O. Sol 4:1-16
O. Sol 4:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
WÒ o, iwọ li ẹwà, olufẹ mi: wò o, iwọ li ẹwà; iwọ li oju àdaba labẹ iboju rẹ: irun rẹ dabi ọwọ́ ewurẹ, ti o dubulẹ lori òke Gileadi. Ehin rẹ dabi ọwọ́ ewurẹ ti a rẹ́ ni irun, ti o gòke lati ibi iwẹ̀ wá, olukulùku wọn bi èjirẹ, kò si si ọkan ti o yàgan ninu wọn. Ete rẹ dabi owu òdodo, ohùn rẹ si dùn: ẹ̀rẹkẹ rẹ si dabi ẹlà pomegranate kan labẹ iboju rẹ. Ọrùn rẹ dabi ile-iṣọ Dafidi ti a kọ́ fun ihamọra, lori eyi ti a fi ẹgbẹrun apata kọ́, gbogbo wọn jẹ asà awọn alagbara. Ọmu rẹ mejeji dabi abo egbin kekere meji ti iṣe èjirẹ, ti njẹ lãrin itanna lili. Titi ọjọ yio fi rọ̀, ti ojiji yio si fi fò lọ, emi o lọ si òke nla ojia, ati si òke kékeké turari. Iwọ li ẹwà gbogbo, olufẹ mi; kò si abawọ́n lara rẹ! Ki a lọ kuro ni Lebanoni, iyawo mi, ki a lọ kuro ni Lebanoni: wò lati ori òke Amana, lati ori òke Ṣeniri ati Hermoni, lati ibi ihò kiniun, lati òke awọn ẹkùn. Iwọ ti gbà mi li ọkàn, arabinrin mi, iyawo! iwọ ti fi ọkan ninu ìwo oju rẹ, ati ọkan ninu ẹwọ̀n ọrùn rẹ gbà mi li ọkàn. Ifẹ rẹ ti dara to, arabinrin mi, iyawo! ifẹ rẹ ti sàn jù ọti-waini to! õrùn ikunra rẹ si jù turari gbogbo lọ. Iyawo! ète rẹ nkán bi afara-oyin: oyin ati wàra mbẹ labẹ ahọn rẹ; õrun aṣọ rẹ si dabi õrun Lebanoni. Ọgbà ti a sọ ni arabinrin mi, iyawo! isun ti a sé, orisun ti a fi edidi dí. Ohun gbigbìn rẹ agbala pomegranate ni, ti on ti eso ti o wunni; kipressi ati nardi. Nardi ati saffroni; kalamusi, kinnamoni, pẹlu gbogbo igi turari; ojia ati aloe, pẹlu gbogbo awọn olori olõrun didùn. Orisun ninu ọgba kanga omi iyè, ti nṣan lati Lebanoni wá. Ji afẹfẹ ariwa; si wá, iwọ ti gusu; fẹ́ sori ọgbà mi, ki õrun inu rẹ̀ le fẹ́ jade. Jẹ ki olufẹ mi wá sinu ọgbà rẹ̀, ki o si jẹ eso didara rẹ̀.
O. Sol 4:1-16 Yoruba Bible (YCE)
Wò ó! O dára gan-an ni, olólùfẹ́ mi, ẹwà rẹ pọ̀. Ẹyinjú rẹ dàbí ti àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ, irun orí rẹ dàbí ọ̀wọ́ ewúrẹ́, tí wọn ń sọ̀kalẹ̀ láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Gileadi. Eyín rẹ dàbí ọ̀wọ́ aguntan tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ gé irun wọn, tí wọn wá fọ̀; gbogbo wọn gún régé, Kò sí ọ̀kan kan tí ó yọ ninu wọn. Ètè rẹ dàbí òwú pupa; ẹnu rẹ fanimọ́ra, ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ ń dán bí ìlàjì èso Pomegiranate, lábẹ́ ìbòjú rẹ. Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi, tí a kọ́ fún ihamọra, ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ dàbí ẹgbẹrun (1000) asà tí a kó kọ́, bí apata àwọn akọni jagunjagun tí a kó jọ. Ọmú rẹ mejeeji dàbí ọmọ àgbọ̀nrín meji, tí wọn jẹ́ ìbejì, tí wọn ń jẹko láàrin òdòdó lílì. N óo wà lórí òkè òjíá, ati lórí òkè turari, títí ilẹ̀ yóo fi mọ́, tí òkùnkùn yóo sì lọ. O dára gan-an ni, olùfẹ́ mi! O dára dára, o ò kù síbìkan, kò sí àbààwọ́n kankan lára rẹ. Máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni, iyawo mi, máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni. Kúrò ní ṣóńṣó òkè Amana, kúrò lórí òkè Seniri ati òkè Herimoni, kúrò ninu ihò kinniun, ati ibi tí àwọn ẹkùn ń gbé. O ti kó sí mi lẹ́mìí, arabinrin mi, iyawo mi, ẹ̀ẹ̀kan náà tí o ti ṣíjú wò mí, pẹlu nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó wà lọ́rùn rẹ, ni o ti kó sí mi lórí. Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó! Arabinrin mi, iyawo mi, ìfẹ́ rẹ dùn ju waini lọ. Òróró ìkunra rẹ dára ju turari-kí-turari lọ. Oyin ní ń kán ní ètè rẹ, iyawo mi, wàrà ati oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ, òórùn dídùn aṣọ rẹ dàbí òórùn Lẹbanoni. Arabinrin mi dàbí ọgbà tí a ti ti ìlẹ̀kùn rẹ̀. Ọgbà tí a tì ni iyawo mi; àní orísun omi tí a tì ni ọ́. Àwọn ohun ọ̀gbìn inú rẹ tí ń sọ dàbí ọgbà pomegiranate, tí ó kún fún èso tí ó dára jùlọ, àwọn bíi igi hena ati nadi; igi nadi ati Safironi, Kalamusi ati Sinamoni, pẹlu oríṣìíríṣìí igi turari, igi òjíá, ati ti aloe, ati àwọn ojúlówó turari tí òórùn wọn dára jùlọ. Ọgbà tí ó ní orísun omi ni ọ́, kànga omi tútù, àní, odò tí ń ṣàn, láti òkè Lẹbanoni. Dìde, ìwọ afẹ́fẹ́ ìhà àríwá, máa bọ̀, ìwọ afẹ́fẹ́ ìhà gúsù! Fẹ́ sórí ọgbà mi, kí òórùn dídùn rẹ̀ lè tàn káàkiri. Kí olùfẹ́ mi wá sinu ọgbà rẹ̀, kí ó sì jẹ èso tí ó bá dára jùlọ.
O. Sol 4:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olólùfẹ́ mi! Háà, ìwọ jẹ́ arẹwà! Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ irun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́. Tí ó sọ̀kalẹ̀ lórí òkè Gileadi. Eyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbò tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀; olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́; kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó da dúró. Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó; ẹnu rẹ̀ dùn. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pomegiranate lábẹ́ ìbòjú rẹ Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi, tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra; lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún àpáta kọ́, gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára. Ọmú rẹ̀ méjèèjì dàbí abo egbin méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì tí ń jẹ láàrín ìtànná ewéko lílì. Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀ tí òjìji yóò fi fò lọ, Èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjìá àti sí òkè kékeré tùràrí. Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwà, olólùfẹ́ mi; kò sì ṣí àbàwọ́n lára rẹ. Kí a lọ kúrò ní Lebanoni, ìyàwó mi, ki a lọ kúrò ní Lebanoni. Àwa wò láti orí òkè Amana, láti orí òkè ti Seniri, àti téńté Hermoni, láti ibi ihò àwọn kìnnìún, láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn. Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi; ìwọ ti gba ọkàn mi pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ, pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ, Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi! Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ, òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ! Ètè rẹ ń kan dídùn bí afárá oyin, ìyàwó mi; wàrà àti oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ. Òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn Lebanoni. Arábìnrin mi ni ọgbà tí a sọ, arábìnrin mi, ìyàwó mi ìsun tí a sé mọ́, orísun tí a fi èdìdì dì. Ohun ọ̀gbìn rẹ àgbàlá pomegiranate ni ti òun ti àṣàyàn èso; kipiresi àti nadi, Nadi àti Safironi, kalamusi àti kinamoni, àti gbogbo igi olóòórùn dídùn, òjìá àti aloe pẹ̀lú irú wọn. Ìwọ ni ọgbà orísun, kànga omi ìyè, ìṣàn omi láti Lebanoni wá. Jí ìwọ afẹ́fẹ́ àríwá kí o sì wá, afẹ́fẹ́ gúúsù! Fẹ́ lórí ọgbà mi, kí àwọn òórùn dídùn inú rẹ lè rùn jáde. Jẹ́ kí olùfẹ́ mi wá sínú ọgbà a rẹ̀ kí ó sì jẹ àṣàyàn èso rẹ̀.