Sek 14:1-21
Sek 14:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
KIYESI i, ọjọ Oluwa mbọ̀, a o si pin ikogun rẹ lãrin rẹ. Nitori emi o kó gbogbo orilẹ-ède jọ si Jerusalemu fun ogun; a o si kó ilu na, a o si kó awọn ile, a o si bà awọn obinrin jẹ, abọ̀ ilu na yio lọ si igbèkun, a kì yio si ké iyokù awọn enia na kuro ni ilu na. Nigbana ni Oluwa yio jade lọ, yio si ba awọn orilẹ-ède wọnni jà, gẹgẹ bi iti ijà li ọjọ ogun. Ẹsẹ̀ rẹ̀ yio si duro li ọjọ na lori oke Olifi, ti o wà niwaju Jerusalemu ni ila-õrun, oke Olifi yio si là meji si ihà ila-õrun ati si ihà iwọ̀-õrun, afonifojì nlanla yio wà: idajì oke na yio si ṣi sihà ariwa, ati idajì rẹ̀ siha gusu. Ẹnyin o si sá si afonifojì oke mi wọnni: nitoripe afonifoji oke na yio de Asali: nitõtọ, ẹnyin o sa bi ẹ ti sa fun ìṣẹ̀lẹ̀ nì li ọjọ Ussiah ọba Juda: Oluwa Ọlọrun mi yio si wá, ati gbogbo awọn Ẹni-mimọ́ pẹlu rẹ̀. Yio si ṣe li ọjọ na, imọlẹ kì yio mọ́, bẹ̃ni kì yio ṣõkùnkun. Ṣugbọn yio jẹ ọjọ kan mimọ̀ fun Oluwa, kì iṣe ọsan, kì iṣe oru; ṣugbọn yio ṣe pe, li aṣãlẹ imọlẹ yio wà. Yio si ṣe li ọjọ na, omi iyè yio ti Jerusalemu ṣàn lọ; idajì wọn sihà kun ilà-õrun, ati idajì wọn sihà okun ẹhìn: nigbà ẹ̀run ati nigbà otutù ni yio ri bẹ̃. Oluwa yio si jọba lori gbogbo aiye: li ọjọ na ni Oluwa kan yio wà, orukọ rẹ̀ yio si jẹ ọkan. A o yi gbogbo ilẹ padà bi pẹtẹlẹ kan lati Geba de Rimmoni lapa gusu Jerusalemu: a o si gbe e soke, yio si gbe ipò rẹ̀, lati ibode Benjamini titi de ibi ibode ekini, de ibode igun nì, ati lati ile iṣọ Hananeeli de ibi ifunti waini ọba. Enia yio si ma gbe ibẹ̀, kì yio si si iparun yanyan mọ; Ṣugbọn a o ma gbe Jerusalemu lailewu. Eyi ni yio si jẹ àrun ti Oluwa yio fi kọlu gbogbo awọn enia ti o ti ba Jerusalemu ja; ẹran-ara wọn yio rù nigbati wọn duro li ẹsẹ̀ wọn, oju wọn yio si rà ni ihò wọn, ahọn wọn yio si jẹrà li ẹnu wọn. Yio si ṣe li ọjọ na, irọkẹ̀kẹ nla lati ọdọ Oluwa wá yio wà lãrin wọn; nwọn o si dì ọwọ ara wọn mu, ọwọ rẹ̀ yio si dide si ọwọ ẹnikeji rẹ̀. Juda pẹlu yio si jà ni Jerusalemu; ọrọ̀ gbogbo awọn keferi ti o wà kakiri li a o si kojọ, wurà, ati fàdakà, ati aṣọ, li ọpọlọpọ. Bẹ̃ni àrun ẹṣin, ibãka, ràkumi, ati ti kẹtẹkẹtẹ, yio si wà, ati gbogbo ẹranko ti mbẹ ninu agọ wọnyi gẹgẹ bi àrun yi. Yio si ṣe, olukuluku ẹniti o kù ninu gbogbo awọn orilẹ-ède ti o dide si Jerusalemu yio ma goke lọ lọdọdun lati sìn Ọba, Oluwa awọn ọmọ-ogun, ati lati pa àse agọ wọnni mọ. Yio si ṣe, ẹnikẹni ti kì yio goke wá ninu gbogbo idile aiye si Jerusalemu lati sìn Ọba, Oluwa awọn ọmọ-ogun, fun wọn ni òjo kì yio rọ̀. Bi idile Egipti kò ba si goke lọ, ti nwọn kò si wá, ti kò ni òjo; àrun na yio wà, ti Oluwa yio fi kọlù awọn keferi ti kò goke wá lati pa àse agọ na mọ. Eyi ni yio si jẹ iyà Egipti, ati iyà gbogbo orilẹ-ède ti kò goke wá lati pa àse agọ mọ. Li ọjọ na ni MIMỌ SI OLUWA yio wà lara ṣaworo ẹṣin; ati awọn ikòko ni ile Oluwa yio si dàbi awọn ọpọ́n wọnni niwaju pẹpẹ. Nitõtọ, gbogbo ikòko ni Jerusalemu ati ni Juda yio jẹ mimọ́ si Oluwa awọn ọmọ-ogun: ati gbogbo awọn ti nrubọ yio wá, nwọn o si gbà ninu wọn, nwọn o si bọ̀ ninu rẹ̀: li ọjọ na ni ara Kenaani kì yio si si mọ ni ile Oluwa awọn ọmọ-ogun.
