Sek 12:1-10
Sek 12:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ-ÌMỌ ọ̀rọ Oluwa fun Israeli, li Oluwa wi, ẹni ti o nnà awọn ọrun, ti o si fi ipilẹ aiye sọlẹ, ti o si mọ ẹmi enia ti mbẹ ni inu rẹ̀. Kiye si i, emi o sọ Jerusalemu di ago iwarìri si gbogbo enia yika, nigbati nwọn o do tì Juda ati Jerusalemu. Li ọjọ na li emi o sọ Jerusalemu di ẹrù okuta fun gbogbo enia: gbogbo awọn ti o ba si fi dẹrù pa ara wọn li a o ke si wẹwẹ, bi gbogbo awọn orilẹ-ède aiye tilẹ ko ara wọn jọ si i. Li ọjọ na, ni Oluwa wi, li emi o fi itagìri lù gbogbo ẹṣin, ati fi wère lu ẹniti ngùn u; emi o si ṣi oju mi si ile Juda, emi o si bu ifọju lù gbogbo ẹṣin ti enia na. Ati awọn bãlẹ Juda yio si wi li ọkàn wọn pe, Awọn ara Jerusalemu li agbara mi nipa Oluwa Ọlọrun wọn. Li ọjọ na li emi o ṣe awọn bãlẹ Juda bi ãrò iná kan lãrin igi, ati bi ètùfù iná lãrin ití; nwọn o si jẹ gbogbo awọn enia run yika lapa ọ̀tun ati lapa osi: a o si tun ma gbe Jerusalemu ni ipo rẹ̀, ani Jerusalemu. Oluwa pẹlu yio kọ́ tète gba agọ Juda là na, ki ogo ile Dafidi ati ogo awọn ara Jerusalemu ma bà gbe ara wọn ga si Juda. Li ọjọ na li Oluwa yio dãbò bò awọn ti ngbe Jerusalemu; ẹniti o ba si ṣe ailera ninu wọn li ọjọ na yio dabi Dafidi; ile Dafidi yio si dabi Ọlọrun, bi angeli Oluwa niwaju wọn. Yio si ṣe li ọjọ na, emi o wá lati pa gbogbo awọn orilẹ-ède run ti o wá kọjuja si Jerusalemu. Emi o si tú ẹmi ore-ọfẹ ati ẹbẹ sori ile Dafidi ati sori Jerusalemu: nwọn o si ma wò mi ẹniti nwọn ti gún li ọ̀kọ, nwọn o si ma ṣọ̀fọ rẹ̀, gẹgẹ bi enia ti nṣọ̀fọ fun ọmọ ọkunrin rẹ̀ kanṣoṣo, nwọn o si wà ni ibanujẹ, bi ẹniti mbanujẹ fun akọbi rẹ̀.
Sek 12:1-10 Yoruba Bible (YCE)
Iṣẹ́ tí OLUWA rán sí Israẹli nìyí, OLUWA tí ó ta ọ̀run bí aṣọ, tí ó dá ayé, tí ó sì dá ẹ̀mí sinu eniyan, ni ó sọ báyìí pé, “N óo ṣe ìlú Jerusalẹmu bí ife ọtí àmutagbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Wọn óo dojú kọ ilẹ̀ Juda, wọn óo sì dóti ìlú Jerusalẹmu. Ṣugbọn ní ọjọ́ náà, n óo mú kí ilẹ̀ Jerusalẹmu le kankan bí òkúta tí ó wúwo, orílẹ̀-èdè tí ó bá dábàá pé òun óo ṣí i nídìí, yóo farapa yánnayànna. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo sì parapọ̀ láti bá a jà. Ní ọjọ́ náà, n óo dẹ́rùba àwọn ẹṣin, n óo sì fi wèrè kọlu àwọn tí wọn ń gùn wọ́n. Ṣugbọn n óo máa ṣọ́ àwọn ará Juda, n óo sì fọ́ ojú ẹṣin àwọn ọ̀tá wọn. Àwọn ará Juda yóo wá máa sọ láàrin ara wọn pé, ‘OLUWA, àwọn ọmọ ogun ti sọ àwọn ará Jerusalẹmu di alágbára.’ “Ní ọjọ́ náà, n óo jẹ́ kí àwọn ará Juda dàbí ìkòkò iná tí ń jó ninu igbó, àní, bí iná tí ń jó láàrin oko ọkà, wọn yóo jó gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri, ṣugbọn Jerusalẹmu yóo wà láàyè rẹ̀ pẹlu gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. “OLUWA yóo kọ́kọ́ fún àwọn ogun Juda ní ìṣẹ́gun, kí ògo ilé Dafidi ati ògo àwọn ará Jerusalẹmu má baà ju ti Juda lọ. Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo dáàbò bo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, ẹni tí ó ṣe aláìlera jùlọ ninu wọn yóo lágbára bíi Dafidi. Ìdílé Dafidi yóo dàbí Ọlọrun, yóo máa darí wọn bí angẹli OLUWA. Ní ọjọ́ náà, n óo run àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. “N óo fi ẹ̀mí àánú ati adura sí ọkàn àwọn ọmọ Dafidi ati àwọn ará Jerusalẹmu, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo jẹ́ pé, bí wọ́n bá wo ẹni tí wọ́n gún lọ́kọ̀, wọn yóo máa ṣọ̀fọ̀ bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo. Wọn yóo sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn bí ẹni tí àkọ́bí rẹ̀ ṣàìsí.
