Àwọn èsì àwárí fún: Isaiah 58:6
Isa 58:6 (YBCV)
Awẹ ti mo ti yàn kọ́ eyi? lati tú ọjá aiṣododo, lati tú ẹrù wiwo, ati lati jẹ ki anilara lọ lọfẹ, ati lati já gbogbo ajàga.
Isa 58:1 (YBCV)
KE rara, máṣe dasi, gbe ohùn rẹ soke bi ipè, ki o si fi irekọja awọn enia mi hàn wọn, ati ile Jakobu, ẹ̀ṣẹ wọn.
Isa 58:2 (YBCV)
Ṣugbọn nwọn nwá mi lojojumọ, nwọn si ni inu didun lati mọ̀ ọ̀na mi, bi orilẹ-ède ti nṣe ododo, ti kò si fi ilàna Ọlọrun wọn silẹ: nwọn mbere ilàna ododo wọnnì lọwọ mi; nwọn a ma ṣe inu didun ati sunmọ Ọlọrun.
Isa 58:3 (YBCV)
Nitori kini awa ṣe ngbãwẹ̀, ti iwọ kò si ri i? nitori kini awa jẹ ọkàn wa ni ìya, ti iwọ kò si mọ̀? Kiyesi i, li ọjọ ãwẹ̀ nyin ẹnyin nṣe afẹ́, ẹ si nfi agbara mu ni ṣe gbogbo iṣẹ nyin.
Isa 58:4 (YBCV)
Kiyesi i, ẹnyin ngbãwẹ̀ fun ìja ati ãwọ̀, ati lilù, nipa ikũku ìwa-buburu: ẹ máṣe gbãwẹ bi ti ọjọ yi, ki a le gbọ́ ohùn nyin li oke.
Isa 58:5 (YBCV)
Ãwẹ̀ iru eyi ni mo yàn bi? ọjọ ti enia njẹ ọkàn rẹ̀ ni ìya? lati tẹ ori rẹ̀ ba bi koriko odo? ati lati tẹ́ aṣọ ọ̀fọ ati ẽru labẹ rẹ̀? iwọ o ha pe eyi ni ãwẹ̀, ati ọjọ itẹwọgba fun Oluwa?
Isa 58:7 (YBCV)
Kì ha ṣe lati fi onjẹ rẹ fun awọn ti ebi npa, ati ki iwọ ki o mu awọn otòṣi ti a tì sode wá si ile rẹ? nigbati iwọ ba ri arinhòho, ki iwọ ki o bò o, ki iwọ, ki o má si fi ara rẹ pamọ kuro lọdọ ẹran-ara tirẹ.
Isa 58:8 (YBCV)
Nigbana ni imọlẹ rẹ yio bẹ́ jade bi owurọ, ilera rẹ yio sọ jade kánkán: ododo rẹ yio si lọ ṣaju rẹ; ogo Oluwa yio kó ọ jọ.
Isa 58:9 (YBCV)
Nigbana ni iwọ o pè, Oluwa yio si dahun; iwọ o kigbe, on o si wipe, Emi nĩ. Bi iwọ ba mu àjaga, ninà ika, ati sisọ asan, kuro lãrin rẹ.
Isa 58:10 (YBCV)
Bi iwọ ba fà ọkàn rẹ jade fun ẹniti ebi npa, ti o si tẹ́ ọkàn ti a npọ́n loju lọrùn, nigbana ni imọlẹ rẹ yio si là ninu okùnkun, ati okùnkun rẹ bi ọ̀san gangan.
Isa 58:11 (YBCV)
Oluwa yio ma tọ́ ọ nigbagbogbo, yio si tẹ́ ọkàn rẹ lọrun ni ibi gbigbẹ, yio si mu egungun rẹ sanra; iwọ o si dabi ọgbà ti a bomirin, ati bi isun omi ti omi rẹ̀ ki itán.