Sek 14:1-21 Yoruba Bible (YCE)
Wò ó! Ọjọ́ OLUWA ń bọ̀ tí wọn yóo pín àwọn ìkógun tí wọ́n kó ní ilẹ̀ Jerusalẹmu lójú yín. Nítorí n óo kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ láti gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. Wọn yóo ṣẹgun rẹ̀, wọn yóo kó àwọn eniyan ibẹ̀ lẹ́rù lọ, wọn yóo sì fi tipátipá bá àwọn obinrin wọn lòpọ̀. Ìdajì àwọn ará ìlú náà yóo lọ sóko ẹrú, ṣugbọn ìdajì yòókù ninu wọn yóo wà láàrin ìlú. OLUWA yóo wá jáde, yóo bá àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi jà, bí ìgbà tí ó ń jà lójú ogun. Tó bá di àkókò náà, yóo dúró lórí òkè olifi tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jerusalẹmu; òkè olifi yóo sì pín sí meji. Àfonífojì tí ó gbòòrò yóo sì wà láàrin rẹ̀ láti apá ìlà oòrùn dé apá ìwọ̀ oòrùn. Apá kan òkè náà yóo lọ ìhà àríwá, apá keji yóo sì lọ sí ìhà gúsù. Ẹ óo sá àsálà gba ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó pín òkè náà sí meji. Ẹ óo sá bí àwọn baba ńlá yín ti sá nígbà tí ilẹ̀ mì tìtì ní àkókò Usaya, ọba Juda, OLUWA, Ọlọrun yín yóo wá dé, pẹlu gbogbo àwọn eniyan mímọ́ rẹ̀. Tó bá di ìgbà náà, kò ní sí òtútù tabi òjò dídì mọ́, kò ní sí òkùnkùn, kò ní sí ọ̀sán, kò ní sí òru bíkòṣe ìmọ́lẹ̀ nígbà gbogbo. Ṣugbọn OLUWA nìkan ló mọ ìgbà tí nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀. Tó bá di ìgbà náà, àwọn odò tí wọ́n kún fún omi ìyè yóo máa ṣàn jáde láti Jerusalẹmu. Apá kan wọn yóo máa ṣàn lọ sinu òkun tí ó wà ní ìwọ̀ oòrùn, apá keji yóo máa ṣàn lọ sí òkun tí ó wà ní ìlà oòrùn, yóo sì máa rí bẹ́ẹ̀ tòjò-tẹ̀ẹ̀rùn. OLUWA yóo wá jọba ní gbogbo ayé; Ọlọrun nìkan ni gbogbo aráyé yóo máa sìn nígbà náà, orúkọ kanṣoṣo ni wọn yóo sì mọ̀ ọ́n. A óo sọ gbogbo ilẹ̀ náà di pẹ̀tẹ́lẹ̀, láti Geba ní ìhà àríwá, títí dé Rimoni ní ìhà gúsù. Ṣugbọn Jerusalẹmu yóo yọ kedere láàrin àwọn ilẹ̀ tí ó yí i ká, láti ẹnubodè Bẹnjamini, lọ dé ẹnubodè àtijọ́ ati dé ẹnubodè Igun, láti ilé-ìṣọ́ Hananeli dé ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí fún ọba. Àwọn eniyan yóo máa gbé inú ìlú Jerusalẹmu, kò ní sí ègún mọ́, ìlú Jerusalẹmu yóo sì wà ní alaafia. Àjàkálẹ̀ àrùn tí OLUWA yóo fi bá àwọn tí wọ́n bá gbógun ti ilẹ̀ Jerusalẹmu jà nìyí: Ẹran ara wọn yóo rà nígbà tí wọ́n ṣì wà láàyè, ojú wọn yóo rà ninu ihò rẹ̀, ahọ́n wọn yóo sì rà lẹ́nu wọn. Tó bá di ìgbà náà, OLUWA yóo mú ìbẹ̀rùbojo bá wọn tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo fi máa pa ara wọn; Àwọn ará Juda pàápàá yóo máa bá àwọn ará Jerusalẹmu jà. A óo kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i ká jọ: ati fadaka, ati wúrà, ati