Tit 2:1-10

Tit 2:1-10 Yoruba Bible (YCE)

Ní tìrẹ, àwọn ohun tí ó bá ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro mu ni kí ó máa ti ẹnu rẹ jáde. Àwọn àgbà ọkunrin níláti jẹ́ ẹni tí ó ń ṣe pẹ̀lẹ́, ẹni ọ̀wọ̀, ọlọ́gbọ́n, tí ó jinná ninu igbagbọ, ninu ìfẹ́ ati ninu ìfaradà. Bákan náà, àwọn àgbà obinrin níláti jẹ́ ẹni tí gbogbo ìgbé-ayé wọn bá ti ìsìn Ọlọrun mu. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ onísọkúsọ tabi ẹrú ọtí. Wọ́n níláti máa kọ́ni ní ohun rere. Kí wọn máa fi òye kọ́ àwọn ọdọmọbinrin wọn láti fẹ́ràn ọkọ wọn ati ọmọ wọn. Kí wọn máa fara balẹ̀, kí wọn sì fara mọ́ ọkọ wọn nìkan. Kí wọn má ya ọ̀lẹ ninu iṣẹ́ ilé, kí wọn sì jẹ́ onínú rere. Kí wọn máa gbọ́ràn sí ọkọ wọn lẹ́nu, kí ẹnikẹ́ni má baà lè sọ ìsọkúsọ sí ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Bákan náà, máa gba àwọn ọdọmọkunrin níyànjú láti fara balẹ̀. Kí o ṣe ara rẹ ní àpẹẹrẹ rere ní gbogbo ọ̀nà. Ninu ẹ̀kọ́ tí ò ń kọ́ àwọn eniyan, kí wọn rí òtítọ́ ninu rẹ, kí wọn sì rí ìwà àgbà lọ́wọ́ rẹ. Kí gbolohun ẹnu rẹ jẹ́ ti ọmọlúwàbí, tí ẹnìkan kò ní lè fi bá ọ wí. Èyí yóo mú ìtìjú bá ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe alátakò nígbà tí kò bá rí ohun burúkú kan sọ nípa wa. Kí àwọn ẹrú fi ara wọn sí abẹ́ àṣẹ ọ̀gá wọn ninu ohun gbogbo. Kí wọn máa ṣe nǹkan tí yóo tẹ́ wọn lọ́rùn, kí wọn má máa fún wọn lésì. Kí wọn má máa ja ọ̀gá wọn lólè. Ṣugbọn kí wọn jẹ́ olóòótọ́ ati ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ní ọ̀nà gbogbo. Báyìí ni wọn yóo fi ṣe ẹ̀kọ́ Ọlọrun Olùgbàlà wa lọ́ṣọ̀ọ́ ninu ohun gbogbo.

Tit 2:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro lórí ìgbé ayé onígbàgbọ́ tòótọ́. Kọ́ àwọn àgbà ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti ní ìrònú àti láti jẹ́ ẹni àpọ́nlé àti ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Wọn gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó jinlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, nínú ìfẹ́ àti nínú ìpamọ́ra. Bákan náà, ni kí ó kọ́ àwọn àgbà obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti kọ́ bí à a tí gbé ìgbé ayé ẹni ọ̀wọ̀, wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ afọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ tàbí olùfẹ́ ọtí mímu, ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ olùkọ́ni ní ohun rere. Nípa èyí, wọ́n yóò lè máa kọ́ àwọn ọ̀dọ́bìnrin láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn àti àwọn ọmọ wọn, láti jẹ́ ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ọlọ́kàn mímọ́, kí wọ́n máa ṣe ojúṣe wọn nínú ilé, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onínúrere, kí wọ́n sì máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọ́n, kí ẹnikẹ́ni máa ba à sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bákan náà, rọ àwọn ọ̀dọ́ ọkùnrin láti kó ara wọn ni ìjánu. Nínú ohun gbogbo fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí alápẹẹrẹ ohun rere. Nínú ẹ̀kọ́ rẹ fi àpẹẹrẹ ìwà pípé hàn, ẹni tó kún ojú òṣùwọ̀n ọ̀rọ̀ tí ó yè kooro, tí a kò lè dá lẹ́bi, kí ojú kí ó ti ẹni tí ó ń sòdì, ní àìní ohun búburú kan láti wí sí wa. Kọ́ àwọn ẹrú láti ṣe ìgbọ́ràn sí àwọn olówó wọn nínú ohun gbogbo, láti máa gbìyànjú láti tẹ́ wọn lọ́rùn, wọn kò gbọdọ̀ gbó olówó wọn lẹ́nu, wọn kò gbọdọ̀ jà wọ́n lólè ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí wọ́n jẹ́ ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, kí wọn ó làkàkà ní gbogbo ọ̀nà láti jẹ́ kí ìkọ́ni nípa Ọlọ́run àti Olùgbàlà ní ìtumọ̀ rere.