun gbogbo ti o ni jọ, o si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n lọ si ilẹ òkere, nibẹ̀ li o si gbé fi ìwa wọ̀bia na ohun ini rẹ̀ ni inákuna.
A. Oni 15:13 (YBCV)
Nwọn si wi fun u pe, Rárá o; didè li awa o dè ọ, a o si fi ọ lé wọn lọwọ: ṣugbọn niti pipa awa ki yio pa ọ. Nwọn si fi okùn titun meji dè e, nwọn si mú u gòke lati ibi apata na wá.
I. Sam 15:13 (YBCV)
Samueli si tọ Saulu wá: Saulu si wi fun u pe, Alabukún ni ọ lati ọdọ Oluwa wá: emi ti ṣe eyi ti Oluwa ran mi.
II. Sam 15:13 (YBCV)
Ẹnikan si wá rò fun Dafidi pe, Ọkàn awọn ọkunrin Israeli ṣi si Absalomu.
I. Kro 15:13 (YBCV)
Nitoriti ẹnyin kò rù u li akọṣe, ni Oluwa Ọlọrun wa fi ṣe ẹ̀ya si wa li ara, nitori awa kò wá a bi o ti yẹ.
II. Kro 15:13 (YBCV)
Pe, ẹnikẹni ti kò ba wá Oluwa Ọlọrun Israeli, pipa li a o pa a, lati ẹni-kekere de ẹni-nla, ati ọkunrin ati obinrin.
Iṣe Apo 15:13 (YBCV)
Lẹhin ti nwọn si dakẹ, Jakọbu dahùn, wipe, Ará, ẹ gbọ ti emi:
I. Kor 15:13 (YBCV)
Ṣugbọn bi ajinde okú kò si, njẹ Kristi kò jinde:
I. A. Ọba 15:13 (YBCV)
Ati Maaka iya rẹ̀ papã, li o si mu kuro lati ma ṣe ayaba, nitori ti o yá ere kan fun oriṣa rẹ̀; Asa si ke ere na kuro; o si daná sun u nibi odò Kidroni.
II. A. Ọba 15:13 (YBCV)
Ṣallumu ọmọ Jabeṣi bẹ̀rẹ si ijọba li ọdun kọkandilogoji Ussiah ọba Juda; o si jọba oṣù kan gbáko ni Samaria.
Gẹn 13:15 (YBCV)
Gbogbo ilẹ ti o ri nì, iwọ li emi o sa fi fun ati fun irú-ọmọ rẹ lailai.
Eks 13:15 (YBCV)
O si ṣe, nigbati Farao kọ̀ lati jẹ ki a lọ, on li OLUWA pa gbogbo akọ́bi ni ilẹ Egipti, ati akọ́bi enia, ati akọ́bi ẹran; nitorina ni mo ṣe fi gbogbo akọ́bi ti iṣe akọ rubọ si OLUWA; ṣugbọn gbogbo awọn akọ́bi ọmọ ọkunrin mi ni mo rapada.