Àwọn èsì àwárí fún: Romans 3:23
Rom 3:23 (YBCV)
Gbogbo enia li o sá ti ṣẹ̀, ti nwọn si kuna ogo Ọlọrun;
Kol 3:23 (YBCV)
Ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mã fi tọkàntọkàn ṣe e, gẹgẹ bi fun Oluwa, kì si iṣe fun enia;
Gẹn 3:23 (YBCV)
Nitorina OLUWA Ọlọrun lé e jade kuro ninu ọgbà Edeni, lati ma ro ilẹ ninu eyiti a ti mu u jade wá.
Num 3:23 (YBCV)
Awọn idile awọn ọmọ Gerṣoni ni ki o dó lẹhin agọ́ ni ìha ìwọ-õrùn.
Deu 3:23 (YBCV)
Emi si bẹ̀ OLUWA ni ìgba na, wipe,
Neh 3:23 (YBCV)
Lẹhin wọn ni Benjamini ati Haṣubu tun ṣe li ọkánkán ile wọn. Lẹhin wọn ni Asariah ọmọ Maasiah ọmọ Ananiah tun ṣe lẹba ile rẹ̀.
Job 3:23 (YBCV)
Kili a fi imọlẹ fun ẹniti ọ̀na rẹ̀ lumọ si, ti Ọlọrun si sọgba di mọ ká?
Owe 3:23 (YBCV)
Nigbana ni iwọ o ma rìn ọ̀na rẹ lailewu, iwọ ki yio si fi ẹsẹ̀ kọ.
Isa 3:23 (YBCV)
Awòjiji, ati aṣọ ọ̀gbọ daradara, ati ibòri ati ibòju,
Jer 3:23 (YBCV)
Lotitọ asan ni eyi ti o ti oke wá, ani ọ̀pọlọpọ oke giga, lõtọ ninu Oluwa Ọlọrun wa ni igbala Israeli wà.
Esek 3:23 (YBCV)
Mo si dide, mo si lọ si pẹtẹlẹ, si kiyesi i ogo Oluwa duro nibẹ, bi ogo ti mo ri lẹba odò Kebari: mo si doju mi bolẹ.
Dan 3:23 (YBCV)
Ṣugbọn awọn ọkunrin mẹtẹta wọnyi, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ṣubu lulẹ ni didè si ãrin iná ileru ti njo.
Mak 3:23 (YBCV)
O si pè wọn sọdọ rẹ̀, o si fi owe ba wọn sọrọ pe, Satani yio ti ṣe le lé Satani jade?
Luk 3:23 (YBCV)
Jesu tikararẹ̀ nto bi ẹni ìwọn ọgbọ̀n ọdún, o jẹ (bi a ti fi pè) ọmọ Josefu, ti iṣe ọmọ Eli,
Joh 3:23 (YBCV)
Johanu pẹlu si mbaptisi ni Ainoni, li àgbegbe Salimu, nitoriti omi pipọ wà nibẹ̀: nwọn si nwá, a si baptisi wọn.
Gal 3:23 (YBCV)
Ṣugbọn ki igbagbọ́ to de, a ti pa wa mọ́ labẹ ofin, a si sé wa mọ́ de igbagbọ́ ti a mbọwa fihàn.
A. Oni 3:23 (YBCV)
Nigbana ni Ehudu si ba ti iloro lọ, o si se ilẹkun gbọngan na mọ́ ọ, o si tì wọn.
II. Sam 3:23 (YBCV)
Nigbati Joabu ati gbogbo ogun ti o pẹlu rẹ̀ si de, nwọn si sọ fun Joabu pe, Abneri, ọmọ Neri ti tọ̀ ọba wá, on si ti rán a lọ, o si ti lọ li alafia.
I. Kro 3:23 (YBCV)
Ati awọn ọmọ Neariah; Elioenai, ati Hesekiah, ati Asrikamu, meta.
Ẹk. Jer 3:23 (YBCV)
Ọtun ni li orowurọ; titobi ni otitọ rẹ.
Iṣe Apo 3:23 (YBCV)
Yio si ṣe, olukuluku ọkàn ti kò ba gbọ ti woli na, on li a o parun patapata kuro ninu awọn enia.
I. Kor 3:23 (YBCV)
Ẹnyin si ni ti Kristi; Kristi si ni ti Ọlọrun.
I. Joh 3:23 (YBCV)
Eyi si li ofin rẹ̀, pe ki awa ki o gbà orukọ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ gbọ́, ki a si fẹràn ara wa, gẹgẹ bi o ti fi ofin fun wa.
I. A. Ọba 3:23 (YBCV)
Ọba si wipe, Ọkan wipe, eyi li ọmọ mi ti o wà lãye, ati okú li ọmọ rẹ; ekeji si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn eyi okú li ọmọ rẹ, eyi alãye li ọmọ mi.
II. A. Ọba 3:23 (YBCV)
Nwọn si wipe, Ẹ̀jẹ li eyi: awọn ọba na run: nwọn si ti pa ara wọn; njẹ nisisiyi, Moabu, dide si ikogun.