Àwọn èsì àwárí fún: psalm 32:8
Gẹn 32:8 (YBCV)
O si wipe, bi Esau ba kàn ẹgbẹ kan, ti o si kọlù u, njẹ ẹgbẹ keji ti o kù yio là.
Eks 32:8 (YBCV)
Nwọn ti yipada kánkan kuro ni ipa-ọ̀na ti mo làsilẹ fun wọn: nwọn ti dá ere ẹgbọrọmalu fun ara wọn, nwọn si ti mbọ ọ, nwọn si ti rubọ si i, nwọn nwipe, Israeli, wọnyi li oriṣa rẹ, ti o mú ọ gòke lati ilẹ̀ Egipti wá.
Num 32:8 (YBCV)
Bẹ̃li awọn baba nyin ṣe, nigbati mo rán wọn lati Kadeṣi-barnea lọ lati wò ilẹ na.
Deu 32:8 (YBCV)
Nigbati Ọga-ogo pín iní fun awọn orilẹ-ède, nigbati o tu awọn ọmọ enia ká, o pàla awọn enia na gẹgẹ bi iye awọn ọmọ Israeli.
Job 32:8 (YBCV)
Ṣugbọn ẹmi kan ni o wà ninu enia, ati imisi Olodumare ni isi ma fun wọn li oye.
Isa 32:8 (YBCV)
Ṣugbọn ẹni-rere a ma gbèro ohun rere; nipa ohun-rere ni yio ṣe duro.
Jer 32:8 (YBCV)
Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, si tọ̀ mi wá li agbala ile túbu gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, o si wi fun mi pe, Jọ̃, ra oko mi, ti o wà ni Anatoti, ti o wà ni ilẹ Benjamini: nitori titọ́ ogun rẹ̀ jẹ tirẹ, ati irasilẹ jẹ tirẹ; rà a fun ara rẹ. Nigbana ni mo mọ̀ pe, eyi li ọ̀rọ Oluwa.
Esek 32:8 (YBCV)
Gbogbo imọlẹ oju ọrun li emi o mu ṣokùnkun lori rẹ, emi o gbe okùnkun kà ilẹ rẹ, li Oluwa Ọlọrun wi.
II. Kro 32:8 (YBCV)
Apa ẹran-ara li o pẹlu rẹ̀, ṣugbọn Oluwa Ọlọrun wa li o pẹlu wa lati ràn wa lọwọ, ati lati jà ogun wa. Awọn enia na si gbẹkẹ wọn le ọ̀rọ Hesekiah, ọba Juda.
O. Daf 32:8 (YBCV)
Emi o fi ẹsẹ̀ rẹ le ọ̀na, emi o si kọ́ ọ li ọ̀na ti iwọ o rìn: emi o ma fi oju mi tọ́ ọ.
Eks 8:32 (YBCV)
Farao si mu àiya rẹ̀ le nigbayi pẹlu, kò si jẹ ki awọn enia na ki o lọ.
Lef 8:32 (YBCV)
Eyiti o ba si kù ninu ẹran na ati ninu àkara na ni ki ẹnyin ki o fi iná sun.
Joṣ 8:32 (YBCV)
O si kọ apẹrẹ ofin Mose sara okuta na, ti o kọ niwaju awọn ọmọ Israeli.
Esr 8:32 (YBCV)
Awa si de Jerusalemu, awa si simi nibẹ li ọjọ mẹta.
Owe 8:32 (YBCV)
Njẹ nisisiyi, ẹ fetisi temi, ẹnyin ọmọ: nitoripe ibukún ni fun awọn ti o tẹle ọ̀na mi:
Mat 8:32 (YBCV)
O si wi fun wọn pe, Ẹ mã lọ. Nigbati nwọn si jade, nwọn lọ sinu agbo ẹlẹdẹ na; si wò o, gbogbo agbo ẹlẹdẹ na rọ́ sinu okun li ogedengbe, nwọn si ṣegbé ninu omi.
Mak 8:32 (YBCV)
O si sọ ọ̀rọ na ni gbangba. Peteru si mu u, o bẹ̀rẹ si iba a wi.
Luk 8:32 (YBCV)
Agbo ẹlẹdẹ pipọ si mbẹ nibẹ̀ ti njẹ li ori òke: nwọn si bẹ̀ ẹ ki o jẹ ki awọn wọ̀ inu wọn lọ. O si jọwọ wọn.
Joh 8:32 (YBCV)
Ẹ ó si mọ̀ otitọ, otitọ yio si sọ nyin di omnira.
Rom 8:32 (YBCV)
Ẹniti kò da Ọmọ on tikararẹ̀ si, ṣugbọn ti o jọwọ rẹ̀ lọwọ fun gbogbo wa, yio ha ti ṣe ti kì yio fun wa li ohun gbogbo pẹlu rẹ̀ lọfẹ?
A. Oni 8:32 (YBCV)
Gideoni ọmọ Joaṣi si kú li ọjọ́ ogbó, a si sin i si ibojì Joaṣi baba rẹ̀, ni Ofra ti awọn Abieseri.
I. Kro 8:32 (YBCV)
Mikloti si bi Ṣimea. Awọn wọnyi pẹlu si mba awọn arakunrin wọn gbe Jerusalemu, nwọn kọju si ara wọn.
Iṣe Apo 8:32 (YBCV)
Ibi iwe-mimọ́ ti o si nkà na li eyi, A fà a bi agutan lọ fun pipa; ati bi ọdọ-agutan iti iyadi niwaju olurẹrun rẹ̀, bẹ̃ni kò yà ẹnu rẹ̀:
I. A. Ọba 8:32 (YBCV)
Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si ṣe, ki o si dajọ awọn iranṣẹ rẹ, ni didẹbi fun enia buburu, lati mu ọ̀na rẹ̀ wá si ori rẹ̀; ati ni didare fun olõtọ, lati fun u gẹgẹ bi ododo rẹ̀.
O. Daf 132:8 (YBCV)
Oluwa, dide si ibi isimi rẹ; iwọ, ati apoti agbara rẹ.