Sek 11:4-17
Sek 11:4-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bayi li Oluwa Ọlọrun mi wi; Bọ́ ọwọ́-ẹran abọ́pa. Ti awọn oluwa wọn npa wọn, ti nwọn kò si kà ara wọn si pe nwọn jẹbi: ati awọn ti ntà wọn wipe, Ibukún ni fun Oluwa, nitoriti mo di ọlọrọ̀: awọn oluṣọ agutan wọn kò si ṣãnu wọn. Nitori emi kì yio ṣãnu fun awọn ara ilẹ na mọ, li Oluwa wi; si kiye si i, emi o fi olukuluku enia le aladugbo rẹ̀ lọwọ, ati le ọwọ ọba rẹ̀: nwọn o si fọ́ ilẹ na, emi kì yio si gbà wọn lọwọ wọn. Emi o si bọ́ ẹran abọ́pa, ani ẹnyin otoṣi ninu ọwọ́ ẹran. Mo si mu ọpa meji sọdọ; mo pe ọkan ni Ẹwà, mo si pe ekeji ni Amure; mo si bọ́ ọwọ́-ẹran na. Oluṣọ agutan mẹta ni mo si ke kuro li oṣu kan; ọkàn mi si korira wọn, ọkàn wọn pẹlu si korira mi. Mo si wipe, emi kì yio bọ nyin: eyi ti nkú lọ, jẹ ki o kú; eyi ti a o ba si ke kuro, jẹ ki a ke e kuro; ki olukuluku ninu awọn iyokù jẹ ẹran-ara ẹnikeji rẹ̀. Mo si mu ọpa mi, ani Ẹwà, mo si ṣẹ ẹ si meji, ki emi ba le dà majẹmu mi ti mo ti ba gbogbo awọn enia ni da. O si dá li ọjọ na; bẹ̃ni awọn otoṣi ninu ọwọ́-ẹran nì ti o duro tì mi mọ̀ pe, ọ̀rọ Oluwa ni. Mo si wi fun wọn pe, Bi o ba dara li oju nyin, ẹ fun mi ni owo-ọ̀ya mi: bi bẹ̃kọ, ẹ jọwọ rẹ̀. Bẹ̃ni nwọn wọ̀n ọgbọ̀n owo fadakà fun iye mi. Oluwa si wi fun mi pe, Sọ ọ si amọkòko: iye daradara na ti nwọn yọwó mi si. Mo si mu ọgbọ̀n owo fadakà na, mo si sọ wọn si amọkòko ni ile Oluwa. Mo si ṣẹ ọpa mi keji, ani Amure, si meji, ki emi ki o le yà ibatan ti o wà lãrin Juda ati lãrin Israeli. Oluwa si wi fun mi pe, Tún mu ohun-elò oluṣọ agutan aṣiwere kan sọdọ rẹ. Nitori kiye si i, Emi o gbe oluṣọ-agutan kan dide ni ilẹ na, ti kì yio bẹ̀ awọn ti o ṣegbé wò, ti kì yio si wá eyi ti o yapa: ti kì yio ṣe awotan eyi ti o ṣẹ́, tabi kì o bọ́ awọn ti o duro jẹ: ṣugbọn on o jẹ ẹran eyi ti o li ọ̀ra, yio si fà ẽkanna wọn ya pẹrẹpẹ̀rẹ. Egbe ni fun oluṣọ agutan asan na ti o fi ọwọ́-ẹran silẹ! idà yio wà li apá rẹ̀, ati li oju ọ̀tun rẹ̀: apá rẹ̀ yio gbẹ patapata, oju ọ̀tun rẹ̀ yio si ṣõkùnkun biribiri.
