O. Sol 5:1-9

O. Sol 5:1-9 Yoruba Bible (YCE)

Mo wọ inú ọgbà mi, arabinrin mi, iyawo mi. Mo kó òjíá ati àwọn turari olóòórùn dídùn mi jọ, mo jẹ afárá oyin mi, pẹlu oyin inú rẹ̀, mo mu waini mi ati wàrà mi. Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ jẹ, kí ẹ sì mu, ẹ mu àmutẹ́rùn, ẹ̀yin olùfẹ́. Mo sùn ṣugbọn ọkàn mi kò sùn. Ẹ gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn. Ṣílẹ̀kùn fún mi, arabinrin mi, olùfẹ́ mi, àdàbà mi, olùfẹ́ mi tí ó péye, nítorí pé, ìrì ti mú kí orí mi tutù, gbogbo irun mi ti rẹ, fún ìrì alẹ́. Mo ti bọ́ra sílẹ̀, báwo ni mo ṣe lè tún múra? Mo ti fọ ẹsẹ̀ mi, báwo ni mo ṣe lè tún dọ̀tí rẹ̀? Olùfẹ́ mi gbọ́wọ́ lé ìlẹ̀kùn, ọkàn mi sì kún fún ayọ̀. Mo dìde, mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, gbogbo ọwọ́ mi kún fún òjíá, òróró òjíá sì ń kán ní ìka mi sára kọ́kọ́rọ́ ìlẹ̀kùn. Mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, ṣugbọn ó ti yipada, ó ti lọ. Mo fẹ́rẹ̀ dákú, nígbà tí ó sọ̀rọ̀, mo wá a, ṣugbọn n kò rí i, mo pè é, ṣugbọn kò dáhùn. Àwọn aṣọ́de rí mi bí wọ́n ti ń rìn káàkiri ìlú; wọ́n lù mí, wọ́n ṣe mí léṣe, wọ́n sì gba ìborùn mi. Mo rọ̀ yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, bí ẹ bá rí olùfẹ́ mi, ẹ bá mi sọ fún un pé: Àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí. Kí ni olùfẹ́ tìrẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ? Ìwọ arẹwà jùlọ láàrin àwọn obinrin? Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ? Tí o fi ń kìlọ̀ fún wa bẹ́ẹ̀?

O. Sol 5:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi; mo ti kó òjìá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ. Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi; mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi. Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu, àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́. Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí. Gbọ́! Olólùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn. “Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi, àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi Orí mi kún fún omi ìrì, irun mi kún fún òtútù òru.” Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà mi ṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀? Mo ti wẹ ẹsẹ̀ mi ṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku? Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ìlẹ̀kùn inú mi sì yọ́ sí i Èmi dìde láti ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, òjìá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi, òjìá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń sàn sí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn Èmi ṣí ìlẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọ ọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀. Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i. Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká. Wọ́n nà mí, wọ́n sá mi lọ́gbẹ́; wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi. Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi! Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo bẹ̀ yín bí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi, kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un? Ẹ wí fún un pé àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mi. Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ, ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin? Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ tí ìwọ fi ń fi wá bú bẹ́ẹ̀?