O. Sol 4:8-12
O. Sol 4:8-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki a lọ kuro ni Lebanoni, iyawo mi, ki a lọ kuro ni Lebanoni: wò lati ori òke Amana, lati ori òke Ṣeniri ati Hermoni, lati ibi ihò kiniun, lati òke awọn ẹkùn. Iwọ ti gbà mi li ọkàn, arabinrin mi, iyawo! iwọ ti fi ọkan ninu ìwo oju rẹ, ati ọkan ninu ẹwọ̀n ọrùn rẹ gbà mi li ọkàn. Ifẹ rẹ ti dara to, arabinrin mi, iyawo! ifẹ rẹ ti sàn jù ọti-waini to! õrùn ikunra rẹ si jù turari gbogbo lọ. Iyawo! ète rẹ nkán bi afara-oyin: oyin ati wàra mbẹ labẹ ahọn rẹ; õrun aṣọ rẹ si dabi õrun Lebanoni. Ọgbà ti a sọ ni arabinrin mi, iyawo! isun ti a sé, orisun ti a fi edidi dí.
O. Sol 4:8-12 Yoruba Bible (YCE)
Máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni, iyawo mi, máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni. Kúrò ní ṣóńṣó òkè Amana, kúrò lórí òkè Seniri ati òkè Herimoni, kúrò ninu ihò kinniun, ati ibi tí àwọn ẹkùn ń gbé. O ti kó sí mi lẹ́mìí, arabinrin mi, iyawo mi, ẹ̀ẹ̀kan náà tí o ti ṣíjú wò mí, pẹlu nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó wà lọ́rùn rẹ, ni o ti kó sí mi lórí. Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó! Arabinrin mi, iyawo mi, ìfẹ́ rẹ dùn ju waini lọ. Òróró ìkunra rẹ dára ju turari-kí-turari lọ. Oyin ní ń kán ní ètè rẹ, iyawo mi, wàrà ati oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ, òórùn dídùn aṣọ rẹ dàbí òórùn Lẹbanoni. Arabinrin mi dàbí ọgbà tí a ti ti ìlẹ̀kùn rẹ̀. Ọgbà tí a tì ni iyawo mi; àní orísun omi tí a tì ni ọ́.
O. Sol 4:8-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Kí a lọ kúrò ní Lebanoni, ìyàwó mi, ki a lọ kúrò ní Lebanoni. Àwa wò láti orí òkè Amana, láti orí òkè ti Seniri, àti téńté Hermoni, láti ibi ihò àwọn kìnnìún, láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn. Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi; ìwọ ti gba ọkàn mi pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ, pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ. Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi! Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ, òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ! Ètè rẹ ń kan dídùn bí afárá oyin, ìyàwó mi; wàrà àti oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ. Òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn Lebanoni. Arábìnrin mi ni ọgbà tí a sọ, arábìnrin mi, ìyàwó mi; ìsun tí a sé mọ́, orísun tí a fi èdìdì dì.