Àwọn èsì àwárí fún: Jeremiah 29:11
Jer 29:11 (YBCV)
Nitori emi mọ̀ ìro ti mo rò si nyin, li Oluwa wi, ani ìro alafia, kì si iṣe fun ibi, lati fun nyin ni ìgba ikẹhin ati ireti.
Jer 29:13 (YBCV)
Ẹnyin o si ṣafẹri mi, ẹ o si ri mi, nitori ẹ o fi gbogbo ọkàn nyin wá mi.
Jer 29:1 (YBCV)
WỌNYI si li ọ̀rọ iwe ti Jeremiah woli rán lati Jerusalemu si iyokù ninu awọn àgba ti o wà ni igbèkun, ati si awọn alufa, ati awọn woli, ati si gbogbo enia ti Nebukadnessari kó ni igbekun lọ lati Jerusalemu si Babeli.
Jer 29:10 (YBCV)
Nitori bayi li Oluwa wi pe, Lẹhin ti ãdọrin ọdun ba pari ni Babeli, li emi o bẹ̀ nyin wò, emi o si mu ọ̀rọ rere mi ṣẹ si nyin, ni mimu nyin pada si ibi yi.
Jer 29:12 (YBCV)
Ẹnyin o si kepe mi, ẹ o si lọ, ẹ o si gbadura si mi, emi o si tẹti si nyin.
Jer 29:14 (YBCV)
Emi o di ríri fun nyin, li Oluwa wi: emi o si yi igbekun nyin pada kuro, emi o si kó nyin jọ lati gbogbo orilẹ-ède ati lati ibi gbogbo wá, nibiti emi ti lé nyin lọ, li Oluwa wi; emi o si tun mu nyin wá si ibi ti mo ti mu ki a kó nyin ni igbekun lọ.
Jer 29:15 (YBCV)
Nitoriti ẹnyin ti wipe, Oluwa ti gbe awọn woli kalẹ fun wa ni Babeli:
Jer 29:16 (YBCV)
Pe, Bayi li Oluwa wi niti ọba ti o joko lori itẹ́ Dafidi, ati niti gbogbo enia, ti ngbe ilu yi, ani niti awọn arakunrin nyin ti kò jade lọ pẹlu nyin sinu igbekun.
Jer 29:17 (YBCV)
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Wò o, emi o rán idà sarin wọn, ìyan, ati àjakalẹ-àrun, emi o ṣe wọn bi eso-ọ̀pọtọ buburu, ti a kò le jẹ, nitori nwọn buru.
Jer 29:18 (YBCV)
Emi o si fi idà, ìyan, ati àjakalẹ-arun lepa wọn; emi o si fi wọn fun iwọsi ni gbogbo ijọba aiye, fun egún, ati iyanu, ati ẹsin, ati ẹ̀gan, lãrin gbogbo orilẹ-ède, nibiti emi o le wọn si.
Jer 29:19 (YBCV)
Nitoriti nwọn kò gbọ́ ọ̀rọ mi, li Oluwa wi, ti emi rán si wọn nipa awọn ọmọ-ọdọ mi, awọn woli, emi dide ni kutukutu mo si rán wọn; ṣugbọn ẹnyin kò fẹ igbọ́, li Oluwa wi.
Jer 29:2 (YBCV)
Lẹhin igbati Jekoniah, ọba, ati ayaba, ati awọn iwẹfa, ati awọn ijoye Juda ati Jerusalemu, ati awọn gbẹna-gbẹna pẹlu awọn alagbẹdẹ ti fi Jerusalemu silẹ lọ.
Jer 29:3 (YBCV)
Nipa ọwọ Elasa, ọmọ Ṣafani, ati Gemariah, ọmọ Hilkiah, (ẹniti Sedekiah, ọba Juda, rán si Babeli tọ Nebukadnessari, ọba Babeli) wipe,
Jer 29:4 (YBCV)
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi fun gbogbo awọn ti a kó ni igbekun lọ, ti emi mu ki a kó lọ lati Jerusalemu si Babeli;
Jer 29:5 (YBCV)
Ẹ kọ́ ile ki ẹ si ma gbe inu wọn; ẹ gbìn ọgba, ki ẹ si mã jẹ eso wọn;
Jer 29:6 (YBCV)
Ẹ fẹ́ aya, ki ẹ si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin; ki ẹ si fẹ́ aya fun awọn ọmọ nyin, ẹ si fi awọn ọmọbinrin nyin fun ọkọ, ki nwọn ki o le mã bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin; ki ẹ le mã pọ si i nibẹ, ki ẹ má si dínkù.
Jer 29:7 (YBCV)
Ki ẹ si mã wá alafia ilu na, nibiti emi ti mu ki a kó nyin lọ ni igbekun, ẹ si mã gbadura si Oluwa fun u: nitori ninu alafia rẹ̀ li ẹnyin o ni alafia.
Jer 29:8 (YBCV)
Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, Ẹ máṣe jẹ ki awọn woli nyin ti o wà lãrin nyin ati awọn alafọṣẹ nyin tàn nyin jẹ, ki ẹ má si feti si alá nyin ti ẹnyin lá.
Jer 29:9 (YBCV)
Nitori nwọn sọ asọtẹlẹ eke fun nyin li orukọ mi: emi kò rán wọn, li Oluwa wi.
Jer 29:20 (YBCV)
Njẹ ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, gbogbo ẹnyin igbekun ti emi ti ran jade lati Jerusalemu si Babeli.
Jer 29:21 (YBCV)
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi, niti Ahabu ọmọ Kolaiah, ati niti Sedekiah ọmọ Maaseiah, ti nsọtẹlẹ eke fun nyin li orukọ mi; wò o, emi fi wọn le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli; on o si pa wọn li oju nyin;
Jer 29:22 (YBCV)
Ati lati ọdọ wọn li a o da ọ̀rọ-egún kan silẹ li ẹnu gbogbo igbekun Juda ti o wà ni Babeli, wipe; Ki Oluwa ki o ṣe ọ bi Sedekiah, ati bi Ahabu, awọn ẹniti ọba Babeli sun ninu iná.
Jer 29:23 (YBCV)
Nitori nwọn ti hùwa wère ni Israeli, nwọn si ba aya aladugbo wọn ṣe panṣaga, nwọn si ti sọ̀rọ eke li orukọ mi, ti emi kò ti pa li aṣẹ fun wọn: emi tilẹ mọ̀, emi si li ẹlẹri, li Oluwa wi.
Jer 29:24 (YBCV)
Ati fun Ṣemaiah ara Nehalami, ni iwọ o sọ wipe.
Jer 29:25 (YBCV)
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Nitoripe iwọ ti rán iwe li orukọ rẹ si gbogbo enia ti o wà ni Jerusalemu ati si Sefaniah, ọmọ Maaseiah, alufa, ati si gbogbo awọn alufa, wipe,