Sek 12:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀: Ọ̀rọ̀ OLúWA fún Israẹli ni. OLúWA wí, ẹni tí ó na àwọn ọ̀run, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ó sì da ẹ̀mí ènìyàn tí ń bẹ ni inú rẹ̀: “Kíyèsi í, èmi yóò sọ Jerusalẹmu dí àgọ́ ìwárìrì sí gbogbo ènìyàn yíká, nígbà tí wọn yóò dó ti Juda àti Jerusalẹmu. Ní ọjọ́ náà, nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé bá parapọ̀ sí i, ni èmi yóò sọ Jerusalẹmu di òkúta ti ko ṣe yí kúrò fún gbogbo ènìyàn: gbogbo àwọn tí ó bá sì fẹ́ yí i ni a ó gé sí wẹ́wẹ́, ní ọjọ́ náà,” ni OLúWA wí, “Ni èmi yóò fi ìdágìrì lu gbogbo ẹṣin, àti fi òmùgọ̀ kọlu ẹni tí ń gun un; èmi yóò sì ṣí ojú mi sí ilé Juda, èmi yóò sì bu ìfọ́jú lu gbogbo ẹṣin tí orílẹ̀-èdè. Àti àwọn baálẹ̀ Juda yóò sì wí ni ọkàn wọn pé, ‘Àwọn ara Jerusalẹmu ni agbára mi nípa OLúWA àwọn ọmọ-ogun ni Ọlọ́run wọn.’ “Ní ọjọ́ náà, ni èmi yóò ṣe àwọn baálẹ̀ Juda bí ààrò iná kan láàrín igi, àti bi ẹ̀fúùfù iná láàrín ìtí; wọn yóò sì jẹ gbogbo àwọn ènìyàn run yíká lápá ọ̀tún àti lápá òsì: a ó sì tún máa gbé inú Jerusalẹmu ní ipò rẹ̀. “OLúWA pẹ̀lú yóò kọ́ tètè gba àgọ́ Juda là ná, kí ògo ilé Dafidi àti ògo àwọn ara Jerusalẹmu má ba gbé ara wọn ga sí Juda. Ní ọjọ́ náà ni OLúWA yóò dáàbò bò àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu; ẹni tí ó bá sì ṣe àìlera nínú wọn ní ọjọ́ náà, yóò dàbí Dafidi; ilé Dafidi yóò sì dàbí Ọlọ́run, bí angẹli OLúWA níwájú wọn. Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, èmi yóò wá láti pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè run tí ó wá kọjú ìjà sí Jerusalẹmu.” “Èmi ó sì tu ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bẹ̀ sórí ilé Dafidi àti sórí Jerusalẹmu: wọn ó sì máa wo ẹni tí wọn tí gún ni ọ̀kọ̀, wọn ó sì máa ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, bí ẹnìkan ti ń ṣọ̀fọ̀ fún ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo àti gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí wọn yóò sì wà ni ìbànújẹ́, bí ẹni tí ń banújẹ́ fún àkọ́bí rẹ̀.