Sef 1:2-6
Sef 1:2-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa wipe, emi o mu gbogbo nkan kuro lori ilẹ na patapata. Emi o mu enia ati ẹranko kuro; emi o mu ẹiyẹ oju ọrun kuro, ati ẹja inu okun, ati ohun idigbòlu pẹlu awọn enia buburu; emi o si ké enia kuro lori ilẹ, ni Oluwa wi. Emi o nà ọwọ́ mi pẹlu sori Juda, ati sori gbogbo ara Jerusalemu; emi o si ké iyokù Baali kuro nihinyi, ati orukọ Kemarimu pẹlu awọn alufa; Ati awọn ti nsìn ogun ọrun lori orule: awọn ti nsìn, ti nfi Oluwa bura, ti si nfi Malkomu bura; Ati awọn ẹniti o yipadà kuro lọdọ Oluwa; ati awọn ẹniti kò ti wá Oluwa, bẹ̃ni nwọn kò si bère rẹ̀.
Sef 1:2-6 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “N óo pa gbogbo nǹkan tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé run: ati eniyan ati ẹranko, ati gbogbo ẹyẹ, ati gbogbo ẹja. N óo bi àwọn eniyan burúkú ṣubú; n óo pa eniyan run lórí ilẹ̀. “N óo na ọwọ́ ibinu mi sí ilẹ̀ Juda, ati sí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu. N óo pa gbogbo oriṣa Baali tí ó kù níhìn-ín run, ati gbogbo àwọn babalóòṣà wọn; ati àwọn tí ń gun orí òrùlé lọ láti bọ oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀. Wọ́n ń sin OLUWA wọ́n sì ń fi orúkọ rẹ̀ búra wọ́n sì tún ń fi oriṣa Milikomu búra; àwọn tí wọ́n ti pada lẹ́yìn OLUWA, tí wọn kò wá a, tí wọn kì í sì í wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀.”
Sef 1:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Èmi yóò mú gbogbo nǹkan kúrò lórí ilẹ̀ náà pátápátá,” ni OLúWA wí. “Èmi yóò mú ènìyàn àti ẹranko kúrò; èmi yóò mú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run kúrò àti ẹja inú Òkun, àti ohun ìdìgbòlù pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú; èmi yóò ké ènìyàn kúrò lórí ilẹ̀ ayé,” ni OLúWA wí. “Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Juda àti sórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu. Èmi yóò sì ké kúrò níhìn-ín-yìí ìyókù àwọn Baali, àti orúkọ àwọn abọ̀rìṣà pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà, àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ lórí òrùlé, àwọn tí ń sin ogun ọ̀run, àwọn tó ń foríbalẹ̀, tí wọ́n sì ń fi OLúWA búra, tí wọ́n sì ń fi Moleki búra. Àwọn tí ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ OLúWA; Àti àwọn tí kò tí wá OLúWA, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì béèrè rẹ̀.”