Àwọn èsì àwárí fún: ephesians 6:12

Mat 6:12 (YBCV)

Dari gbese wa jì wa, bi awa ti ndarijì awọn onigbese wa.

Efe 6:12 (YBCV)

Nitoripe kì iṣe ẹ̀jẹ ati ẹran-ara li awa mba jijakadi, ṣugbọn awọn ijoye, awọn ọlọla, awọn alaṣẹ ibi òkunkun aiye yi, ati awọn ẹmí buburu ni oju ọrun.

Gẹn 6:12 (YBCV)

Ọlọrun si bojuwò aiye, si kiye si i, o bajẹ; nitori olukuluku enia ti bà ìwa rẹ̀ jẹ li aiye.

Eks 6:12 (YBCV)

Mose si sọ niwaju OLUWA wipe, Kiyesi i, awọn ọmọ Israeli kò gbọ́ ti emi, Farao yio ha ti ṣe gbọ́ ti emi, emi ẹniti iṣe alaikọlà ète?

Lef 6:12 (YBCV)

Ki iná ori pẹpẹ nì ki o si ma jó lori rẹ̀; ki a máṣe pa a; ki alufa ki o si ma kòná igi lori rẹ̀ li orowurọ̀, ki o si tò ẹbọ sisun sori rẹ̀; ki o si ma sun ọrá ẹbọ alafia lori rẹ̀.

Num 6:12 (YBCV)

Ki o si yà ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ simimọ́ si OLUWA, ki o si mú akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan wá, fun ẹbọ ẹbi: ṣugbọn ọjọ́ ti o ti ṣaju yio di asan, nitoripe ìyasapakan rẹ̀ bàjẹ́.

Deu 6:12 (YBCV)

Kiyesara rẹ ki iwọ ki o má ba gbagbé OLUWA ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú.

Joṣ 6:12 (YBCV)

Joṣua si dide ni kùtukutu owurọ̀, awọn alufa si gbé apoti OLUWA.

Esr 6:12 (YBCV)

Ki Ọlọrun ẹniti o mu ki orukọ rẹ̀ ma gbe ibẹ, ki o pa gbogbo ọba, ati orilẹ-ède run, ti yio da ọwọ wọn le lati ṣe ayipada, ati lati pa ile Ọlọrun yi run, ti o wà ni Jerusalemu. Emi Dariusi li o ti paṣẹ, ki a mu u ṣẹ li aijafara.

Neh 6:12 (YBCV)

Sa kiyesi i, mo woye pe, Ọlọrun kò rán a, ṣugbọn pe, o nsọ asọtẹlẹ yi si mi: nitori Tobiah ati Sanballati ti bẹ̀ ẹ li ọ̀wẹ.

Est 6:12 (YBCV)

Mordekai si tun pada wá si ẹnu-ọ̀na ile ọba, ṣugbọn Hamani yara lọ si ile rẹ̀ ti on ti ibinujẹ, o si bò ori rẹ̀.

Job 6:12 (YBCV)

Agbara mi iṣe agbara okuta bi, tabi ẹran ara mi iṣe idẹ?

Owe 6:12 (YBCV)

Enia-kenia, ọkunrin buburu, ti o nrìn ti on ti ẹnu arekereke.

Oni 6:12 (YBCV)

Nitoripe tali o mọ̀ ohun ti o dara fun enia li aiye yi, ni iye ọjọ asan rẹ̀ ti nlọ bi ojiji? nitoripe tali o le sọ fun enia li ohun ti yio wà lẹhin rẹ̀ labẹ õrùn?

Isa 6:12 (YBCV)

Titi Oluwa yio fi ṣi awọn enia na kuro lọ rére, ti ikọ̀silẹ nla yio si wà ni inu ilẹ na.

Jer 6:12 (YBCV)

Ile wọn o di ti ẹlomiran, oko wọn ati aya wọn lakopọ̀: nitori emi o nà ọwọ mi si ori awọn olugbe ilẹ na, li Oluwa wi.

Esek 6:12 (YBCV)

Ẹniti o jina rere yio kú nipa ajakalẹ àrun; ati ẹniti o sunmọ tosí yio ṣubu nipa idà; ati ẹniti o kù ti a si do tì yio kú nipa iyàn: bayi li emi o mu irunu mi ṣẹ lori wọn.

Dan 6:12 (YBCV)

Nigbana ni nwọn wá, nwọn si wi niwaju ọba niti aṣẹ ọba pe, Kò ṣepe iwọ fi ọwọ sinu iwe pe, ẹnikan ti o ba bère ohunkohun lọwọ Ọlọrun tabi lọwọ enia kan niwọn ọgbọ̀n ọjọ, bikoṣe lọwọ rẹ, ọba, pe a o gbé e sọ sinu iho kiniun? Ọba si dahùn o wipe, Otitọ li ọ̀ran na, gẹgẹ bi ofin awọn ara Media ati Persia, ti a kò gbọdọ pada.

Amo 6:12 (YBCV)

Ẹṣin ha le ma sure lori apata? ẹnikan ha le fi akọ malu ṣiṣẹ ìtulẹ̀ nibẹ̀? nitoriti ẹnyin ti yi idajọ dà si oró, ati eso ododo dà si iwọ:

Mik 6:12 (YBCV)

Ti awọn ọlọrọ̀ rẹ̀ kún fun ìwa-ipá, ati awọn ti ngbe inu rẹ̀ ti sọ̀rọ eké, ahọn wọn si kún fun ẹ̀tan li ẹnu wọn.

Sek 6:12 (YBCV)

Si sọ fun u pe, Bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ wipe, Wò ọkunrin na ti orukọ rẹ̀ njẹ ẸKA; yio si yọ ẹka lati abẹ rẹ̀ wá, yio si kọ́ tempili Oluwa;

Mak 6:12 (YBCV)

Nwọn si jade lọ, nwọn si wasu ki awọn enia ki o le ronupiwada.

Luk 6:12 (YBCV)

O si ṣe ni ijọ wọnni, o lọ si ori òke lọ igbadura, o si fi gbogbo oru na gbadura si Ọlọrun.

Joh 6:12 (YBCV)

Nigbati nwọn si yó, o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ kó ajẹkù ti o kù jọ, ki ohunkohun máṣe ṣegbé.

Rom 6:12 (YBCV)

Nitorina ẹ maṣe jẹ ki ẹ̀ṣẹ ki o jọba ninu ara kiku nyin, ti ẹ o fi mã gbọ ti ifẹkufẹ rẹ̀;