Tit 1:1-2
Tit 1:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
PAULU, iranṣẹ Ọlọrun, ati Aposteli Jesu Kristi, gẹgẹ bi igbagbọ́ awọn ayanfẹ Ọlọrun, ati imọ otitọ ti mbẹ gẹgẹ bi ìwa-bi-Ọlọrun, Ni ireti ìye ainipẹkun, ti Ọlọrun, Ẹniti kò le ṣèké, ti ṣe ileri ṣaju ipilẹṣẹ aiye
Pín
Kà Tit 1Tit 1:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Èmi Paulu, ẹrú Ọlọrun, ati aposteli Jesu Kristi, ni mò ń kọ ìwé yìí. Oluwa yàn mí láti jẹ́ kí àwọn àyànfẹ́ Ọlọrun lè ní igbagbọ ati ìmọ̀ òtítọ́ ti ẹ̀sìn, ati ìrètí ìyè ainipẹkun, tí Ọlọrun tí kì í purọ́ ti ṣèlérí láti ayérayé.
Pín
Kà Tit 1Tit 1:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Paulu, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti aposteli Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run àti ìmọ̀ òtítọ́ irú èyí tí í máa darí ènìyàn sí ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run— ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ tí ó dúró lórí ìrètí iyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run tí kì í purọ́ ti ṣe ìlérí rẹ̀ ṣáájú kí ayé tó bẹ̀rẹ̀
Pín
Kà Tit 1