Sek 14:8-9
Sek 14:8-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Yio si ṣe li ọjọ na, omi iyè yio ti Jerusalemu ṣàn lọ; idajì wọn sihà kun ilà-õrun, ati idajì wọn sihà okun ẹhìn: nigbà ẹ̀run ati nigbà otutù ni yio ri bẹ̃. Oluwa yio si jọba lori gbogbo aiye: li ọjọ na ni Oluwa kan yio wà, orukọ rẹ̀ yio si jẹ ọkan.
Sek 14:8-9 Yoruba Bible (YCE)
Tó bá di ìgbà náà, àwọn odò tí wọ́n kún fún omi ìyè yóo máa ṣàn jáde láti Jerusalẹmu. Apá kan wọn yóo máa ṣàn lọ sinu òkun tí ó wà ní ìwọ̀ oòrùn, apá keji yóo máa ṣàn lọ sí òkun tí ó wà ní ìlà oòrùn, yóo sì máa rí bẹ́ẹ̀ tòjò-tẹ̀ẹ̀rùn. OLUWA yóo wá jọba ní gbogbo ayé; Ọlọrun nìkan ni gbogbo aráyé yóo máa sìn nígbà náà, orúkọ kanṣoṣo ni wọn yóo sì mọ̀ ọ́n.
Sek 14:8-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, omi ìyè yóò tí Jerusalẹmu sàn lọ; ìdajì wọn síhà Òkun ìlà-oòrùn, àti ìdajì wọn síhà okùn ẹ̀yìn: nígbà ẹ̀rùn àti nígbà òtútù ni yóò rí bẹ́ẹ̀. OLúWA yóò sì jẹ ọba lórí gbogbo ayé; ni ọjọ́ náà ni OLúWA kan yóò wa orúkọ rẹ̀ nìkan náà ni orúkọ.