Tit 3:5-8
Tit 3:5-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kì iṣe nipa iṣẹ ti awa ṣe ninu ododo ṣugbọn gẹgẹ bi ãnu rẹ̀ li o gbà wa là, nipa ìwẹnu atúnbi ati isọdi titun Ẹmí Mimọ́, Ti o dà si wa lori lọpọlọpọ nipasẹ Jesu Kristi Olugbala wa; Ki a le dá wa lare nipa ore-ọfẹ rẹ̀, ki a si le sọ wa di ajogún gẹgẹ bi ireti ìye ainipẹkun. Otitọ li ọ̀rọ na, emi si nfẹ ki iwọ ki o tẹnumọ nkan wọnyi gidigidi, ki awọn ti o gbà Ọlọrun gbọ́ le mã tọju ati ṣe iṣẹ rere. Nkan wọnyi dara, nwọn si ṣe anfani fun enia.
Tit 3:5-8 Yoruba Bible (YCE)
kì í ṣe nítorí iṣẹ́ rere kan tí a ṣe, ṣugbọn nítorí àánú rẹ̀ ni ó fi gbà wá là, nípa ìwẹ̀mọ́ pẹlu omi tí ó fi tún wa bí, ati Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fi sọ wá di ẹni titun. Ó da Ẹ̀mí yìí lé wa lórí lọpọlọpọ láti ọwọ́ Jesu Kristi Olùgbàlà wa. Ó dá wa láre nípa oore-ọ̀fẹ́ kan náà, tí a fi ní ìrètí láti di ajogún ìyè ainipẹkun. Ọ̀rọ̀ tí ó dájú ni ọ̀rọ̀ yìí. Mo fẹ́ kí o tẹnumọ́ àwọn nǹkan wọnyi, kí àwọn tí ó ti gba Ọlọrun gbọ́ lè fi ọkàn sí i láti máa ṣe iṣẹ́ tí ó dára. Irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ dára, wọ́n sì ń ṣe eniyan ní anfaani.
Tit 3:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
o gbà wá là. Kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí àwa ṣe nínú òdodo bí kò ṣe nítorí àánú rẹ̀. Ó gbà wá là, nípasẹ̀ ìwẹ̀nù àtúnbí àti ìsọdọ̀tun ti Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí tú lé wa lórí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nípasẹ̀ Jesu Kristi Olùgbàlà wá. Tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó jẹ́ wí pé lẹ́hìn tí a tí dá wa láre nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́, kí a lè jẹ́ àjùmọ̀jogún ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Mo sì fẹ́ kí ó ṣe ìtẹnumọ́ rẹ̀ gidigidi, kí àwọn tí wọ́n ti gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run le kíyèsi láti máa fi ara wọn jì fún iṣẹ́ rere. Nǹkan wọ̀nyí dára, wọ́n sì jẹ́ èrè fún gbogbo ènìyàn.