Àwọn èsì àwárí fún: Job 4
Job 4:1 (YBCV)
NIGBANA ni Elifasi, ara Tema, dahùn wipe,
Job 4:2 (YBCV)
Bi awa ba fi ẹnu le e, lati ba ọ sọrọ, iwọ o ha binujẹ? ṣugbọn tali o le pa ọ̀rọ mọ ẹnu laisọ?
Job 4:3 (YBCV)
Kiyesi i, iwọ sa ti kọ́ ọ̀pọ enia, iwọ sa ti mu ọwọ alailera le.
Job 4:4 (YBCV)
Ọ̀rọ rẹ ti gbe awọn ti nṣubu lọ duro, iwọ si ti mu ẽkun awọn ti nwarirì lera.
Job 4:5 (YBCV)
Ṣugbọn nisisiyi o de ba ọ, o si rẹ̀ ọ, o kọlu ọ, ara rẹ kò lelẹ̀.
Job 4:6 (YBCV)
Ibẹru Ọlọrun rẹ kò ha jẹ igbẹkẹle rẹ? ati iduro ṣinṣin si ìwa ọ̀na rẹ kò ha si jẹ abá rẹ?
Job 4:7 (YBCV)
Emi bẹ̀ ọ ranti, tali o ṣegbe ri laiṣẹ̀, tabi nibo li a gbe ké olododo kuro ri?
Job 4:8 (YBCV)
Ani bi emi ti ri rí pe: awọn ti nṣe itulẹ ẹ̀ṣẹ, ti nwọn si fọ́n irugbin ìwa buburu, nwọn a si ká eso rẹ̀ na.
Job 4:9 (YBCV)
Nipa ifẹsi Ọlọrun nwọn a ṣegbe, nipa ẽmi ibinu rẹ̀ nwọn a parun.
Job 4:10 (YBCV)
Bibu ramuramu kiniun ati ohùn onroró kiniun ati ehin awọn ẹ̀gbọrọ kiniun li a ka.
Job 4:11 (YBCV)
Ogbo kiniun kígbe, nitori airi ohun-ọdẹ, awọn ẹ̀gbọrọ kiniun sisanra li a tukakiri.
Job 4:12 (YBCV)
Njẹ nisisiyi a fi ohun lilumọ́ kan hàn fun mi, eti mi si gbà diẹ ninu rẹ̀.
Job 4:13 (YBCV)
Ni iro inu loju iran oru, nigbati orun ìjika kun enia.
Job 4:14 (YBCV)
Ẹ̀ru bà mi ati iwarirì ti o mu gbogbo egungun mi wá pepé.
Job 4:15 (YBCV)
Nigbana ni iwin kan kọja lọ niwaju mi, irun ara mi dide ró ṣanṣan.
Job 4:16 (YBCV)
On duro jẹ, ṣugbọn emi kò le iwò apẹrẹ irí rẹ̀, àworan kan hàn niwaju mi, idakẹ rọrọ wà, mo si gbohùn kan wipe:
Job 4:17 (YBCV)
Ẹni kikú le jẹ olododo niwaju Ọlọrun, enia ha le mọ́ ju Ẹlẹda rẹ̀ bi?
Job 4:18 (YBCV)
Kiyesi i, on kò gbẹkẹle awọn iranṣẹ rẹ̀, ninu awọn angeli rẹ̀ ni o si ri ẹ̀ṣẹ.
Job 4:19 (YBCV)
Ambọtori awọn ti ngbe inu ile amọ̀, ẹniti ipilẹ wọn jasi erupẹ ti yio di rirun kòkoro.
Job 4:20 (YBCV)
A npa wọn run lati òwurọ di alẹ́, nwọn gbe lailai lairi ẹni kà a si.
Job 4:21 (YBCV)
A kò ha ke okùn iye wọn kuro bi? nwọn ku, ani lailọgbọn.
Job 1:4 (YBCV)
Awọn ọmọ rẹ̀ a si ma lọ ijẹun àse ninu ile ara wọn, olukuluku li ọjọ rẹ̀; nwọn a si ma ranṣẹ pe arabinrin wọn mẹtẹta lati jẹun ati lati mu pẹlu wọn.
Job 2:4 (YBCV)
Satani si dá Oluwa lohùn wipe, awọ fun awọ; ani ohun gbogbo ti enia ni, on ni yio fi rà ẹmi rẹ̀.
Job 3:4 (YBCV)
Ki ọjọ na ki o jasi òkunkun, ki Ọlọrun ki o má ṣe kà a si lati ọrun wá, bẹ̃ni ki imọlẹ ki o máṣe mọ́ si i.
Job 5:4 (YBCV)
Awọn ọmọ rẹ̀ kò jina sinu ewu, a si tẹ̀ wọn mọlẹ loju ibode, bẹ̃ni kò si alãbò kan.