Sef 3:6-8
Sef 3:6-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mo ti ke awọn orilẹ-ède kuro; ile giga wọn dahoro; mo sọ ita wọnni di ofo, tobẹ̃ ti ẹnikan kò kọja ihà ibẹ̀: a pa ilu wọnni run, tobẹ̃ ti kò si enia kan, ti kò si ẹniti ngbe ibẹ̀. Emi wipe, Lõtọ iwọ o bẹ̀ru mi, iwọ o gba ẹkọ́; bẹ̃ni a kì ba ti ke ibujoko wọn kuro, bi o ti wù ki mo jẹ wọn ni iyà to: ṣugbọn nwọn dide ni kùtukùtu, nwọn ba gbogbo iṣẹ wọn jẹ. Nitorina ẹ duro dè mi, ni Oluwa wi, titi di ọjọ na ti emi o dide si ohun-ọdẹ: nitori ipinnu mi ni lati kó awọn orilẹ-ède jọ, ki emi ki o le kó awọn ilẹ ọba jọ, lati dà irúnu mi si ori wọn, ani gbogbo ibinu mi gbigbona: nitori a o fi iná owu mi jẹ gbogbo aiye run.
Sef 3:6-8 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA wí pé: “Mo ti pa àwọn orílẹ̀-èdè run; ilé-ìṣọ́ wọn sì ti di àlàpà; mo ti ba àwọn ìgboro wọn jẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè rìn níbẹ̀; àwọn ìlú wọn ti di ahoro, láìsí olùgbé kankan níbẹ̀. Mo ní, ‘Dájúdájú, wọn óo bẹ̀rù mi, wọn óo gba ìbáwí, wọn óo sì fọkàn sí gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún wọn.’ Ṣugbọn, ń ṣe ni wọ́n ń múra kankan, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ibi.” Nítorí náà, OLUWA ní, “Ẹ dúró dè mí di ọjọ́ tí n óo dìde bí ẹlẹ́rìí. Mo ti pinnu láti kó àwọn orílẹ̀-èdè ati àwọn ìjọba jọ, láti jẹ́ kí wọn rí ibinu mi, àní ibinu gbígbóná mi; gbogbo ayé ni yóo sì parun nítorí ìrúnú gbígbóná mi.
Sef 3:6-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Èmi ti ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò, ilé gíga wọn sì ti bàjẹ́. Mo ti fi ìgboro wọn sílẹ̀ ní òfo tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnìkankan kò kọjá níbẹ̀. Ìlú wọn parun tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnìkan tí yóò ṣẹ́kù, kò sì ní sí ẹnìkan rárá. Èmi wí fún ìlú náà wí pé ‘Nítòótọ́, ìwọ yóò bẹ̀rù mi, ìwọ yóò sì gba ìtọ́ni!’ Bẹ́ẹ̀ ni, a kì yóò ké ibùgbé rẹ̀ kúrò bí ó ti wù kí ń jẹ wọ́n ní yà tó. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ wọ́n sì tún ní ìtara láti ṣe ìbàjẹ́. Nítorí náà ẹ dúró dè mí,” ni OLúWA wí, “títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò fi jẹ́rìí sí yin; nítorí ìpinnu mi ni láti kó orílẹ̀-èdè jọ kí èmi kí ó lè kó ilẹ̀ ọba jọ àti láti da ìbínú mi jáde sórí wọn, àní gbogbo ìbínú gbígbóná mi. Nítorí, gbogbo ayé ni a ó fi iná owú mi jẹ run.