Isa 58:12 (YBCV)
Ati awọn tirẹ yio mọ ibi ahoro atijọ wọnni: iwọ o gbé ipilẹ iran ọ̀pọlọpọ ró, a o si ma pe ọ ni, Alatunṣe ẹyà nì, Olumupada ọ̀na wọnni lati gbe inu rẹ̀.
Isa 58:13 (YBCV)
Bi iwọ ba yí ẹsẹ rẹ kuro li ọjọ isimi, lati má ṣe afẹ́ rẹ li ọjọ isimi mi; ti iwọ si pè ọjọ isimi ni adùn, ọjọ mimọ́ Oluwa, ọlọ́wọ̀; ti iwọ si bọ̀wọ fun u, ti iwọ kò hù ìwa rẹ, tabi tẹle afẹ rẹ, tabi sọ ọ̀rọ ara rẹ.
Isa 58:14 (YBCV)
Nigbana ni inu rẹ yio dùn si Oluwa, emi o si mu ọ gùn ibi giga aiye, emi o si fi ilẹ níni Jakobu baba rẹ bọ́ ọ: nitori ẹnu Oluwa li o ti sọ ọ.
Isa 6:1 (YBCV)
LI ọdun ti Ussiah ọba kú, emi ri Oluwa joko lori itẹ ti o ga, ti o si gbe ara soke, iṣẹti aṣọ igunwà rẹ̀ kun tempili.
Isa 6:2 (YBCV)
Awọn serafu duro loke rẹ̀: ọkọ̃kan wọn ni iyẹ mẹfa, o fi meji bò oju rẹ̀, o si fi meji bò ẹsẹ rẹ̀, o si fi meji fò.
Isa 6:3 (YBCV)
Ikini si ke si ekeji pe, Mimọ́, mimọ́, mimọ́, li Oluwa awọn ọmọ-ogun, gbogbo aiye kún fun ogo rẹ̀.
Isa 6:4 (YBCV)
Awọn òpo ilẹ̀kun si mì nipa ohùn ẹniti o ke, ile na si kún fun ẹ̃fin.
Isa 6:5 (YBCV)
Nigbana ni mo wipe, Egbe ni fun mi, nitori mo gbé, nitoriti mo jẹ́ ẹni alaimọ́ etè, mo si wà lãrin awọn enia alaimọ́ etè, nitoriti oju mi ti ri Ọba, Oluwa awọn ọmọ-ogun.
Isa 6:6 (YBCV)
Nigbana ni ọkan ninu awọn serafu fò wá sọdọ mi, o ni ẹṣẹ́-iná li ọwọ́ rẹ̀, ti o ti fi ẹmú mu lati ori pẹpẹ wá.
Isa 6:7 (YBCV)
O si fi kàn mi li ẹnu, o si wipe, Kiyesi i, eyi ti kàn etè rẹ, a mu aiṣedede rẹ kuro, a si fọ ẹ̀ṣẹ rẹ nù.
Isa 6:8 (YBCV)
Emi si gbọ́ ohùn Oluwa pẹlu wipe, Tali emi o rán, ati tani yio si lọ fun wa? Nigbana li emi wipe, Emi nĩ; rán mi.
Isa 6:9 (YBCV)
On si wipe, Lọ, ki o si wi fun awọn enia yi, Ni gbigbọ́, ẹ gbọ́, ṣugbọn oye ki yio ye nyin; ni riri, ẹ ri, ṣugbọn ẹnyin ki yio si mọ̀ oye.
Isa 6:10 (YBCV)
Mu ki aiya awọn enia yi ki o sebọ́, mú ki eti wọn ki o wuwo, ki o si di wọn li oju, ki nwọn ki o má ba fi eti wọn gbọ́, ki nwọn ki o má ba fi ọkàn wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ki a má ba mu wọn li ara dá.
Isa 6:11 (YBCV)
Nigbana ni emi wipe, Oluwa, yio ti pẹ to? O si dahùn pe, Titi awọn ilu-nla yio fi di ahoro, li aisi olugbe, ati awọn ile li aisi enia, ati ilẹ yio di ahoro patapata.