Sek 14:1-4
Sek 14:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
KIYESI i, ọjọ Oluwa mbọ̀, a o si pin ikogun rẹ lãrin rẹ. Nitori emi o kó gbogbo orilẹ-ède jọ si Jerusalemu fun ogun; a o si kó ilu na, a o si kó awọn ile, a o si bà awọn obinrin jẹ, abọ̀ ilu na yio lọ si igbèkun, a kì yio si ké iyokù awọn enia na kuro ni ilu na. Nigbana ni Oluwa yio jade lọ, yio si ba awọn orilẹ-ède wọnni jà, gẹgẹ bi iti ijà li ọjọ ogun. Ẹsẹ̀ rẹ̀ yio si duro li ọjọ na lori oke Olifi, ti o wà niwaju Jerusalemu ni ila-õrun, oke Olifi yio si là meji si ihà ila-õrun ati si ihà iwọ̀-õrun, afonifojì nlanla yio wà: idajì oke na yio si ṣi sihà ariwa, ati idajì rẹ̀ siha gusu.
Sek 14:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Wò ó! Ọjọ́ OLUWA ń bọ̀ tí wọn yóo pín àwọn ìkógun tí wọ́n kó ní ilẹ̀ Jerusalẹmu lójú yín. Nítorí n óo kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ láti gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. Wọn yóo ṣẹgun rẹ̀, wọn yóo kó àwọn eniyan ibẹ̀ lẹ́rù lọ, wọn yóo sì fi tipátipá bá àwọn obinrin wọn lòpọ̀. Ìdajì àwọn ará ìlú náà yóo lọ sóko ẹrú, ṣugbọn ìdajì yòókù ninu wọn yóo wà láàrin ìlú. OLUWA yóo wá jáde, yóo bá àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi jà, bí ìgbà tí ó ń jà lójú ogun. Tó bá di àkókò náà, yóo dúró lórí òkè olifi tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jerusalẹmu; òkè olifi yóo sì pín sí meji. Àfonífojì tí ó gbòòrò yóo sì wà láàrin rẹ̀ láti apá ìlà oòrùn dé apá ìwọ̀ oòrùn. Apá kan òkè náà yóo lọ ìhà àríwá, apá keji yóo sì lọ sí ìhà gúsù.
Sek 14:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kíyèsi i, ọjọ́ OLúWA ń bọ̀, a ó sì pín ìkógun rẹ̀ láàrín rẹ̀. Nítorí èmi ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí Jerusalẹmu fún ogun; a ó sì ko ìlú naà, a ó sì kó àwọn ilé, a ó sì ba àwọn obìnrin jẹ́, ààbọ̀ ìlú náà yóò lọ sí ìgbèkùn, a kì yóò sì gé ìyókù àwọn ènìyàn náà kúrò ni ìlú náà. Nígbà náà ni OLúWA yóò jáde lọ, yóò sì bá àwọn orílẹ̀-èdè náà jà, gẹ́gẹ́ bí í ti ìjà ní ọjọ́ ogun. Ẹsẹ̀ rẹ̀ yóò sì dúró ni ọjọ́ náà lórí òkè Olifi, tí ó wà níwájú Jerusalẹmu ni ìlà-oòrùn, òkè Olifi yóò sì là á sí méjì, sí ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn, Àfonífojì ńláńlá yóò wà: ìdajì òkè náà yóò sì ṣí síhà àríwá, àti ìdajì rẹ̀ síhà gúúsù.