Àwọn èsì àwárí fún: 1 Chronicles 15
I. Kro 15:1 (YBCV)
DAFIDI si kọ́ ile fun ara rẹ̀ ni ilu Dafidi, o si pese ipò kan fun apoti ẹri Ọlọrun, o si pa agọ kan fun u.
I. Kro 15:2 (YBCV)
Nigbana ni Dafidi wipe, Ẹnikan kò yẹ lati rù apoti ẹri Ọlọrun bikoṣe awọn ọmọ Lefi; nitori awọn ni Oluwa ti yàn lati ma gbé apoti ẹri Ọlọrun, ati lati ma ṣe iranṣẹ fun u titi lai.
I. Kro 15:3 (YBCV)
Dafidi si ko gbogbo Israeli jọ si Jerusalemu, lati gbé apoti ẹri Oluwa gòke lọ si ipò rẹ̀ ti o ti pese fun u.
I. Kro 15:4 (YBCV)
Dafidi si pè awọn ọmọ Aaroni, ati awọn ọmọ Lefi jọ.
I. Kro 15:5 (YBCV)
Ninu awọn ọmọ Kohati; Urieli olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ ọgọfa:
I. Kro 15:6 (YBCV)
Ninu awọn ọmọ Merari; Asaiah olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ igba o le ogun:
I. Kro 15:7 (YBCV)
Ninu awọn ọmọ Gerṣomu; Joeli olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ ãdoje:
I. Kro 15:8 (YBCV)
Ninu awọn ọmọ Elisafani; Ṣemaiah olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ igba.
I. Kro 15:9 (YBCV)
Ninu awọn ọmọ Hebroni; Elieli olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ ọgọrin:
I. Kro 15:10 (YBCV)
Ninu awọn ọmọ Ussieli; Aminadabu olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ mejilelãdọfa.
I. Kro 15:11 (YBCV)
Dafidi si ranṣẹ pè Sadoku ati Abiatari awọn alufa; ati awọn ọmọ Lefi, Urieli, Asaiah, ati Joeli, Ṣemaiah, ati Elieli, ati Aminadabu;
I. Kro 15:12 (YBCV)
O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li olori awọn baba awọn ọmọ Lefi: ẹ ya ara nyin si mimọ́, ẹnyin ati awọn arakunrin nyin, ki ẹnyin ki o le gbé apoti ẹri Oluwa Ọlọrun Israeli gòke lọ si ibi ti mo ti pèse fun u.
I. Kro 15:13 (YBCV)
Nitoriti ẹnyin kò rù u li akọṣe, ni Oluwa Ọlọrun wa fi ṣe ẹ̀ya si wa li ara, nitori awa kò wá a bi o ti yẹ.
I. Kro 15:14 (YBCV)
Bẹ̃ li awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi ya ara wọn si mimọ́ lati gbe apoti ẹri Oluwa Ọlọrun Israeli gòke wá.
I. Kro 15:15 (YBCV)
Awọn ọmọ Lefi si rù apoti ẹri Ọlọrun bi Mose ti pa a li aṣẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, nwọn fi ọpa rù u li ejika wọn.
I. Kro 15:16 (YBCV)
Dafidi si wi fun olori awọn ọmọ Lefi pe ki nwọn yàn awọn arakunrin wọn, awọn akọrin pẹlu ohun èlo orin, psalteri ati duru, ati kimbali; ti ndún kikan ti o si nfi ayọ gbé ohùn soke.
I. Kro 15:17 (YBCV)
Bẹ̃ li awọn ọmọ Lefi yan Hemani ọmọ Joeli; ati ninu awọn arakunrin rẹ̀, Asafu ọmọ Berekiah; ati ninu awọn ọmọ Merari arakunrin wọn, Etani ọmọ Kuṣaiah;
I. Kro 15:18 (YBCV)
Ati pẹlu wọn awọn arakunrin wọn li ọwọ́ keji; Sekariah, Beni, ati Jaasieli, ati Ṣemiramotu, ati Jehieli, ati Unni, Eliabu, ati Benaiah, ati Maaseiah, ati Obed-Edomu, ati Jeieli awọn adena.
I. Kro 15:19 (YBCV)
Awọn akọrin si ni Hemani, Asafu, ati Etani, ti awọn ti kimbali ti ndun kikan;
I. Kro 15:20 (YBCV)
Ati Sekariah, ati Asieli, ati Ṣemiramotu, ati Jelieli, ati Unni, ati Eliabu, ati Maaseiah, ati Benaiah, ti awọn ti psaltiri olohùn òke;
I. Kro 15:21 (YBCV)
Ati Mattitiah, ati Elifeleti, ati Mikneiah, lati fi duru olokun mẹjọ ṣaju orin.
I. Kro 15:22 (YBCV)
Ati Kenaniah, olori awọn ọmọ Lefi ni ọ̀ga orin: on ni nkọni li orin, nitoriti o moye rẹ̀.
I. Kro 15:23 (YBCV)
Ati Berekiah, ati Elkana li awọn adena fun apoti ẹri na.
I. Kro 15:24 (YBCV)
Ati Ṣebaniah, ati Jehoṣafati, ati Netaneeli, ati Amasai, ati Sekariah, ati Benaiah, ati Elieseri, awọn alufa, li o nfun ipè niwaju apoti ẹri Ọlọrun: ati Obed-Edomu, ati Jehiah li awọn adena fun apoti ẹri na.
I. Kro 15:25 (YBCV)
Bẹ̃ni Dafidi ati awọn agbagba Israeli, ati awọn olori ẹgbẹgbẹrun, lọ lati gbe apoti ẹri majẹmu Oluwa jade ti ile Obed-Edomu gòke wá pẹlu ayọ̀.