Àwọn èsì àwárí fún: Isaiah 64:8
Isa 64:8 (YBCV)
Ṣugbọn nisisiyi, Oluwa, iwọ ni baba wa; awa ni amọ̀, iwọ si ni ọ̀mọ; gbogbo wa si ni iṣẹ ọwọ́ rẹ.
Isa 64:1 (YBCV)
IWỌ iba jẹ fà awọn ọrun ya, ki iwọ si sọkalẹ, ki awọn oke-nla ki o le yọ́ niwaju rẹ.
Isa 64:2 (YBCV)
Gẹgẹ bi igbati iná ileru ti njo, bi iná ti imu omi hó, lati sọ orukọ rẹ di mimọ̀ fun awọn ọta rẹ, ki awọn orilẹ-ède ki o le warìri niwaju rẹ!
Isa 64:3 (YBCV)
Nigbati iwọ ṣe nkan wọnni ti o lẹ̀ru ti awa kò fi oju sọna fun, iwọ sọkalẹ wá, awọn oke-nla yọ́ niwaju rẹ.
Isa 64:4 (YBCV)
Nitori lati ipilẹṣẹ aiye wá, a kò ti igbọ́, bẹ̃ni eti kò ti gbọ́ ọ, bẹ̃ni oju kò ti iri Ọlọrun kan lẹhin rẹ, ti o ti pèse fun ẹniti o duro dè e.
Isa 64:5 (YBCV)
Iwọ pade ẹniti nyọ̀ ti o nṣiṣẹ ododo, ti o ranti rẹ li ọ̀na rẹ: kiyesi i, iwọ binu; nitori awa ti dẹṣẹ̀; a si pẹ ninu wọn, a o ha si là?
Isa 64:6 (YBCV)
Gbogbo wa si dabi ohun aimọ́, gbogbo ododo wa si dabi akisa ẹlẹgbin; gbogbo wa si rẹ̀ bi ewe; aiṣedede wa si mu wa kuro bi afẹfẹ.
Isa 64:7 (YBCV)
Kò si ẹniti npè orukọ rẹ, ti o si rú ara rẹ̀ soke lati di ọ mu: nitori iwọ ti pa oju rẹ mọ kuro lara wa, iwọ si ti run wa, nitori aiṣedede wa.
Isa 64:9 (YBCV)
Máṣe binu kọja àla, Oluwa, ki o má si ranti aiṣedede wa titilai: kiyesi i, wò, awa bẹ̀ ọ, enia rẹ ni gbogbo wa iṣe.
Isa 64:10 (YBCV)
Awọn ilu mimọ́ rẹ di aginju, Sioni dí aginju, Jerusalemu di ahoro.
Isa 64:11 (YBCV)
Ile wa mimọ́ ati ologo, nibiti awọn baba wa ti nyìn ọ, li a fi iná kun: gbogbo ohun ãyo wa si ti run.
Isa 64:12 (YBCV)
Iwọ o ha da ara rẹ duro nitori nkan wọnyi, Oluwa? iwọ o ha dakẹ, ki o si pọn wa loju kọja àla?
Isa 8:1 (YBCV)
PẸLUPẸLU Oluwa wi fun mi pe, Iwọ mu iwe nla kan, ki o si fi kalamu enia kọwe si inu rẹ̀ niti Maher-ṣalal-haṣ-basi.
Isa 8:2 (YBCV)
Emi si mu awọn ẹlẹri otitọ sọdọ mi lati ṣe ẹlẹri. Uriah alufa, ati Sekariah ọmọ Jeberekiah.
Isa 8:3 (YBCV)
Mo si wọle tọ wolĩ obinrin ni lọ; o si loyun o si bi ọmọkunrin kan. Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, sọ orukọ rẹ̀ ni Maher-ṣalal-haṣ-basi.
Isa 8:4 (YBCV)
Nitoripe ki ọmọ na to ni oye ati ke pe, Baba mi, ati iya mi, ọrọ̀ Damasku ati ikogun Samaria ni a o mu kuro niwaju ọba Assiria.
Isa 8:5 (YBCV)
Oluwa si tun wi fun mi pe,
Isa 8:6 (YBCV)
Niwọn bi enia yi ti kọ̀ omi Ṣiloa ti nṣàn jẹjẹ silẹ, ti nwọn si nyọ̀ ninu Resini ati ọmọ Remaliah.
Isa 8:7 (YBCV)
Njẹ nitorina kiyesi i, Oluwa nfà omi odò ti o le, ti o si pọ̀, wá sori wọn, ani ọba Assiria ati gbogbo ogo rẹ̀; yio si wá sori gbogbo ọ̀na odò rẹ̀, yio si gun ori gbogbo bèbe rẹ̀.
Isa 8:8 (YBCV)
Yio si kọja li arin Juda; yio si ṣàn bò o mọlẹ yio si mù u de ọrùn, ninà iyẹ rẹ̀ yio si kún ibú ilẹ rẹ, iwọ Immanueli.
Isa 8:9 (YBCV)
Ẹ ko ara nyin jọ, ẹnyin enia, a o si fọ nyin tũtu: ẹ si fi eti silẹ, gbogbo ẹnyin ará ilẹ jijìna: ẹ di ara nyin li àmure, a o si fọ nyin tũtu; ẹ di ara nyin li àmure, a o si fọ nyin tũtu.
Isa 8:10 (YBCV)
Ẹ gbìmọ pọ̀ yio si di asan; ẹ sọ̀rọ na, ki yio si duro: nitoripe Ọlọrun wà pẹlu wa.
Isa 8:11 (YBCV)
Nitoriti Oluwa wi bayi fun mi, nipa ọwọ agbara, o si kọ mi ki nmá ba rìn ni ọ̀na enia yi, pe,
Isa 8:12 (YBCV)
Ẹ máṣe pè gbogbo eyi ni imulẹ ti awọn enia yi pè ni imulẹ: bẹ̃ni ẹ máṣe bẹ̀ru ibẹ̀ru wọn, ẹ má si ṣe foya.
Isa 8:13 (YBCV)
Yà Oluwa awọn ọmọ-ogun tikalarẹ̀ si mimọ́; si jẹ ki o ṣe ẹ̀ru nyin, si jẹ ki o ṣe ifòya nyin.