Sek 13:8-9
Sek 13:8-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Yio si ṣe, ni gbogbo ilẹ, li Oluwa wi, a o ké apá meji ninu rẹ̀ kuro yio si kú; ṣugbọn apá kẹta yio kù ninu rẹ̀. Emi o si mu apá kẹta na là ãrin iná, emi o si yọ́ wọn bi a ti yọ́ fàdakà, emi o si dán wọn wò, bi a ti idán wura wò: nwọn o si pè orukọ mi, emi o si gbọ́ wọn: emi o wipe, Awọn enia mi ni: awọn o si wipe, Oluwa li Ọlọrun mi.
Sek 13:8-9 Yoruba Bible (YCE)
Jákèjádò ilẹ̀ náà, ìdá meji ninu mẹta àwọn eniyan náà ni wọn yóo kú, a óo sì dá ìdá kan yòókù sí. N óo da ìdá kan yòókù yìí sinu iná, n óo fọ̀ wọ́n mọ́, bí a tíí fi iná fọ fadaka. N óo sì dán wọn wò, bí a tíí dán wúrà wò. Wọn yóo pe orúkọ mi, n óo sì dá wọn lóhùn. N óo wí pé, ‘Eniyan mi ni wọ́n’; àwọn náà yóo sì jẹ́wọ́ pé, ‘OLUWA ni Ọlọrun wa.’ ”
Sek 13:8-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Yóò sì ṣe, ni gbogbo ilẹ̀,” ni OLúWA wí, “a ó gé apá méjì nínú rẹ̀ kúrò yóò sì kú; ṣùgbọ́n apá kẹta yóò kù nínú rẹ̀. Èmi ó sì mú apá kẹta náà la àárín iná, èmi yóò sì yọ́ wọn bí a ti yọ́ fàdákà, èmi yóò sì dán wọn wò, bi a tí ń dán wúrà wò: wọn yóò sì pé orúkọ mi, èmi yóò sì dá wọn lóhùn: èmi yóò wí pé, ‘Àwọn ènìyàn mi ni,’ àwọn yóò sì wí pé, ‘OLúWA ni Ọlọ́run wa.’ ”