Tit 3:9-11
Tit 3:9-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn yà kuro ni ìbẽre wère, ati ìtan iran, ati ijiyan, ati ija nipa ti ofin; nitoripe alailere ati asan ni nwọn. Ẹniti o ba ṣe aladamọ̀ lẹhin ìkilọ ikini ati ekeji, kọ̀ ọ; Ki o mọ̀ pe irú ẹni bẹ̃ ti yapa, o si ṣẹ̀, o dá ara rẹ̀ lẹbi.
Tit 3:9-11 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn yẹra fún iyàn jíjà lórí ọ̀rọ̀ wèrè ati ìtàn ìrandíran, ati ìjà, ati àríyànjiyàn lórí ọ̀rọ̀ òfin. Nítorí wọn kò ṣe eniyan ní anfaani, wọn kò sì wúlò rárá. Bí o bá ti kìlọ̀ fún adíjàsílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tabi lẹẹmeji, tí kò gbọ́, yẹra fún un. Mọ̀ pé ọkàn irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti wọ́, ó ń dá ẹ̀ṣẹ̀, ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi.
Tit 3:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n yẹra kúrò nínú àwọn ìbéèrè òmùgọ̀, àti ìtàn ìran, àti àríyànjiyàn àti ìjà nípa ti òfin, nítorí pé àwọn nǹkan báyìí jẹ́ aláìlérè àti asán. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ dá ìyapa sílẹ̀ láàrín yín, ẹ bá a wí lẹ́ẹ̀kínní àti lẹ́ẹ̀kejì. Lẹ́yìn náà, ẹ má ṣe ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú rẹ̀. Kí ó dá ọ lójú wí pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti yapa, ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì dá ara rẹ̀ lẹ́bi.