Sek 2:10-13
Sek 2:10-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kọrin ki o si yọ̀, iwọ ọmọbinrin Sioni: sa wò o, mo de, emi o si gbe ãrin rẹ, ni Oluwa wi. Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède ni yio dapọ̀ mọ Oluwa li ọjọ na, nwọn o si di enia mi; emi o si gbe ãrin rẹ, iwọ o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi si ọ. Oluwa o si jogún Juda iní rẹ̀, nilẹ̀ mimọ́, yio si tun yàn Jerusalemu. Ẹ dakẹ, gbogbo ẹran-ara niwaju Oluwa: nitori a ji i lati ibùgbe mimọ́ rẹ̀ wá.
Sek 2:10-13 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Ẹ kọrin ayọ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí inú yín máa dùn, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, nítorí pé mò ń bọ̀ wá máa ba yín gbé. Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ni yóo parapọ̀ láti di eniyan mi nígbà náà. N óo máa gbé ààrin yín; ẹ óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo ranṣẹ si yín. N óo jogún Juda bí ohun ìní mi ninu ilẹ̀ mímọ́, n óo sì yan Jerusalẹmu.” Ẹ̀yin eniyan, ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA, nítorí ó ń jáde bọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀.
Sek 2:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Kọrin kí o sì yọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni: Nítorí èmi ń bọ̀ àti pé èmi yóò sì gbé àárín rẹ,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò dàpọ̀ mọ́ OLúWA ní ọjọ́ náà, wọn yóò sì di ènìyàn mi: èmi yóò sì gbé àárín rẹ, ìwọ yóò sì mọ̀ pé, OLúWA àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí ọ. OLúWA yóò sì jogún Juda ìní rẹ̀, ni ilẹ̀ mímọ́, yóò sì tún yan Jerusalẹmu. Ẹ̀ dákẹ́, gbogbo ẹran-ara níwájú OLúWA: nítorí a jí i láti ibùgbé mímọ́ rẹ̀ wá.”