Sek 1:1-21

Sek 1:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

LI oṣù kẹjọ, li ọdun keji Dariusi, li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Sekariah wá, ọmọ Berekiah ọmọ Iddo woli, pe, Oluwa ti binu pupọ̀ si awọn baba nyin. Nitorina iwọ wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Ẹ yipadà si mi, emi o si yipadà si nyin, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Ẹ má dàbi awọn baba nyin, awọn ti awọn woli iṣãju ti ké si wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Ẹ yipadà nisisiyi kuro li ọ̀na buburu nyin, ati kuro ninu ìwa-buburu nyin: ṣugbọn nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò fetisi ti emi, ni Oluwa wi. Awọn baba nyin, nibo ni nwọn wà? ati awọn woli, nwọn ha wà titi aiye? Ṣugbọn ọ̀rọ mi ati ilàna mi, ti mo pa li aṣẹ fun awọn iranṣẹ mi woli, nwọn kò ha fi mu awọn baba nyin? nwọn si padà nwọn wipe, Gẹgẹ bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti rò lati ṣe si wa, gẹgẹ bi ọ̀na wa, ati gẹgẹ bi iṣe wa, bẹ̃ni o ti ṣe si wa. Li ọjọ kẹrinlelogun oṣù kọkanla, ti iṣe oṣù Sebati, li ọdun keji Dariusi, li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Sekariah, ọmọ Berekiah ọmọ Iddo woli wá, pe, Mo ri li oru, si wò o, ọkunrin kan ngun ẹṣin pupa kan, on si duro lãrin awọn igi mirtili ti o wà ni ibi õji; lẹhìn rẹ̀ si li ẹṣin pupa, adíkalà, ati funfun gbe wà. Nigbana ni mo wipe, Kini wọnyi oluwa mi? Angeli ti mba mi sọ̀rọ si wi fun mi pe, emi o fi ohun ti wọnyi jẹ hàn ọ. Ọkunrin ti o duro lãrin awọn igi mirtili si dahùn o si wipe, Wọnyi li awọn ti Oluwa ti rán lati ma rìn sokè sodò li aiye. Nwọn si da angeli Oluwa ti o duro lãrin awọn igi mirtili na lohùn pe, Awa ti rìn sokè sodò já aiye, si kiyesi i, gbogbo aiye wà ni isimi, o si duro jẹ. Nigbana ni angeli Oluwa na dahùn o si wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, yio ti pẹ to ti iwọ kì yio fi ṣãnu fun Jerusalemu, ati fun awọn ilu-nla Juda, ti iwọ ti binu si li ãdọrin ọdun wọnyi? Oluwa si fi ọ̀rọ rere ati ọ̀rọ itùnu da angeli ti mba mi sọ̀rọ lohùn. Angeli ti mba mi sọ̀rọ si wi fun mi pe, Iwọ kigbe wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi nfi ijowu nla jowu fun Jerusalemu ati fun Sioni. Emi si binu pupọ̀pupọ̀ si awọn orilẹ-ède ti o gbe jẹ: nitoripe emi ti binu diẹ, nwọn si ti kún buburu na lọwọ. Nitorina bayi li Oluwa wi; mo padà tọ̀ Jerusalemu wá pẹlu ãnu; Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, a o kọ ile mi sinu rẹ̀, a o si ta okùn kan jade sori Jerusalemu. Ma ke sibẹ̀ pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; A o ma fi ire kún ilu-nla mi sibẹ̀; Oluwa yio si ma tù Sioni ninu sibẹ̀, yio si yàn Jerusalemu sibẹ̀. Mo si gbe oju mi soke, mo si ri, si kiyesi i, iwo mẹrin. Mo si sọ fun angeli ti o ba mi sọ̀rọ pe, Kini wọnyi? O si da mi lohùn pe, Awọn wọnyi ni iwo ti o ti tú Juda, Israeli, ati Jerusalemu ka. Oluwa si fi gbẹnàgbẹnà mẹrin kan hàn mi. Nigbana ni mo wipe, kini awọn wọnyi wá ṣe? O si sọ wipe, Awọn wọnyi ni iwo ti o ti tú Juda ka, tobẹ̃ ti ẹnikẹni kò fi gbe ori rẹ̀ soke? ṣugbọn awọn wọnyi wá lati dẹruba wọn, lati le iwo awọn orilẹ-ède jade, ti nwọn gbe iwo wọn sori ilẹ Juda lati tu u ka.

Sek 1:1-21 Yoruba Bible (YCE)

Ní oṣù kẹjọ, ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA rán wolii Sakaraya, ọmọ Berekaya, ọmọ Ido, sí àwọn ọmọ Israẹli; ó ní, “Èmi OLUWA bínú sí àwọn baba ńlá yín. Nítorí náà, èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ní kí ẹ pada wá sọ́dọ̀ mi, èmi náà yóo sì pada sọ́dọ̀ yín. Ẹ má ṣe bí àwọn baba ńlá yín, tí àwọn wolii mi rọ̀ títí pé kí wọ́n jáwọ́ ninu ìgbé-ayé burúkú, kí wọ́n jáwọ́ ninu iṣẹ́ ibi, ṣugbọn tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́. Níbo ni àwọn baba ńlá yín ati àwọn wolii wà nisinsinyii? Ǹjẹ́ wọ́n wà mọ́? Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi ati ìlànà mi tí àwọn wolii, iranṣẹ mi, sọ kò ṣẹ sí àwọn baba ńlá yín lára?” Àwọn eniyan náà bá ronupiwada, wọ́n ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun ti ṣe wá bí ó ti pinnu láti ṣe, nítorí ìwà burúkú ati iṣẹ́ ibi wa.” Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kọkanla tíí ṣe oṣù Ṣebati, ní ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA fi ìran kan han wolii Sakaraya ọmọ Berekaya, ọmọ Ido. Mo rí ìran kan lóru. Ninu ìran náà, mo rí ọkunrin kan lórí ẹṣin pupa, láàrin àwọn igi kan tí wọ́n ń pè ní mitili, láàrin àfonífojì kan. Àwọn ẹṣin pupa, ati ẹṣin rẹ́súrẹ́sú ati ẹṣin funfun dúró lẹ́yìn rẹ̀. Mo bá bèèrè pé, “OLUWA mi, kí ni ìtumọ̀ kinní wọnyi?” Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì dáhùn pé, “N óo sọ ìtumọ̀ wọn fún ọ.” Ọkunrin tí ó dúró láàrin àwọn igi mitili náà bá dáhùn pé, “Àwọn wọnyi ni àwọn tí OLUWA rán láti máa rin ilẹ̀ ayé wò.” Wọ́n sì jíṣẹ́ fún angẹli OLUWA, tí ó dúró láàrin àwọn igi mitili náà pé, “A ti lọ rin ilẹ̀ ayé wò jákèjádò, a sì rí i pé wọ́n wà ní alaafia ati ìdákẹ́rọ́rọ́.” Angẹli OLUWA bá dáhùn pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, yóo ti pẹ́ tó kí o tó yọ́nú sí Jerusalẹmu ati àwọn ìlú Juda, tí o tí ń bínú sí láti aadọrin ọdún sẹ́yìn?” OLUWA sì dá angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn pẹlu ọ̀rọ̀ ìtùnú. Angẹli náà bá sọ fún mi pé kí n lọ kéde pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Mo ní ìfẹ́ ati ìtara tí ó jinlẹ̀ pupọ fún Jerusalẹmu ati Sioni. Inú sì ń bí mi gidigidi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí wọ́n sì wà ní alaafia; nítorí pé, nígbà tí mo bínú díẹ̀ sí àwọn eniyan mi, wọ́n tún dá kún ìṣòro wọn ni. Nítorí náà, mo ti pada sí Jerusalẹmu láti ṣàánú fún un: a óo tún ilé mi kọ́ sibẹ, a óo sì tún ìlú Jerusalẹmu kọ́.” Angẹli náà tún sọ fún mi pé, “Lọ kéde pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, àwọn ìlú òun yóo tún kún fún ọrọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, òun OLUWA yóo tu Sioni ninu, òun óo sì tún yan Jerusalẹmu ní àyànfẹ́ òun.” Bí mo ti gbé ojú sókè ni mo rí ìwo mààlúù mẹrin, mo sì bèèrè ìtumọ̀ ohun tí mo rí lọ́wọ́ angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Ó bá dá mi lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọnyi dúró fún àwọn alágbára ayé tí wọ́n fọ́n Juda, Israẹli, ati Jerusalẹmu ká.” Lẹ́yìn náà, OLUWA fi àwọn alágbẹ̀dẹ mẹrin kan hàn mí. Mo bèèrè pé, “Kí ni àwọn wọnyi ń bọ̀ wá ṣe?” Ó bá dáhùn pé, “Àwọn ìwo wọnyi dúró fún àwọn tí wọ́n fọ́n Juda ká patapata, tóbẹ́ẹ̀ tí kò ku ẹnìkan mọ́. Ṣugbọn àwọn alágbẹ̀dẹ wọnyi wá láti dẹ́rùba àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n fọ́n Juda ká, ati láti fọ́n àwọn náà ká.”

