Sek 4:1-6
Sek 4:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
ANGELI ti o mba mi sọ̀rọ si tún de, o si ji mi, bi ọkunrin ti a ji lati oju orun rẹ̀, O si wi fun mi pe, Kini iwọ ri? Mo si wipe, mo wò, si kiyesi i, ọ̀pa fitilà ti gbogbo rẹ̀ jẹ wurà, pẹlu kòjo rẹ̀ lori rẹ̀, pẹlu fitilà meje rẹ̀ lori rẹ̀, ati àrọ meje fun fitilà mejeje, ti o wà lori rẹ̀: Igi olifi meji si wà leti rẹ̀, ọkan li apa ọtun kòjo na, ati ekeji li apa osì rẹ̀. Mo si dahùn mo si wi fun angeli ti o mba mi sọ̀rọ, pe, Kini wọnyi, Oluwa mi? Angeli ti o mba mi sọ̀rọ dahùn o si wi fun mi pe, Iwọ kò mọ̀ ohun ti awọn wọnyi jasi? Mo si wipe, Nkò mọ̀, oluwa mi. O si dahùn o si wi fun mi pe, Eyi ni ọ̀rọ Oluwa si Serubbabeli wipe, Kì iṣe nipa ipá, kì iṣe nipa agbara, bikoṣe nipa Ẹmi mi, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Sek 4:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ tún pada wá, ó jí mi bí ẹni pé mo sùn. Ó bi mí pé kí ni mo rí. Mo dáhùn pé, “Mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà, àwo kan sì wà lórí rẹ̀. Fìtílà meje wà lórí ọ̀pá náà, fìtílà kọ̀ọ̀kan sì ní òwú fìtílà meje. Igi olifi meji wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fìtílà náà, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwo náà, ọ̀kan ní apá òsì.” Nígbà náà ni mo bi angẹli náà pé, “OLUWA mi, Kí ni ìtumọ̀ àwọn kinní wọnyi?” Ó bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ṣé o kò mọ ìtumọ̀ wọn ni?” Mo dáhùn pé, “Rárá, oluwa mi, n kò mọ̀ ọ́n.” Angẹli náà sọ fún mi pé, “Iṣẹ́ tí OLUWA àwọn ọmọ ogun rán sí Serubabeli ni pé, ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bíkòṣe nípa ẹ̀mí mi.
Sek 4:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ sì tún dé, ó sì jí mi, bí ọkùnrin tí a jí lójú oorun rẹ̀, Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?” Mo sì wí pé, “Mo wò, sì kíyèsi i, ọ̀pá fìtílà tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ wúrà, pẹ̀lú àwokòtò rẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú fìtílà méje rẹ̀ lórí rẹ̀, àti ẹnu méje fún fìtílà méjèèje, tí ó wà lórí rẹ̀: Igi olifi méjì sì wà létí rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwokòtò náà, àti èkejì ní apá òsì rẹ̀.” Mo sì dáhùn mo sì wí fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀, pé, “Kín ni wọ̀nyí, olúwa mi?” Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?” Mo sì wí pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n, olúwa mi.” Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ OLúWA sí Serubbabeli tó wí pé: ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò ṣe nípa Ẹ̀mí mi,’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí.