O. Sol 7:1-4
O. Sol 7:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹsẹ rẹ ti li ẹwà to ninu bata, iwọ ọmọ-alade! orike itan rẹ dabi ohun ọṣọ́, iṣẹ ọwọ ọlọgbọ́n oniṣọna. Iwọ́ rẹ dabi ago ti kò ṣe alaini ọti, ara rẹ dabi okiti alikama ti a fi lili yika. Ọmú rẹ mejeji dabi abo ọmọ agbọnrin meji ti iṣe ìbejì. Ọrùn rẹ dabi ile iṣọ ehin-erin; oju rẹ dabi adagun ni Heṣboni, lẹba ẹnu-bode Batrabbimu: imú rẹ dabi ile-iṣọ Lebanoni ti o kọju si ihà Damasku.
O. Sol 7:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ẹsẹ̀ rẹ ti dára tó ninu bàtà, ìwọ, ọmọ aládé. Itan rẹ dàbí ohun ọ̀ṣọ́, tí ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà ṣe. Ìdodo rẹ dàbí abọ́, tí kì í gbẹ fún àdàlú waini, ikùn rẹ dàbí òkítì ọkà, tí a fi òdòdó lílì yíká. Ọmú rẹ mejeeji dàbí ọmọ àgbọ̀nrín meji, tí wọn jẹ́ ìbejì. Ọrùn rẹ dàbí ilé-ìṣọ́ tí wọn fi eyín erin kọ́. Ojú rẹ dàbí adágún omi ìlú Heṣiboni, tí ó wà ní ẹnubodè Batirabimu. Imú rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Lẹbanoni, tí ó dojú kọ ìlú Damasku.
O. Sol 7:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báwo ni ẹsẹ̀ rẹ ti ní ẹwà tó nínú bàtà, Ìwọ ọmọbìnrin ọba! Oríkèé itan rẹ rí bí ohun ọ̀ṣọ́ iṣẹ́ ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà Ìdodo rẹ rí bí àwo tí kì í ṣe aláìní ọtí, ìbàdí rẹ bí òkìtì alikama tí a fi lílì yíká. Ọmú rẹ rí bí abo egbin méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì àgbọ̀nrín. Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín erin. Ojú rẹ rí bí adágún ní Heṣboni ní ẹ̀bá ẹnu ibodè Bati-Rabbimu. Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lebanoni tí ó kọ ojú sí Damasku.