Tit 3:1-2
Tit 3:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Máa rán wọn létí kí wọn máa tẹríba fún ìjọba ati àwọn aláṣẹ, kí wọn máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, kí wọn sì múra láti máa ṣe iṣẹ́ rere gbogbo. Kí wọn má sọ ìsọkúsọ sí ẹnikẹ́ni. Kí wọn kórìíra ìjà. Kí wọn ní ìfaradà. Kí wọ́n máa fi ìrẹ̀lẹ̀ bá gbogbo eniyan lò.
Tit 3:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
MÃ rán wọn leti lati mã tẹriba fun awọn ijoye, ati fun awọn alaṣẹ, lati mã gbọ́ ti wọn, ati lati mã mura si iṣẹ rere gbogbo, Ki nwọn má sọrọ ẹnikẹni ni ibi, ki nwọn má jẹ onija, bikoṣe ẹni pẹlẹ, ki nwọn mã fi ìwa tutù gbogbo han si gbogbo enia.
Tit 3:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Máa rán wọn létí kí wọn máa tẹríba fún ìjọba ati àwọn aláṣẹ, kí wọn máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, kí wọn sì múra láti máa ṣe iṣẹ́ rere gbogbo. Kí wọn má sọ ìsọkúsọ sí ẹnikẹ́ni. Kí wọn kórìíra ìjà. Kí wọn ní ìfaradà. Kí wọ́n máa fi ìrẹ̀lẹ̀ bá gbogbo eniyan lò.
Tit 3:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Rán àwọn ènìyàn náà létí láti máa tẹríba fún ìjọba àti àwọn aláṣẹ. Kí wọn ṣe ìgbọ́ràn nígbà gbogbo, kí wọn sì múra fún iṣẹ́ rere gbogbo. Wọn kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ ẹnikẹ́ni ní ibi, kí wọn jẹ́ ẹni àlàáfíà àti ẹni pẹ̀lẹ́, kí wọn sì máa fi ìwà tútù gbogbo hàn sí gbogbo ènìyàn.