Sek 1:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní oṣù kẹjọ ọdún kejì ọba Dariusi, ọ̀rọ̀ OLúWA tọ wòlíì Sekariah ọmọ Berekiah, ọmọ Iddo pé: “OLúWA ti bínú sí àwọn baba ńlá yín. Nítorí náà sọ fún àwọn ènìyàn: Èyí ni ohun tí OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Ẹ padà sí Ọ̀dọ̀ mi,’ Báyìí ní OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí, ‘èmi náà yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín,’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. Ẹ má dàbí àwọn baba yín, àwọn tí àwọn wòlíì ìṣáájú ti ké sí wí pé: Báyìí ní OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín,’ àti kúrò nínú ìwà búburú yín; ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sí ti èmi, ni OLúWA wí. Àwọn baba yín, níbo ni wọ́n wà? Àti àwọn wòlíì, wọ́n ha wà títí ayé? Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi àti ìlànà mi, ti mo pa ní àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì, kò ha tún bá àwọn baba yín? “Wọ́n sì padà wọ́n wí pé, ‘Gẹ́gẹ́ bí OLúWA àwọn ọmọ-ogun ti rò láti ṣe sí wa, gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà wa, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa, bẹ́ẹ̀ ní o ti ṣe sí wa.’ ” Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kọkànlá, tí ó jẹ́, oṣù Sebati, ní ọdún kejì Dariusi, ni ọ̀rọ̀ OLúWA tọ wòlíì Sekariah, ọmọ Bẹrẹkiah ọmọ Iddo wá, pé. Mo rí ìran kan ni òru, si wò ó, ọkùnrin kan ń gun ẹṣin pupa kan, òun sì dúró láàrín àwọn igi maritili tí ó wà ní ibi òòji; lẹ́yìn rẹ̀ sì ni ẹṣin pupa, adíkálà, àti funfun gbé wà. Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni wọ̀nyí olúwa mi?” Angẹli tí ń ba mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Èmi ó fi ohun tí àwọn wọ̀nyí jẹ́ hàn ọ́.” Ọkùnrin tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili sì dáhùn ó sì wí pé, “Wọ̀nyí ní àwọn tí OLúWA ti rán láti máa rìn sókè sódò ni ayé.” Wọ́n si dá angẹli OLúWA tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili náà lóhùn pé, “Àwa ti rìn sókè sódò já ayé, àwa sí ti rí i pé gbogbo ayé wà ní ìsinmi àti àlàáfíà.” Nígbà náà ni angẹli OLúWA náà dáhùn ó sì wí pé, “OLúWA àwọn ọmọ-ogun, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ kì yóò fi ṣàánú fún Jerusalẹmu, àti fún àwọn ìlú ńlá Juda, ti ìwọ ti bínú sí ni àádọ́rin ọdún wọ̀nyí?” OLúWA sì fi ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ ìtùnú dá angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn. Angẹli ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbe wí pé: Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jowú fún Jerusalẹmu àti fún Sioni. Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí ó rò wí pé òun ní ààbò. Nítorí nígbà tí mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú.’ “Nítorí náà, báyìí ni OLúWA wí: ‘Mo padà tọ Jerusalẹmu wá pẹ̀lú àánú; ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí, a ó kọ́ ilé mi sínú rẹ̀, a o sí ta okùn ìwọ̀n kan jáde sórí Jerusalẹmu.’ “Máa ké síbẹ̀ pé: Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: ‘A o máa fi ìre kún ìlú ńlá mi síbẹ̀; OLúWA yóò sì máa tu Sioni nínú síbẹ̀, yóò sì yan Jerusalẹmu síbẹ̀.’ ” Mo si gbé ojú sókè, mo sì rí, sì kíyèsi i, ìwo mẹ́rin. Mo sì sọ fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni nǹkan wọ̀nyí?” Ó si dà mí lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọ̀nyí ni ó tí tú Juda, Israẹli, àti Jerusalẹmu ká.” OLúWA sì fi alágbẹ̀dẹ mẹ́rin kan hàn mí. Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni àwọn wọ̀nyí wá ṣe?” O sì sọ wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìwo tí ó ti tú Juda ká, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò fi gbé orí rẹ̀ sókè? Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí wá láti dẹ́rùbà wọ́n, láti lé ìwo àwọn orílẹ̀-èdè jáde, ti wọ́n gbé ìwo wọn sórí ilẹ̀ Juda láti tú ènìyàn rẹ̀ ká.”