Sef 3:14-20
Sef 3:14-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kọrin, iwọ ọmọbinrin Sioni; kigbe, iwọ Israeli; fi gbogbo ọkàn yọ̀, ki inu rẹ ki o si dùn, iwọ ọmọbinrin Jerusalemu. Oluwa ti mu idajọ rẹ wọnni kuro, o ti tì ọta rẹ jade: ọba Israeli, ani Oluwa, mbẹ lãrin rẹ: iwọ kì yio si ri ibi mọ. Li ọjọ na a o wi fun Jerusalemu pe, Iwọ má bẹ̀ru: ati fun Sioni pe, Má jẹ ki ọwọ́ rẹ ki o dẹ̀. Oluwa Ọlọrun rẹ li agbara li ãrin rẹ; yio gbà ni là, yio yọ̀ li ori rẹ fun ayọ̀; yio simi ninu ifẹ rẹ̀, yio fi orin yọ̀ li ori rẹ. Emi o kó awọn ti o banujẹ fun ajọ mimọ́ jọ awọn ti o jẹ tirẹ, fun awọn ti ẹgàn rẹ̀ jasi ẹrù. Kiyesi i, nigbana li emi o ṣe awọn ti npọn ọ li oju: emi a gbà atiro là, emi o si ṣà ẹniti a le jade jọ; emi o si sọ wọn di ẹni iyìn ati olokìki ni gbogbo ilẹ ti a ti gàn wọn. Nigbana li emi o mu nyin padà wá, ani li akokò na li emi o ṣà nyin jọ: nitori emi o fi orukọ ati iyìn fun nyin lãrin gbogbo enia agbaiye, nigbati emi o yi igbèkun nyin padà li oju nyin, ni Oluwa wi.
Sef 3:14-20 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ kọrin sókè, kí ẹ sì hó; ẹ̀yin ọmọ Israẹli! Ẹ máa yọ̀ kí inú yín sì dùn gidigidi, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! OLUWA ti mú ẹ̀bi yín kúrò, ó sì ti lé àwọn ọ̀tá yín lọ. OLUWA, ọba Israẹli wà lọ́dọ̀ yín; ẹ kò sì ní bẹ̀rù ibi mọ́. Ní ọjọ́ náà, a óo sọ fún Jerusalẹmu pé: “Ẹ má ṣe fòyà; ẹ má sì ṣe jẹ́ kí agbára yín dínkù. OLUWA Ọlọrun yín wà lọ́dọ̀ yín, akọni tí ń fúnni ní ìṣẹ́gun ni; yóo láyọ̀ nítorí yín, yóo tún yín ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ si yín, yóo yọ̀, yóo sì kọrin ayọ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àjọ̀dún.” OLUWA ní: “N óo mú ibi kúrò lórí yín, kí ojú má baà tì yín. N óo wá kọlu àwọn ọ̀tá yín, n óo gba àwọn arọ là, n óo sì kó àwọn tí a ti fọ́nká jọ. N óo yí ìtìjú wọn pada sí ògo gbogbo aráyé ni yóo máa bu ọlá fún wọn. N óo wá mu yín pada wálé nígbà náà, nígbà tí mo bá ko yín jọ tán: n óo sọ yín di eniyan pataki ati ẹni iyì láàrin gbogbo ayé, nígbà tí mo bá dá ire yín pada lójú yín, Èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀.”
Sef 3:14-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Sioni, kígbe sókè, ìwọ Israẹli! Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu. OLúWA ti mú ìdájọ́ rẹ wọ̀n-ọn-nì kúrò, ó sì ti ti àwọn ọ̀tá rẹ padà sẹ́yìn. OLúWA, ọba Israẹli wà pẹ̀lú rẹ, Ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù ibi kan mọ́. Ní ọjọ́ náà, wọn yóò sọ fún Jerusalẹmu pé, “Má ṣe bẹ̀rù Sioni; má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀. OLúWA Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, Ó ní agbára láti gbà ọ là. Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀; Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀, Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.” “Èmi ó kó àwọn tí ó ń banújẹ́ fún àjọ̀dún tí a yàn jọ, àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀; àwọn tí ẹ̀gàn rẹ̀ jásí ẹ̀rù. Ní àkókò náà ni èmi yóò dojúkọ àwọn tí ń ni yín lára, èmi yóò gba àtiro là, èmi yóò sì ṣa àwọn tí ó ti fọ́nká jọ, èmi yóò fi ìyìn àti ọlá fún wọn ní gbogbo ilẹ̀ tí a bá ti dójútì wọ́n. Ní àkókò náà ni èmi yóò ṣà yín jọ; Nígbà náà ni èmi yóò mú un yín padà wá sílé. Èmi yóò fi ọlá àti ìyìn fún un yín láàrín gbogbo ènìyàn àgbáyé, nígbà tí èmi yóò yí ìgbèkùn yín padà bọ sípò ní ojú ara yín,” ni OLúWA wí.