Sef 1:1-6
Sef 1:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Sefaniah wá ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedaliah, ọmọ Amariah, ọmọ Hisikiah, li ọjọ Josiah, ọmọ Amoni ọba Juda. Oluwa wipe, emi o mu gbogbo nkan kuro lori ilẹ na patapata. Emi o mu enia ati ẹranko kuro; emi o mu ẹiyẹ oju ọrun kuro, ati ẹja inu okun, ati ohun idigbòlu pẹlu awọn enia buburu; emi o si ké enia kuro lori ilẹ, ni Oluwa wi. Emi o nà ọwọ́ mi pẹlu sori Juda, ati sori gbogbo ara Jerusalemu; emi o si ké iyokù Baali kuro nihinyi, ati orukọ Kemarimu pẹlu awọn alufa; Ati awọn ti nsìn ogun ọrun lori orule: awọn ti nsìn, ti nfi Oluwa bura, ti si nfi Malkomu bura; Ati awọn ẹniti o yipadà kuro lọdọ Oluwa; ati awọn ẹniti kò ti wá Oluwa, bẹ̃ni nwọn kò si bère rẹ̀.
Sef 1:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Èyí ni iṣẹ́ tí Ọlọrun rán Sefanaya, ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedalaya, ọmọ Amaraya, ọmọ Hesekaya ní àkókò ìjọba Josaya, ọmọ Amoni, ọba Juda. OLUWA ní, “N óo pa gbogbo nǹkan tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé run: ati eniyan ati ẹranko, ati gbogbo ẹyẹ, ati gbogbo ẹja. N óo bi àwọn eniyan burúkú ṣubú; n óo pa eniyan run lórí ilẹ̀. “N óo na ọwọ́ ibinu mi sí ilẹ̀ Juda, ati sí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu. N óo pa gbogbo oriṣa Baali tí ó kù níhìn-ín run, ati gbogbo àwọn babalóòṣà wọn; ati àwọn tí ń gun orí òrùlé lọ láti bọ oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀. Wọ́n ń sin OLUWA wọ́n sì ń fi orúkọ rẹ̀ búra wọ́n sì tún ń fi oriṣa Milikomu búra; àwọn tí wọ́n ti pada lẹ́yìn OLUWA, tí wọn kò wá a, tí wọn kì í sì í wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀.”
Sef 1:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀ OLúWA tí ó tọ Sefaniah ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedaliah, ọmọ Amariah, ọmọ Hesekiah, ní ìgbà Josiah ọmọ Amoni ọba Juda. “Èmi yóò mú gbogbo nǹkan kúrò lórí ilẹ̀ náà pátápátá,” ni OLúWA wí. “Èmi yóò mú ènìyàn àti ẹranko kúrò; èmi yóò mú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run kúrò àti ẹja inú Òkun, àti ohun ìdìgbòlù pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú; èmi yóò ké ènìyàn kúrò lórí ilẹ̀ ayé,” ni OLúWA wí. “Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Juda àti sórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu. Èmi yóò sì ké kúrò níhìn-ín-yìí ìyókù àwọn Baali, àti orúkọ àwọn abọ̀rìṣà pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà, àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ lórí òrùlé, àwọn tí ń sin ogun ọ̀run, àwọn tó ń foríbalẹ̀, tí wọ́n sì ń fi OLúWA búra, tí wọ́n sì ń fi Moleki búra. Àwọn tí ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ OLúWA; Àti àwọn tí kò tí wá OLúWA, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì béèrè rẹ̀.”