Sek 5:1-3
Sek 5:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni mo yipadà, mo si gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, iwe-kiká ti nfò. O si wi fun mi pe, Kini iwọ ri? Emi si dahùn pe, mo ri iwe-kiká ti nfò; gigùn rẹ̀ jẹ ogún igbọnwọ, ibú rẹ̀ si jẹ igbọnwọ mẹwa. O si wi fun mi pe, Eyi ni ègun ti o jade lọ si gbogbo ilẹ aiye: nitori gbogbo awọn ti o ba jale ni a o ke kuro lati ihin lọ nipa rẹ̀; gbogbo awọn ti o ba si bura ni a o ke kuro lati ihin lọ nipa rẹ̀.
Sek 5:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Mo tún gbé ojú sókè, mo bá rí ìwé kíká kan tí ń fò ní òfuurufú. Angẹli náà bi mí pé, “Kí ni o rí?” Mo bá dáhùn pé “Mo rí ìwé kíká kan tí ń fò ní òfuurufú. Ìwé náà gùn ní ìwọ̀n ogún igbọnwọ, (mita 9); ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½).” Ó bá sọ fún mi pé, “Ègún tí yóo máa káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà ni a kọ sinu ìwé yìí. Láti ìsinsìnyìí lọ, ẹnikẹ́ni tí ó bá jalè ati ẹnikẹ́ni tí ó bá búra èké, a óo yọ orúkọ rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ náà.”
Sek 5:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni mo yípadà, mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ìwé kíká ti ń fò. Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?” Èmi sì dáhùn pé, “Mo rí ìwé kíká tí ń fò; gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.” Ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ègún tí ó jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé: nítorí gbogbo àwọn tí ó bá jalè ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀; gbogbo àwọn tí ó bá sì búra èké ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀.