Sek 3:1-2
Sek 3:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
O sì fi Joṣua olori alufa hàn mi, o duro niwaju angeli Oluwa, Satani si duro lọwọ ọtun rẹ̀ lati kọju ijà si i. Oluwa si wi fun Satani pe, Oluwa ba ọ wi, iwọ Satani; ani Oluwa ti o ti yàn Jerusalemu, o ba ọ wi: igi iná kọ eyi ti a mu kuro ninu iná?
Sek 3:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà, OLUWA fi Joṣua olórí alufaa hàn mí; ó dúró níwájú angẹli OLUWA, Satani sì dúró lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti fi ẹ̀sùn kàn án. Angẹli OLUWA sọ fún Satani pé, “OLUWA óo bá ọ wí, ìwọ Satani! OLUWA tí ó yan Jerusalẹmu óo bá ọ wí! Ṣebí ẹ̀ka igi tí a yọ jáde láti inú iná ni ọkunrin yìí?”
Sek 3:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì fi Joṣua olórí àlùfáà hàn mí, ó dúró níwájú angẹli OLúWA, Satani sí dúró lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti kọjú ìjà sí i. OLúWA si wí fún Satani pé, “OLúWA bá ọ wí ìwọ Satani; àní OLúWA tí ó ti yan Jerusalẹmu, bá ọ wí, igi iná kọ́ ni èyí tí a mú kúrò nínú iná?”