Sek 11:4-17 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ọlọrun mi sọ; ó ní, “Fi ara rẹ sí ipò olùṣọ́-aguntan tí ó da àwọn ẹran rẹ̀ lọ sí ibi tí wọ́n ti pa wọ́n. Àwọn tí wọ́n rà wọ́n pa wọ́n ní àpagbé; àwọn tí wọn n tà wọ́n sì wí pé, ‘Ìyìn ni fún OLUWA, mo ti di ọlọ́rọ̀’; àwọn tí wọ́n ni wọ́n kò tilẹ̀ ṣàánú wọn.” OLUWA ní, “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni n kò ní ṣàánú àwọn eniyan ilẹ̀ yìí mọ́. Fúnra mi ni n óo fi wọ́n lé àwọn aláṣẹ ati àwọn ọba wọn lọ́wọ́. Wọn óo run ilẹ̀ náà, n kò sì ní gba ẹnikẹ́ni lọ́wọ́ wọn.” Mo ti di darandaran agbo ẹran tí à ń dà lọ fún àwọn alápatà. Mo mú ọ̀pá meji, mo sọ ọ̀kan ní “Oore-ọ̀fẹ́,” mo sì sọ ekeji ní “Ìṣọ̀kan.” Inú mi ru sí mẹta ninu àwọn darandaran tí wọ́n kórìíra mi, mo sì mú wọn kúrò láàrin oṣù kan. Mo wá sọ fún àwọn agbo ẹran náà pé, “N kò ní ṣe olùṣọ́ yín mọ́. Èyí tí yóo bá kú ninu yín kí ó kú, èyí tí yóo bá ṣègbé, kí ó ṣègbé, kí àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù sì máa pa ara wọn jẹ.” Mo bá mú ọ̀pá mi tí ń jẹ́ “Oore-ọ̀fẹ́,” mo dá a, mo fi fi òpin sí majẹmu tí mo bá àwọn orílẹ̀-èdè dá. Nítorí náà, majẹmu mi ti dópin lọ́jọ́ náà. Àwọn tí wọn ń ṣòwò aguntan, tí wọn ń wò mí, mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo ṣe ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. Nígbà náà ni mo wí fún wọn pé, “Bí ó bá tọ́ lójú yín, ẹ fún mi ní owó iṣẹ́ mi, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ máa mú un lọ.” Wọ́n bá wọn ọgbọ̀n owó fadaka fún mi gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ mi. Nígbà náà ni OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ pa owó náà mọ́ sílé ìṣúra.” Nítorí náà, mo da ọgbọ̀n owó fadaka tí wọ́n san fún mi, sinu ilé ìṣúra ní ilé OLUWA. Nígbà náà ni mo dá ọ̀pá mi keji tí ń jẹ́ “Ìṣọ̀kan,” mo fi fi òpin sí àjọṣe tí ó wà láàrin Juda ati Israẹli. OLUWA tún sọ fún mi pé “Tún fi ara rẹ sí ipò darandaran tí kò wúlò fún nǹkankan. Wò ó! N óo gbé darandaran kan dìde tí kò ní bìkítà fún àwọn ẹran tí wọ́n ń ṣègbé, kò ní tọpa àwọn tí wọn ń ṣáko lọ, tabi kí ó wo àwọn tí ń ṣàìsàn sàn, tabi kí ó fún àwọn tí ara wọn le ní oúnjẹ. Dípò kí ó tọ́jú wọn, pípa ni yóo máa pa àwọn tí ó sanra jẹ, tí yóo sì máa fa pátákò wọn ya. Olùṣọ́-aguntan mi tí kò bá níláárí gbé! Tí ó ń fi agbo ẹran sílẹ̀. Idà ni yóo ṣá a ní apá, yóo sì bá a ní ojú ọ̀tún, apá rẹ̀ óo rọ patapata, ojú ọ̀tún rẹ̀ óo sì fọ́ patapata.”
Sek 11:4-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báyìí ni OLúWA Ọlọ́run mi wí: “Bọ́ ọ̀wọ́ ẹran àbọ́pa. Tí àwọn olúwa wọn ń pa wọ́n, tí wọn kò sì ka ara wọn sí pé wọn jẹ̀bi: àti àwọn tí ń tà wọ́n wí pé, ‘Ìbùkún ni fún OLúWA, nítorí tí mo dí ọlọ́rọ̀!’ Àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn kò sì ṣàánú wọn. Nítorí èmi kì yóò ṣàánú fún àwọn ara ilẹ̀ náà mọ́,” ni OLúWA wí, “Ṣí kíyèsi í, èmi yóò fi olúkúlùkù ènìyàn lé aládùúgbò rẹ̀ lọ́wọ́, àti lé ọwọ́ ọba rẹ̀, wọn yóò sì fọ́ ilẹ̀ náà, èmi kì yóò sì gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn.” Èmi yóò sì bọ́ ẹran àbọ́pa, àní ẹ̀yin òtòṣì nínú ọ̀wọ́ ẹran. Mo sì mu ọ̀pá méjì sọ́dọ̀; mo pè ọ̀kan ni Oore-ọ̀fẹ́, mo pè èkejì ni Àmùrè; mo sì bọ́ ọ̀wọ́ ẹran náà. Olùṣọ́-àgùntàn mẹ́ta ni mo sì gé kúrò ní oṣù kan. Ọkàn mi sì kórìíra wọn, ọkàn wọn pẹ̀lú sì kórìíra mi. Mo sì wí pé, “Èmi kì yóò bọ́ yin: èyí ti ń ku lọ, jẹ́ kí òkú o kú; èyí tí a o ba sì gé kúrò, jẹ́ kí a gé e kúrò; ki olúkúlùkù nínú àwọn ìyókù jẹ́ ẹran-ara ẹnìkejì rẹ̀.” Mo sì mu ọ̀pá mi, ti a ń pè ní Oore-ọ̀fẹ́, mo ṣẹ́ si méjì, ki èmi bá lè da májẹ̀mú mi tí mo tí bá gbogbo àwọn ènìyàn náà dá. Ó sì dá ni ọjọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn òtòṣì nínú ọ̀wọ́ ẹran náà tí ó dúró tì mí mọ̀ pé, ọ̀rọ̀ OLúWA ni. Mo sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá dára ní ojú yin, ẹ fún mi ni owó ọ̀yà mi; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ mú un lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọn ọgbọ̀n owó fàdákà fún iye owó ọ̀yà mi. OLúWA sì wí fún mi pé, “Sọ ọ sí amọ̀kòkò.” Iye dáradára náà, tí wọn yọ owó mi sí. Mo sì mu ọgbọ̀n owó fàdákà náà, mo sì sọ wọ́n sí àpótí ìṣúra ní ilé OLúWA. Mo sì ṣẹ́ ọ̀pá mi kejì, àní Àmùrè, sí méjì, kí èmi lè ya ìbátan tí ó wà láàrín Juda àti láàrín Israẹli. OLúWA sì wí fún mi pé, “Tún mú ohun èlò aṣiwèrè olùṣọ́-àgùntàn kan sọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí Èmi o gbé olùṣọ́-àgùntàn kan dìde ni ilẹ̀ náà, tí kí yóò bẹ àwọn tí ó ṣègbé wò, ti kì yóò sì wá èyí tí ó yapa; tí kì yóò ṣe ìtọ́jú èyí tí a pa lára tàbí kí ó bọ́ àwọn tí ara wọn dá pépé: Ṣùgbọ́n òun yóò jẹ ẹran èyí tí ó ni ọ̀rá, àwọn èyí tiwọn fi èékánná wọn ya ara wọn pẹ́rẹpẹ̀rẹ. “Ègbé ni fún olùṣọ́-àgùntàn asán náà, tí ó fi ọ̀wọ́ ẹran sílẹ̀! Idà yóò gé apá rẹ̀ àti ojú ọ̀tún rẹ̀: apá rẹ̀ yóò gbẹ pátápátá, ojú ọ̀tún rẹ̀ yóò sì fọ́ pátápátá!”