Sek 13:1-9

Sek 13:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)

LI ọjọ na isun kan yio ṣi silẹ fun ile Dafidi ati fun awọn ara Jerusalemu, fun ẹ̀ṣẹ ati fun ìwa aimọ́. Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, li emi o ke orukọ awọn òriṣa kuro ni ilẹ na, a kì yio si ranti wọn mọ: ati pẹlu emi o mu awọn woli ati awọn ẹmi aimọ́ kọja kuro ni ilẹ na. Yio si ṣe, nigbati ẹnikan yio sọtẹlẹ sibẹ̀, ni baba rẹ̀ ati iya rẹ̀ ti o bi i yio wi fun u pe, Iwọ kì yio yè: nitori iwọ nsọ̀rọ eké li orukọ Oluwa: ati baba rẹ̀ ati iya rẹ̀ ti o bi i yio gún u li agúnyọ nigbati o ba sọ̀tẹlẹ. Yio si ṣe li ọjọ na, oju yio tì awọn woli olukulukù nitori iran rẹ̀, nigbati on ba ti sọtẹlẹ; bẹ̃ni nwọn kì yio si wọ̀ aṣọ onirun lati tan ni jẹ: Ṣugbọn on o wipe, Emi kì iṣe woli, agbẹ̀ li emi; nitori enia li o ni mi bi iranṣẹ lati igbà ewe mi wá. Ẹnikan o si wi fun u pe, Ọgbẹ́ kini wọnyi li ọwọ rẹ? On o si dahùn pe, Wọnyi ni a ti ṣá mi ni ile awọn ọrẹ́ mi. Dide, iwọ idà, si olùṣọ-agùtan mi, ati si ẹniti iṣe ẹnikeji mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; kọlù olùṣọ-agùtan, awọn àgutan a si tuká: emi o si yi ọwọ mi si awọn kékèké. Yio si ṣe, ni gbogbo ilẹ, li Oluwa wi, a o ké apá meji ninu rẹ̀ kuro yio si kú; ṣugbọn apá kẹta yio kù ninu rẹ̀. Emi o si mu apá kẹta na là ãrin iná, emi o si yọ́ wọn bi a ti yọ́ fàdakà, emi o si dán wọn wò, bi a ti idán wura wò: nwọn o si pè orukọ mi, emi o si gbọ́ wọn: emi o wipe, Awọn enia mi ni: awọn o si wipe, Oluwa li Ọlọrun mi.

Sek 13:1-9 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA ní, “Nígbà tó bá yá, orísun omi kan yóo ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi, ati fún àwọn ará Jerusalẹmu láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà èérí wọn. “N óo gbá àwọn oriṣa kúrò ní ilẹ̀ náà débi pé ẹnikẹ́ni kò ní ranti wọn mọ́; bákan náà ni n óo mú gbogbo àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní wolii kúrò, ati àwọn ẹ̀mí àìmọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá pe ara rẹ̀ ní wolii, baba ati ìyá rẹ̀ tí ó bí i yóo wí fún un pé yóo kú, nítorí ó ń purọ́ ní orúkọ OLUWA. Bí ó bá sọ àsọtẹ́lẹ̀, baba ati ìyá rẹ̀ yóo gún un pa. Nígbà tí àkókò bá tó, ojú yóo ti olukuluku wolii fún ìran tí ó rí nígbà tí ó bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, kò sì ní wọ aṣọ onírun mọ́ láti fi tan eniyan jẹ. Ṣugbọn yóo sọ pé, ‘Èmi kì í ṣe wolii, àgbẹ̀ ni mí; oko ni mò ń ro láti ìgbà èwe mi.’ Bí ẹnikẹ́ni bá bi í pé, ‘Àwọn ọgbẹ́ wo wá ni ti ẹ̀yìn rẹ?’ Yóo dáhùn pé, ‘Ọgbẹ́ tí mo gbà nílé àwọn ọ̀rẹ́ mi ni.’ ” OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ìwọ idà, kọjú ìjà sí olùṣọ́ àwọn aguntan mi, ati sí ẹni tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi. Kọlu olùṣọ́-aguntan, kí àwọn aguntan lè fọ́nká; n óo kọjú ìjà sí àwọn aguntan kéékèèké. Jákèjádò ilẹ̀ náà, ìdá meji ninu mẹta àwọn eniyan náà ni wọn yóo kú, a óo sì dá ìdá kan yòókù sí. N óo da ìdá kan yòókù yìí sinu iná, n óo fọ̀ wọ́n mọ́, bí a tíí fi iná fọ fadaka. N óo sì dán wọn wò, bí a tíí dán wúrà wò. Wọn yóo pe orúkọ mi, n óo sì dá wọn lóhùn. N óo wí pé, ‘Eniyan mi ni wọ́n’; àwọn náà yóo sì jẹ́wọ́ pé, ‘OLUWA ni Ọlọrun wa.’ ”

Sek 13:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ní ọjọ́ náà ìsun kan yóò ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi àti fún àwọn ará Jerusalẹmu, láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìmọ́ wọn. “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí, ni èmi ó gé orúkọ àwọn òrìṣà kúrò ni ilẹ̀ náà, a kì yóò sì rántí wọn mọ́: àti pẹ̀lú èmi ó mú àwọn wòlíì èké àti àwọn ẹ̀mí àìmọ́ kúrò ni ilẹ̀ náà. Yóò sì ṣe, nígbà tí ẹnìkan yóò sọtẹ́lẹ̀ síbẹ̀, ni baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí ó bí í yóò wí fún un pé, ‘Ìwọ ki yóò yè: nítorí ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ èké ni orúkọ OLúWA.’ Àti baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí o bí í yóò gun un ni àgúnpa nígbà tí ó bá sọtẹ́lẹ̀. “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ojú yóò tí àwọn wòlíì èké olúkúlùkù nítorí ìran rẹ̀, nígbà tí òun ba tí sọtẹ́lẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì wọ aṣọ wòlíì onírun rẹ̀ tí o fi ń tan ní jẹ. Ṣùgbọ́n òun o wí pé, ‘Èmi kí í ṣe wòlíì, àgbẹ̀ ni èmi; nítorí tí a ti fi mí ṣe ìránṣẹ́ láti ìgbà èwe mi wá.’ Ẹnìkan ó sì wí fún un pé, ‘Ọgbẹ́ kín ní wọ̀nyí ni ẹ̀yìn rẹ?’ Òun o sì dáhùn pé, ‘Wọ̀nyí ni ibi tí a ti sá mi ní ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi.’ “Dìde, ìwọ idà, sí olùṣọ́-àgùntàn mi, àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn, àwọn àgùntàn a sì túká: èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kéékèèkéé. Yóò sì ṣe, ni gbogbo ilẹ̀,” ni OLúWA wí, “a ó gé apá méjì nínú rẹ̀ kúrò yóò sì kú; ṣùgbọ́n apá kẹta yóò kù nínú rẹ̀. Èmi ó sì mú apá kẹta náà la àárín iná, èmi yóò sì yọ́ wọn bí a ti yọ́ fàdákà, èmi yóò sì dán wọn wò, bi a tí ń dán wúrà wò: wọn yóò sì pé orúkọ mi, èmi yóò sì dá wọn lóhùn: èmi yóò wí pé, ‘Àwọn ènìyàn mi ni,’ àwọn yóò sì wí pé, ‘OLúWA ni Ọlọ́run wa.’ ”