Àwọn èsì àwárí fún: Luke 8:30
Eks 8:30 (YBCV)
Mose si jade kuro lọdọ Farao, o si bẹ̀ OLUWA.
Lef 8:30 (YBCV)
Mose si mú ninu oróro itasori nì, ati ninu ẹ̀jẹ ti mbẹ lori pẹpẹ, o si fi i wọ́n ara Aaroni, ati ara aṣọ rẹ̀ wọnni, ati ara awọn ọmọ rẹ̀, ati ara aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; o si yà Aaroni simimọ́, ati aṣọ rẹ̀ wọnni, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀.
Joṣ 8:30 (YBCV)
Nigbana ni Joṣua tẹ́ pẹpẹ kan fun OLUWA, Ọlọrun Israeli, li òke Ebali,
Esr 8:30 (YBCV)
Bẹ̃ni awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi mu fàdaka ati wura ti a wọ̀n pẹlu ohun-èlo wọnni lati ko wọn wá si Jerusalemu, sinu ile Ọlọrun wa.
Owe 8:30 (YBCV)
Nigbana, emi wà lọdọ rẹ̀, bi oniṣẹ: emi si jẹ didùn-inu rẹ̀ lojojumọ, emi nyọ̀ nigbagbogbo niwaju rẹ̀;
Mat 8:30 (YBCV)
Agbo ọ̀pọ ẹlẹdẹ ti njẹ mbẹ li ọ̀na jijìn si wọn.
Mak 8:30 (YBCV)
O si kìlọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ̀rọ on fun ẹnikan.
Luk 8:30 (YBCV)
Jesu si bi i pe, Orukọ rẹ? Ó si dahùn pe, Legioni: nitoriti ẹmi eṣu pipọ wọ̀ ọ lara lọ.
Joh 8:30 (YBCV)
Bi o ti nsọ nkan wọnyi, ọ̀pọ enia gbà a gbọ́.
Rom 8:30 (YBCV)
Awọn ti o si ti yàn tẹlẹ, awọn li o si ti pè: awọn ẹniti o si ti pè, awọn li o si ti dalare: awọn ẹniti o si ti dalare, awọn li o si ti ṣe logo.
A. Oni 8:30 (YBCV)
Gideoni si ní ãdọrin ọmọkunrin ti o bi fun ara rẹ̀: nitoripe o lí obinrin pupọ̀.
I. Kro 8:30 (YBCV)
Ọmọ rẹ̀ akọbi si ni Abdoni, ati Suri, ati Kiṣi, ati Baali, ati Nadabu,
Iṣe Apo 8:30 (YBCV)
Filippi si sure lọ, o gbọ́, o nkà iwe woli Isaiah, o si bi i pe, Ohun ti iwọ nkà nì, o yé ọ?
I. A. Ọba 8:30 (YBCV)
Ki o si tẹtisilẹ si ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ ati ti Israeli, enia rẹ, ti nwọn o gbadura siha ibi yi: ki o si gbọ́ li ọrun, ibugbe rẹ! gbọ́, ki o si darijì.
Gẹn 30:8 (YBCV)
Rakeli si wipe, Ijakadi nla ni mo fi bá arabinrin mi ja, emi si dá a: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Naftali.
Eks 30:8 (YBCV)
Nigbati Aaroni ba si tàn fitila wọnni li aṣalẹ, yio si ma jó turari lori rẹ̀, turari titilai niwaju OLUWA lati irandiran nyin.
Num 30:8 (YBCV)
Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kọ̀ fun u li ọjọ́ na ti o gbọ́; njẹ on o mu ẹjẹ́ rẹ̀ ti o jẹ́ ati ohun ti o ti ẹnu rẹ̀ jade, eyiti o fi dè ara rẹ̀ dasan: OLUWA yio si darijì i.
Deu 30:8 (YBCV)
Iwọ o si pada, iwọ o si gbà ohùn OLUWA gbọ́, iwọ o si ma ṣe gbogbo ofin rẹ̀ ti mo palaṣẹ fun ọ li oni.
Job 30:8 (YBCV)
Awọn ọmọ ẹniti oye kò ye, ani ọmọ awọn enia lasan, a si le wọn kuro ninu ilẹ.
Owe 30:8 (YBCV)
Mu asan ati eke jìna si mi: máṣe fun mi li òṣi, máṣe fun mi li ọrọ̀; fi onjẹ ti o to fun mi bọ mi.
Isa 30:8 (YBCV)
Nisisiyi lọ, kọ ọ niwaju wọn si walã kan, si kọ ọ sinu iwe kan, ki o le jẹ fun igbà ti mbọ lai ati lailai:
Jer 30:8 (YBCV)
Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti emi o si ṣẹ àjaga kuro li ọrùn rẹ, emi o si ja ìde rẹ, awọn alejo kì yio si mu ọ sìn wọn mọ:
Esek 30:8 (YBCV)
Nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati mo bá gbe iná kalẹ ni Egipti, ti gbogbo awọn olùranlọ́wọ rẹ̀ bá parun.
I. Sam 30:8 (YBCV)
Dafidi si bere lọdọ Oluwa wipe, Ki emi ki o lepa ogun yi bi? emi le ba wọn? O si da a lohùn pe, Lepa: nitoripe ni biba iwọ o ba wọn, ni gbigba iwọ o si ri wọn gbà.
II. Kro 30:8 (YBCV)
Njẹ ki ẹnyin ki o máṣe ṣe ọlọrùn lile, bi awọn baba nyin, ṣugbọn ẹ jọwọ ara nyin lọwọ fun Oluwa, ki ẹ si wọ̀ inu ibi-mimọ́ rẹ̀ lọ, ti on ti yà si mimọ́ titi lai: ki ẹ si sin Oluwa, Ọlọrun nyin, ki imuna ibinu rẹ̀ ki o le yipada kuro li ọdọ nyin.