Sek 8:3-8
Sek 8:3-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bayi li Oluwa wi; Mo ti yipada si Sioni emi o si gbe ãrin Jerusalemu: a o si pè Jerusalemu ni ilu nla otitọ; ati oke nla Oluwa awọn ọmọ-ogun, okenla mimọ́ nì. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, arugbo ọkunrin ati arugbo obinrin, yio sa gbe igboro Jerusalemu, ati olukuluku ti on ti ọ̀pa li ọwọ rẹ̀ fun ogbó. Igboro ilu yio si kún fun ọmọdekunrin, ati ọmọdebinrin, ti nṣire ni ita wọn. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, bi o ba ṣe iyanu li oju iyokù awọn enia yi li ọjọ wọnyi, iba jẹ iyanu li oju mi pẹlu bi? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, Kiye si i, emi o gbà awọn enia mi kuro ni ilẹ ila-õrun, ati kuro ni ilẹ yama; Emi o si mu wọn wá, nwọn o si ma gbe ãrin Jerusalemu: nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn, li otitọ, ati li ododo.
Sek 8:3-8 Yoruba Bible (YCE)
Ó ní, òun óo pada sí Sioni, òun óo máa gbé Jerusalẹmu, a óo máa pe Jerusalẹmu ní ìlú olóòótọ́, òkè OLUWA àwọn ọmọ ogun, ati òkè mímọ́. Àwọn arúgbó lọkunrin, lobinrin, tí wọn ń tẹ̀pá yóo jókòó ní ìgboro Jerusalẹmu, ìta ati òpópónà yóo sì kún fún àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin tí wọn ń ṣeré. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní bí eléyìí bá jẹ́ ohun ìyanu lójú àwọn eniyan yòókù, ǹjẹ́ ó yẹ kí ó jẹ́ ohun ìyanu lójú òun náà? Ó ní òun óo gba àwọn eniyan òun là láti orílẹ̀-èdè tí ó wà ní ìlà oòrùn ati ti ìwọ̀ rẹ̀, òun óo mú wọn pada wá sí Jerusalẹmu láti máa gbébẹ̀; wọn óo jẹ́ eniyan òun, òun náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn, lóòótọ́ ati lódodo.
Sek 8:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báyìí ni OLúWA wí: “Mo yípadà sí Sioni èmi ó sì gbé àárín Jerusalẹmu: Nígbà náà ni a ó sì pé Jerusalẹmu ni ìlú ńlá òtítọ́; àti òkè ńlá OLúWA àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè ńlá mímọ́.” Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Arúgbó ọkùnrin, àti arúgbó obìnrin, yóò gbé ìgboro Jerusalẹmu, àti olúkúlùkù pẹ̀lú ọ̀pá ni ọwọ́ rẹ̀ fún ogbó. Ìgboro ìlú yóò sì kún fún ọmọdékùnrin, àti ọmọdébìnrin, tí ń ṣiré ní ìta wọn.” Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Bí ó bá ṣe ìyanu ní ojú ìyókù àwọn ènìyàn yìí ni ọjọ́ wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó ha lè jẹ́ ìyanu ni ojú mi bí?” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. Báyìí ní OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Kíyèsi i, èmi ó gba àwọn ènìyàn mi kúrò ni ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti kúrò ni ilẹ̀ ìwọ̀-oòrùn. Èmi ó sì mú wọn padà wá, wọn ó sì máa gbé àárín Jerusalẹmu. Wọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ní òtítọ́, àti ní òdodo.”