Àwọn èsì àwárí fún: John 15:5
Joh 15:5 (YBCV)
Emi ni àjara, ẹnyin li ẹka. Ẹniti o ngbé inu mi, ati emi ninu rẹ̀, on ni yio so eso ọ̀pọlọpọ: nitori ni yiyara nyin kuro lọdọ mi, ẹ ko le ṣe ohun kan.
Gẹn 15:5 (YBCV)
O si mu u jade wá si gbangba, o si wi pe, Gboju wò oke ọrun nisisiyi, ki o si kà irawọ bi iwọ ba le kà wọn: o si wi fun u pe, Bẹ̃ni irú-ọmọ rẹ yio ri.
Eks 15:5 (YBCV)
Ibú bò wọn mọlẹ: nwọn rì si isalẹ bi okuta.
Lef 15:5 (YBCV)
Ẹnikẹni ti o ba farakàn akete rẹ̀ ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
Num 15:5 (YBCV)
Ati idamẹrin òṣuwọn hini ọti-waini fun ẹbọ ohunmimu ni ki iwọ ki o pèse pẹlu ẹbọ sisun, tabi ẹbọ, fun ọdọ-agutan kan.
Deu 15:5 (YBCV)
Kìki bi iwọ ba fi ifarabalẹ fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi gbogbo ofin yi, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni lati ṣe.
Joṣ 15:5 (YBCV)
Ati àla ìha ìla-õrùn ni Okun Iyọ̀, ani titi dé ipẹkun Jordani. Ati àla apa ariwa ni lati kọ̀rọ okun nì wá dé ipẹkun Jordani:
Job 15:5 (YBCV)
Nitoripe ẹnu ara rẹ li o jẹwọ ẹ̀ṣẹ rẹ, iwọ si yàn ahọn alarekereke li ãyò.
Owe 15:5 (YBCV)
Aṣiwère gàn ẹkọ́ baba rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba feti si ibawi li o moye.
Isa 15:5 (YBCV)
Ọkàn mi kigbe soke fun Moabu; awọn ìsánsá rẹ̀ sá de Soari, abo-malũ ọlọdun mẹta: ni gigun oke Luhiti tẹkúntẹkún ni nwọn o ma fi gùn u lọ; niti ọ̀na Horonaimu nwọn o gbe ohùn iparun soke.
Jer 15:5 (YBCV)
Nitori tani yio ṣãnu fun ọ, iwọ Jerusalemu? tabi ti yio sọkun rẹ? tabi tani yio wá lati bere alafia rẹ.
Esek 15:5 (YBCV)
Kiyesi i, nigbati o wà li odidi, kò yẹ fun iṣẹ kan: melomelo ni kì yio si yẹ fun iṣẹkiṣẹ, nigbati iná ba ti jo o, ti o si jona?
Mat 15:5 (YBCV)
Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ẹnikẹni ti o ba wi fun baba tabi iya rẹ̀ pe, Ẹbùn li ohunkohun ti iwọ iba fi jère lara mi,
Mak 15:5 (YBCV)
Ṣugbọn Jesu ko da a ni gbolohùn kan: tobẹ̃ ti ẹnu fi yà Pilatu.
Luk 15:5 (YBCV)
Nigbati o si ri i tan, o gbé e le ejika rẹ̀, o nyọ.
Rom 15:5 (YBCV)
Njẹ ki Ọlọrun sũru ati itunu ki o fi fun nyin lati ni inu kan si ara nyin gẹgẹ bi Kristi Jesu:
Ifi 15:5 (YBCV)
Lẹhin na mo si wò, si kiyesi i, a ṣí tẹmpili agọ́ ẹrí li ọrun silẹ:
A. Oni 15:5 (YBCV)
Nigbati o si ti fi iná si ètufu na, o jọwọ wọn lọ sinu oko-ọkà awọn Filistini, o si kun ati eyiti a dì ni ití, ati eyiti o wà li oró, ati ọgbà-olifi pẹlu.
I. Sam 15:5 (YBCV)
Saulu si wá si ilu-nla kan ti awọn ara Amaleki, o si ba dè wọn li afonifoji kan.
II. Sam 15:5 (YBCV)
Bẹ̃ni bi ẹnikan ba si sunmọ ọ lati tẹriba fun u, on a si nawọ́ rẹ̀, a si dì i mu, a si fi ẹnu kò o li ẹnu.
I. Kro 15:5 (YBCV)
Ninu awọn ọmọ Kohati; Urieli olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ ọgọfa:
II. Kro 15:5 (YBCV)
Ati li ọjọ wọnni alafia kò si fun ẹniti o njade, tabi fun ẹniti nwọle, ṣugbọn ibanujẹ pupọ li o wà lori gbogbo awọn olugbe ilẹ wọnni.
O. Daf 15:5 (YBCV)
Ẹniti kò fi owo rẹ̀ gbà èle, ti kò si gbà owo ẹ̀bẹ si alaiṣẹ. Ẹniti o ba ṣe nkan wọnyi kì yio yẹsẹ lailai.
Iṣe Apo 15:5 (YBCV)
Ṣugbọn awọn kan ti ẹya awọn Farisi ti nwọn gbagbọ́ dide, nwọn nwipe, a ni lati kọ wọn ni ilà, ati lati paṣẹ fun wọn pe ki nwọn ki o mã pa ofin Mose mọ́.
I. Kor 15:5 (YBCV)
Ati pe o farahan Kefa, lẹhin eyini awọn mejila: