Sek 11:1-3
Sek 11:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
ṢI ilẹkun rẹ wọnni silẹ, Iwọ Lebanoni, ki iná ba le jẹ igi kedari rẹ run. Hu, igi firi; nitori igi kedari ṣubu; nitori ti a ba awọn alagbara jẹ: hu, ẹnyin igi oaku ti Baṣani, nitori a ke igbo ajara lulẹ. Ohùn igbe awọn oluṣọ agutan; nitori ogo wọn bajẹ: ohùn bibu awọn ọmọ kiniun; nitori ogo Jordani bajẹ.
Sek 11:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ṣílẹ̀kùn rẹ, ìwọ ilẹ̀ Lẹbanoni kí iná lè jó àwọn igi kedari rẹ! Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin igi Sipirẹsi, nítorí igi kedari ti ṣubú, àwọn igi ológo ti parun. Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin igi oaku ní Baṣani, nítorí pé, a ti gé àwọn igi igbó dídí Baṣani lulẹ̀! Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ gbọ́ ẹkún àwọn darandaran, nítorí ògo wọn ti díbàjẹ́. Ẹ gbọ́ bí àwọn kinniun ti ń bú ramúramù, nítorí igbó tí wọn ń gbé lẹ́bàá odò Jọdani ti parun!
Sek 11:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ sílẹ̀, ìwọ Lebanoni, kí iná bá lè jẹ igi kedari rẹ run, Hu, igi junifa; nítorí igi kedari ṣubú, nítorí tí a ba àwọn igi tí o lógo jẹ́: hu, ẹ̀yin igi óákù tí Baṣani, nítorí gé igbó àjàrà lulẹ̀. Gbọ́ ohun igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn; ògo wọn bàjẹ́; gbọ́ ohùn bíbú àwọn ọmọ kìnnìún nítorí ògo Jordani bàjẹ́.