2,643,350ti d'ara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ náà
Ìyípadà Ọlọ́gbọ̀n Ọjọ́ nípasẹ̀ Bíbélí

Oṣù Bélú jẹ́ Oṣù Bíbélì Ní Àgbáyé
Ní Ìrírí
Ìwé tí àwọn ènìyàn ká jùlọ
ní gbogbo ìgbà
Kò ì tíì sí ìwé mìíràn tí ó ní agbára tó bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú imisi, tí ó sì ń yí ìgbésí ayé ènìyàn padà bí i ti Bíbélì. Ní oṣù Bélú yìí, darapọ̀ mọ́ ètò àgbáyé bí àwọn ẹ̀ka iṣẹ́-ìránṣẹ́, àwọn ilé-iṣẹ́, àti àwọn ohun-èlò Bíbélì ṣe ń kóra jọ láti ṣe àjọyọ̀ agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tìì yí ẹni padà, tìì yí ìgbésí ayé padà, tí ó sì kọjá àkókò.
Àwọ́n alájọṣiṣẹ́

Ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú ìpèníjà Bíbélì ọlọ́gbọ̀n ọjọ́
Wòye ohun tí yìó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà tì áwọn ènìyàn káàkiri ayé bá péjọ láti jíròrò nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní oṣù Bélú. Ìpèníjà Bíbélì ọlọ́gbọ̀n ọjọ́ jẹ́ ọ̀nà kan fún wa láti mọ̀. Darapọ mọ gbogbo agbáyé nípa fífi ara jìn fún ìjíròrò ojoojúmọ́ láti inú Ìwé Mímọ́ fún ọgbọ̀n ọjọ́.
