Sek 7:1-7
Sek 7:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe li ọdun kẹrin Dariusi ọba, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Sekariah wá ni ijọ kẹrin oṣù kẹsan, Kislefi; Nigbati nwọn rán Ṣereṣeri ati Regemmeleki, ati awọn enia wọn si ile Ọlọrun lati wá oju rere Oluwa. Ati lati bá awọn alufa ti o wà ni ile Oluwa awọn ọmọ-ogun, ati awọn woli sọ̀rọ, wipe, Ki emi ha sọkun li oṣù karun, ki emi ya ara mi sọtọ, bi mo ti nṣe lati ọdun melo wonyi wá? Nigbana li ọ̀rọ Oluwa awọn ọmọ-ogun tọ̀ mi wá wipe, Sọ fun gbogbo awọn enia ilẹ na, ati fun awọn alufa, wipe, Nigbati ẹnyin gbawẹ̀ ti ẹ si ṣọ̀fọ li oṣù karun ati keje, ani fun ãdọrin ọdun wọnni, ẹnyin ha gbawẹ̀ si mi rara, ani si emi? Nigbati ẹ si jẹ, ati nigbati ẹ mu, fun ara nyin ki ẹnyin ha jẹ, ati fun ara nyin ki ẹnyin ha mu? Wọnyi kì ọ̀rọ ti Oluwa ti kigbe lati ọdọ awọn woli iṣãju wá, nigbati a ngbe Jerusalemu, ti o si wà li alafia, pẹlu awọn ilu rẹ̀ ti o yi i ka kiri, nigbati a ngbe gusù ati pẹtẹlẹ?
Sek 7:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹsan-an, tíí ṣe oṣù Kisilefi, ní ọdún kẹrin ìjọba Dariusi, ni OLUWA rán mi níṣẹ́ yìí. Àwọn ará Bẹtẹli rán Ṣareseri ati Regemumeleki ati gbogbo àwọn eniyan wọn lọ sí ilé OLUWA; wọ́n lọ wá ojurere OLUWA, wọn sì lọ bèèrè lọ́wọ́ àwọn alufaa ilé OLUWA, àwọn ọmọ ogun ati àwọn wolii pé, “Nígbà wo ni a óo dẹ́kun láti máa ṣọ̀fọ̀, ati láti máa gbààwẹ̀ ní oṣù karun-un bí a ti ń ṣe láti ọpọlọpọ ọdún sẹ́yìn?” OLUWA àwọn ọmọ ogun bá rán mi pé, “Sọ fún gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ náà ati àwọn alufaa pé, nígbà tí ẹ̀ ń gbààwẹ̀, tí ẹ sì ń ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karun-un ati oṣù keje fún odidi aadọrin ọdún, ṣé èmi ni ẹ̀ ń gbààwẹ̀ fún? Tabi nígbà tí ẹ̀ ń jẹ tí ẹ sì ń mu, kì í ṣe ara yín ni ẹ̀ ń jẹ tí ẹ̀ ń mu fún?” Nígbà tí nǹkan fi ń dára fún Jerusalẹmu, tí eniyan sì pọ̀ níbẹ̀, ati àwọn ìlú agbègbè tí ó yí i ká, ati àwọn ìlú ìhà gúsù ati ti ẹsẹ̀ òkè ní ìwọ̀ oòrùn; ṣebí àwọn wolii OLUWA ti sọ nǹkan wọnyi tẹ́lẹ̀?
Sek 7:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ṣe ní ọdún kẹrin Dariusi ọba, ọ̀rọ̀ OLúWA tọ́ Sekariah wá ni ọjọ́ kẹrin oṣù Kisleu tí ń ṣe oṣù kẹsànán. Nígbà tí wọ́n ènìyàn Beteli rán Ṣareseri àti Regemmeleki, àti àwọn ènìyàn wọn sí ilé Ọlọ́run láti wá ojúrere OLúWA. Àti láti bá àwọn àlùfáà tí ó wà ní ilé OLúWA àwọn ọmọ-ogun, àti àwọn wòlíì sọ̀rọ̀ wí pé, “Ṣé kí èmi ó sọkún ní oṣù karùn-ún kí èmi ya ara mi sọ́tọ̀, bí mo ti ń ṣe láti ọdún mélòó wọ̀nyí wá bí?” Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLúWA àwọn ọmọ-ogun tọ̀ mí wá pé, “Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti fún àwọn àlùfáà pé, ‘Nígbà tí ẹ̀yin gbààwẹ̀, tí ẹ sì ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karùn-ún àti keje, àní fun àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, ǹjẹ́ èmi ni ẹ̀yin ha ń gbààwẹ̀ yín fún? Nígbà tí ẹ sì jẹ, àti nígbà tí ẹ mu, fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin jẹ, àti fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin mú bí? Wọ̀nyí kọ́ ni ọ̀rọ̀ ti OLúWA ti kígbe láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì ìṣáájú wá, nígbà tí a ń gbé Jerusalẹmu, tí ó sì wà ní àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀ tí ó yí i káàkiri, nígbà tí a ń gbé gúúsù àti pẹ̀tẹ́lẹ̀.’ ”