ọpọlọpọ aṣọ. Àjàkálẹ̀ àrùn burúkú náà yóo kọlu àwọn ẹṣin, ìbakasíẹ, ràkúnmí, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati gbogbo àwọn ẹran tí wọ́n bá wà ní ibùdó ogun wọn. Àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù láti àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo tí ó gbógun ti ilẹ̀ Jerusalẹmu yóo máa wá lọdọọdun láti sin Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ní ìlú Jerusalẹmu ati láti ṣe Àjọ̀dún Àgọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá kọ̀ tí kò lọ sí ìlú Jerusalẹmu lọ sin Ọba, OLUWA àwọn ọmọ ogun, òjò kò ní rọ̀ sí ilẹ̀ rẹ̀. Bí ó bá ṣe pé àwọn ará Ijipti ni wọ́n kọ̀ tí wọn kò wá síbi Àjọ̀dún Àgọ́ náà, irú àrùn tí OLUWA fi bá àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò wá sí ibi Àjọ Àgọ́ jà, ni yóo dà lé wọn lórí. Èyí ni ìyà tí yóo jẹ ilẹ̀ Ijipti ati gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò bá wá síbi Àjọ Àgọ́. Tó bá di ìgbà náà, a óo máa kọ “MÍMỌ́ SÍ OLUWA,” sí ara aago tí wọn ń so mọ́ ẹṣin lára. Ìkòkò inú ilé OLUWA, yóo sì máa dàbí àwọn àwo tí ó wà níwájú pẹpẹ. Gbogbo ìkòkò tí ó wà ní Jerusalẹmu ati ní Juda yóo di mímọ́ fún OLUWA àwọn ọmọ ogun. Àwọn tí wọ́n wá ṣe ìrúbọ yóo máa se ẹran ẹbọ wọn ninu ìkòkò wọnyi. Kò ní sí oníṣòwò ní ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun mọ́ tó bá di ìgbà náà.
Sek 14:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kíyèsi i, ọjọ́ OLúWA ń bọ̀, a ó sì pín ìkógun rẹ̀ láàrín rẹ̀. Nítorí èmi ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí Jerusalẹmu fún ogun; a ó sì ko ìlú naà, a ó sì kó àwọn ilé, a ó sì ba àwọn obìnrin jẹ́, ààbọ̀ ìlú náà yóò lọ sí ìgbèkùn, a kì yóò sì gé ìyókù àwọn ènìyàn náà kúrò ni ìlú náà. Nígbà náà ni OLúWA yóò jáde lọ, yóò sì bá àwọn orílẹ̀-èdè náà jà, gẹ́gẹ́ bí í ti ìjà ní ọjọ́ ogun. Ẹsẹ̀ rẹ̀ yóò sì dúró ni ọjọ́ náà lórí òkè Olifi, tí ó wà níwájú Jerusalẹmu ni ìlà-oòrùn, òkè Olifi yóò sì là á sí méjì, sí ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn, Àfonífojì ńláńlá yóò wà: ìdajì òkè náà yóò sì ṣí síhà àríwá, àti ìdajì rẹ̀ síhà gúúsù. Ẹ̀yin ó sì sá sí àfonífojì àwọn òkè mi: nítorí pé àfonífojì òkè náà yóò dé Aseli: nítòótọ́, ẹ̀yin ó sá bí ẹ tí sá fún ìmìmì-ilẹ̀ ni ọjọ́ Ussiah ọba Juda: OLúWA Ọlọ́run mi yóò sì wá, àti gbogbo àwọn Ẹni mímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìmọ́lẹ̀ kì yóò mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ṣókùnkùn. Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ ọjọ́ kan mímọ́ fún OLúWA, kì í ṣe ọ̀sán, kì í ṣe òru; ṣùgbọ́n yóò ṣe pé, ni àṣálẹ́ ìmọ́lẹ̀ yóò wà. Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, omi ìyè yóò tí Jerusalẹmu sàn lọ; ìdajì wọn síhà Òkun ìlà-oòrùn, àti ìdajì wọn síhà okùn ẹ̀yìn: nígbà ẹ̀rùn àti nígbà òtútù ni yóò rí bẹ́ẹ̀. OLúWA yóò sì jẹ ọba lórí gbogbo ayé; ni ọjọ́ náà ni OLúWA kan yóò wa orúkọ rẹ̀ nìkan náà ni orúkọ. A ó yí gbogbo ilẹ̀ padà bi pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan láti Geba dé Rimoni lápá gúúsù Jerusalẹmu: yóò di bí aginjù, ṣùgbọ́n a ó sì gbé Jerusalẹmu sókè, yóò sì gbe ipò rẹ̀, láti ibodè Benjamini títí dé ibi ibodè èkínní, dé ibodè igun nì, àti láti ilé ìṣọ́ Hananeli dé ibi ìfúntí wáìnì ọba. Ènìyàn yóò sì máa gbé ibẹ̀, kì yóò sì sí ìparun mọ́; ṣùgbọ́n a ó máa gbé Jerusalẹmu láìléwu. Èyí ni yóò sì jẹ́ ààrùn tí OLúWA yóò fi kọlu gbogbo àwọn ènìyàn ti ó tí ba Jerusalẹmu jà; ẹran-ara wọn yóò rù nígbà tí wọn dúró ni ẹsẹ̀ wọn, ojú wọn yóò sì rà ni ihò wọn, ahọ́n wọn yóò sì bàjẹ́ ni ẹnu wọn. Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láti ọ̀dọ̀ OLúWA wá yóò wà láàrín wọn; wọn ó sì di ọwọ́ ara wọn mú, ọwọ́ èkínní yóò sì dìde sì ọwọ́ èkejì rẹ̀. Juda pẹ̀lú yóò sì jà ni Jerusalẹmu: ọrọ̀ gbogbo àwọn kèfèrí tí ó wà káàkiri ni a ó sì kójọ, wúrà àti fàdákà, àti aṣọ, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ààrùn ẹṣin, ìbáaka, ìbákasẹ, àti tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, yóò sì wà, àti gbogbo ẹranko tí ń bẹ nínú àgọ́. Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ẹni tí o kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó dìde sí Jerusalẹmu yóò máa gòkè lọ lọ́dọọdún láti sìn ọba, OLúWA àwọn ọmọ-ogun, àti láti ṣe àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà. Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí kì yóò gòkè wá nínú gbogbo ìdílé ayé sí Jerusalẹmu láti sín ọba, OLúWA àwọn ọmọ-ogun, òjò kì yóò rọ̀ fún wọn. Bí ìdílé Ejibiti kò bá sì gòkè lọ, tí wọn kò sì wá, fi ara wọn hàn tí wọn kò ní òjò; ààrùn náà yóò wà, tí OLúWA yóò fi kọlù àwọn kèfèrí tí kò gòkè wá láti ṣe àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà Èyí ni yóò sì jẹ́ ìyà Ejibiti, àti ìyà gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò gòkè wá láti pa àsè àgọ́ mọ́. Ní ọjọ́ náà ni “mímọ́ sí OLúWA” yóò wà lára ṣaworo ẹṣin: àti àwọn ìkòkò ni ilé OLúWA yóò sì dàbí àwọn ọpọ́n tí ń bẹ níwájú pẹpẹ. Nítòótọ́, gbogbo ìkòkò ni Jerusalẹmu àti ni Juda yóò jẹ́ mímọ́ sí OLúWA àwọn ọmọ-ogun: àti gbogbo àwọn tí ń rú ẹbọ yóò wá, wọn ó sì mú ìkòkò díẹ̀, wọn ó sì bọ ẹran wọn nínú rẹ̀, ni ọjọ́ náà ni àwọn Kenaani kò ní sí mọ́ ni ilé OLúWA àwọn ọmọ-ogun.